Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ níbi ètò ìdìbò Ààrẹ Ghana tí yóò wáyé lọ́jọ́ Àbámẹ́ta?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Opin ọsẹ yii, ọjọ keje, oṣu Kejila, ọdun 2024 ni eto idibo aarẹ orilẹede Ghana yoo waye.

Igbakeji aarẹ to wa lori oye, Mahamudu Bawumia, ati aarẹ orilẹede naa nigba kan ri, John Mahama, lo n lewaju laarin awọn oludije.

Ọdun 2016 ni wọn dibo yan Nana Akufo-Addo to wa lori oye bayii, yoo si pari saa rẹ lẹyin eto idibo to n bọ lọna.

Awọn ibo wo ni yoo waye lọjọ Abamẹta?

  • Ibo Aarẹ – oludije mejila n du ipo yii
  • Ibo awọn aṣofin – awọn oludije kaakiri ẹkun 275 ni Ghana ni yoo kopa ninu rẹ

Ta ni yoo di Aarẹ Ghana lẹyin Nana Akufo-Addo?

Bo tilẹ jẹ pe eeyan mejila lo n figagbaga lati di aarẹ, meji pere ninu wọn lo wa loke tente to si ṣeeṣe ki awọn to ku lulẹ.

Awọn meji to n lewaju ọhun ree

  • Mahamudu Bawumia (NPP) - Oun lo ti n ṣiṣẹ gẹgẹ bii igbakeji Aarẹ Nana Akufo Ado fun ọdun mẹjọ. O kawe ni fasiti Oxford nilẹ Gẹẹsi. To ba wọle, oun ni yoo jẹ aarẹ musulumi akọkọ ni Ghana. O ti fi akoko igba kan jẹ gomina banki apapọ ni Ghana.
  • John Mahama (NDC) – Mahama ni aarẹ Ghana fun ọdun mẹrin aabọ lati 2012. O tun gbegba ibo lọdun 2016 amọ o lulẹ lẹẹkan sii. O ti ṣeleri lati ṣe awọn atunṣe ti orilẹede naa n fẹ lai fi akoko ṣofo.

Lara awọn iṣoro ti aarẹ tuntun ni Ghana yoo dojukọ ni ọrọ aje to dẹnukọlẹ.

Banki agbaye ti kọkọ sọ pe ti nnkan ba n tẹsiwaju bo ṣe wa nigba kan ri ni Ghana, o ṣeeṣe ki eeyan to le ni 850,000 wọ inu iṣẹ ati oṣi ko to di ọdun 2022.

Nigba ti yoo to ọdun 2022, nnkan ti buru ju bo ṣe wa tẹlẹ lọ.

Yatọ si ọrọ aje, aarẹ tuntun yoo tun dojukọ iṣoro ti iwakusa wura ilẹ naa lọna aitọ n da silẹ nibẹ.

Nigba wo ni esi ibo naa yoo jade?

Gẹgẹ bo ṣe ṣẹlẹ lawọn eto idibo to ti waye sẹyin, o ṣeeṣe ki a mọ ẹni to jawe olubori lọjọ kẹwaa, oṣu Kejila yii kan naa.

Gẹgẹ bii alakalẹ ofin to rọ mọ eto idibo ni Ghana, esi ibo gbọdọ jade laarin ọjọ mẹta ti eto idibo ba waye nibẹ.