You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọba àwọn olókoòwò Crypto gbàdájọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n
Oyinbo yii, Sam Bankman-Fried, tawọn eeyan n pe ni ọba okoowo ayelujara ti gbadajọ ẹwọn ọdun mẹẹẹdọgbọn (25 years) bayii.
Kootu sọ pe o jẹbi ẹsun jibiti lilu to le ju lagbaaye.
Olowo nla (billionaire) ni Sam Bankman-Fried, awọn idokowo bii Bitcoin, Ethereum atawọn mii tawọn eeyan maa n kowo le lorii ayelujara ni iṣẹ tawọn eeyan mọ to n ṣe.
Awọn eeyan nla-nla bii Tony Blair, olootu ilẹ Gẹẹsi nigba kan ati Bill Clinton to jẹ aarẹ Amẹrika tẹlẹ ni Bankman maa n ba lọ sode, nibi to gbayi de.
Loootọ lo ni ileeṣẹ to pe ni FXT, eyi ti miliọnu eeyan n ba dowopọ lojumọ.
Ṣugbọn gbese ni ileeṣẹ naa pada jẹ, awọn to kowo rẹpẹtẹ sibẹ ko ri kọbọ kan gba pada.
Paapaa julọ, okoowo ori ayelujara ko lọfiisi, ko sibi teeyan yoo ti lọọ halẹ mọ́ ẹni to ṣe gbaju ẹ fun un.
Kí ló ṣẹlẹ̀ tóyìnbó Bankman-Fried fi jẹ gbèsè?
Oṣu kọkanla ọdun 2022 ni gbese wọle tọ Sam Bankman-Fried, to di pe awọn eeyan to ba a dowopọ lati jere padanu gidi ni.
Ohun to fa a gẹgẹ bi awọn agbefọba ni kootu ṣe wi, wọn ni Sam fowo awọn onibaara rẹpẹtẹ ṣe faaji ara rẹ ni.
Wọn lo fowo tawọn onibaara fi ba a dowopọ ra dukia bii ile ati mọto.
Wọn lo koju bọ oṣelu pẹlu o si nawo nla sibẹ. O tun da eyi to ku sori awọn okoowo ọlọdun pipẹ ti yoo maa mowo wọle fun oun nikan.
Biliọnu mẹjọ dọla ($8bn), owo awọn ẹni ẹlẹni kaakiri aye ni Bankman fi gbọ ti ara rẹ nikan bi wọn ṣe wi ni kootu.
Eyi lo fa a ti gbogbo ẹni to ba ileeṣẹ rẹ, FTX dowopọ fi padanu, nigba ti wọn ko ri oju owo wọn gba debi èrè jijẹ.
Ọpọlọpọ wọn ni wọn wa ninu idaamu ọkan bayii, wọn n ronu boya wọn yoo rowo wọn gba tabi o ti lọ fáà-fáà.
Jìbìtì tó burú jù lágbàáyé ni Bankman-Fried lù-Adájọ́
Adajọ Lewis Kaplan to ju Bankman Fried sẹwọn ọdun mẹẹẹdọgbọn sọ pe jibiti to buru ju laye ree. O ni awọn yooku n tọ Sam lẹyin ni.
Adajọ ṣo pe gbogbo ẹsun jibiti lilu ati didari owo olowo gba ibomi-in ti wọn fi kan an yii ri bẹẹ, o si jẹbi.
Kootu naa waa paṣẹ ẹwọn ọdun mẹẹẹdọgbọn gẹgẹ bi ijiya fun ọmọde olowo tọwọ ti ba lati ọjọ kejila oṣu kejila ọdunn 2023 to kọja.
Awọn agbofinro lati ẹka Bahamas Financial Crimes Investigation, ni wọn mu un pẹlu aṣẹ ilẹ Amẹrika.
Kí wáá ni Bankman náà wí ní kóótù
Ẹsun meje mi-in, yatọ si jibiti ati gbigbe owo olowo gba ibomi-in ni wọn fi kan olujẹjọ Bankman.
Ṣugbọn nigba to n jẹjọ naa, o ni oun ko jẹbi eyikeyi ninu wọn.
Bankman ni ti oun ba tiẹ ṣe aṣiṣe, oun ko ṣe e lati ba teeyan jẹ. Ko le baa daa naa ni.