Àtúnṣe afárá Third Mainland yóò gba N3.8 tírílíọ̀nù, kíkọ́ afárá tuntun yóò tó N3.6 Tírílíọ́nù - ìjọba Nàìjíríà

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Minisita fun awọn akanṣe iṣẹ ode, David Umahi, ti sọ pe atunṣe afara Third Mainland Bridge yoo na ijọba ni biliọnu mẹrin din diẹ.

Nigba to n sọrọ nibi ipade igbimọ alaṣẹ Naijiria niluu Abuja, Umahi ṣalaye pe awọn opo to gbe afara naa duro labẹ omi ti yinrin tan, nitori aisi amojuto fun ọpọlọpọ ọdun, ati bi awọn kan ṣe n wa erupẹ lọna aitọ, àgbàrá, ati bi ogbó ṣe n ba awọn eroja ti wọn fi ṣe wọn.

Umahi sọ pe ọdun 2019 ni ayẹwo ati iwadii ijinlẹ ti kọkọ waye lati mọ nnkan to n ṣẹlẹ ni isalẹ omi abẹ afara naa.

"A si ri i pe ọpọlọpọ wahala lo ti ba afara naa."

Minisita ọhun ṣalaye pe ijọba ti kọkọ n gbeero lati tun afara naa ṣe, eyi ti yoo na wọn ni N3.8tr.

"Ṣugbọn ti a ba fẹ ẹ ṣe afara tuntun, yoo na wa ni N3.6tr."

Ṣaaju ni ijọba ti buwọlu N6.3bn fun atunṣe afara naa lọdun 2023, ti wọn si ti i pa fun ọpọlọpọ oṣu lati ṣe 'atunṣe rẹ'.

Eyi si kọ ni igba akọkọ ti wọn ṣe atunṣe afara naa.

Lọdun 2020 si 2021, oṣu bii mẹjọ ni wọn fi ti afara naa fun atunṣe.

Dave Umahi fi kun ọrọ rẹ pe agbaṣẹ ṣe meje ni awọn ti buwọluu lati lọ ọ ṣe iwadii finifini, ki wọn o si tun ṣe atupalẹ iye ti ikọọkan wọn ro pe awọn le fi pari atunṣe tabi kikọ afara tuntun.

O ni awọn nnkan ti awọn ba pade lara afara Third Mainland Bridge, ko yatọ si ti Carter Bridge ti ohun naa wa niluu Eko.

Ni ti afara naa, o ni awọn agbaṣẹ ṣe sọ pe o ti bajẹ kọja atunṣe, ti ileeṣẹ Julius Berger ti wọn ni ko wo o si sọ pe 359 biliọnu naira ni yoo ṣe afara tuntun.

"Nitori naa, ko si pe a fi n falẹ. O si ti han daju pe, kikọ afara mii dinwo ju ṣiṣe atunṣe Third Mainland Bridge, eyi to wa nilẹ lọ.

"Ni ibamu pẹlu ontẹ igbimọ alaṣẹ, ijọba yoo gbe ipolowo sita fun awọn ileeṣẹ to ba fẹ sowọpọ pẹlu ijọba lati gbọ bukaata awọn akanṣe iṣẹ yii, ti a o si tun jiroro pẹlu awọn ileeṣẹ ayanilowo nilẹ okeere."

Ọdun 1990 ni wọn ṣi Afara Third Mainland Bridge fun lilo, lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti wọn fi kọ ọ ni abẹ iṣejọba ologun Ibrahim Babangida.

Afara naa gun to iwọn kilomita mọkanla - oun si ni afara to gun julọ to so erekusu Eko mọ awọn agbegbe yooku.