You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wọ́n bá òkú ayálégbé tó ń jẹrà nínú yàrá l'Ógùn
Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko yii ko tii si ẹni to ṣọ pato ohun to ṣokunfa iku ọkunrin ayalegbe kan, Tolulope Olusanya, sibẹ, kayeefi ni iku rẹ ṣi n jẹ fawọn ara adugbo, paapaa awọn to gbọ.
Ẹni ọdun marundinlaadọta ni wọn pe Olusanya to n gbe ladugbo Shittu, opopona Madojutimi, Abiola Way niluu Abeokuta, ipinlẹ Ogun.
Baba onile ti Olusanya n gbe ni iroyin fi to wa leti pe o ṣakiyesi oku rẹ ninu ile, to si lọ fi to awọn ọlọpaa ẹkun Kemta, Idi-Aba leti.
Wọn ni o ti to ọjọ meloo kan ti awọn ara adugbo naa ti gburo Olusanya gbẹyin, ẹni ti wọn lo gbajumọ daadaa lagbegbe naa, koda ti wọn sọ pe baba onile rẹ ko gburo rẹ.
Ai gburo Olussanya lo mu ki baba onile rẹ dide lati lọ sile rẹ, lati lo wo ohun to n ṣẹlẹ. Igba ti wọn ni baba naa debẹ, ni wọn lo bẹrẹ sii gboorun buruku kan lati inu yara, eyi lo jẹ ko gbiyanju lati ṣilẹkun wọle.
Wọn ni gbogbo akitiyan baba onile naa lati ja ilẹkun wọle lo ja si pabo, eyi gan-an lo jẹ ko gba teṣan ọlọpaa Kemta, Idi-Aba lọ lale ọjọ Aje, ọsẹ yii lọ, lati fi to wọn leti.
Kayeefi ni wọn lo jẹ fawọn ọlọpaa naa nigba ti wọn debẹ, nigba ti wọn bẹrẹ sii gbọ oorun buruku. Idi ree ti wọn fi fipa ja ilẹkun naa wọle.
'Iru ki leyi' ni ọrọ iyalẹnu to jade lẹnu gbogbo awọn to wa nibẹ lasiko naa, nigba ti wọn ba oku Olusanya lori bẹẹdi, to ti wu kọja sisọ.
Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Omolola Odutola, nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn akọroyin, jẹ ko di mimọ pe Ọgbẹni Adebesin Adebayo to jẹ baba onile Olusanya lo pariwo sita, to si lọ fi to awọn ọlọpaa leti ni nnkan bi agogo mẹjọ kọja iṣẹju mẹẹdogun alẹ, to kọja.
"Nigba ti aigburo Olusanya n kọ baba onile naa lominu, lo jẹ ko gba ile rẹ lọ, to si ṣakiyesi oorun buruku lati inu yara. O ti tilẹkun lati inu ile, idi ree to fi pariwo sita," Odutola sọ bẹẹ.
Odutọla tẹsiwaju pe "Awọn ọlọpaa wa, ni wọn ja ilẹkun wọnu ile Olusanya, wọn si ba oku rẹ to ti wu lori bẹẹdi, to si dabi ẹni pe o ti ku tipẹ."
Agbẹnusọ naa sọ pe o ṣoro fawọn ọlọpaa lati gbe oku Olusanya kuro nile naa lalẹ ọjọ naa, nitori gbogbo igbiyanju lati ri iranlọwọ awọn eleto ilera lo ja si pabo.
Bakan naa lo sọ pe awọn ko tun ri awọn mọlẹbi oloogbe naa lati ba sọrọ, idi ree to fi sọ pe awọn ko ri oku naa gbe lọ si mọṣuari, bo tilẹ jẹ pe ti ilẹ fi mọ lawọn fi daabo bo gbogbo agbegbe naa.
Bi ẹ ko ba gbagbe, iru iṣẹlẹ yii waye lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun to kọja nigba ti wọn ri oku Fatai Hamzat ninu ile rẹ to wa ladugbo Oremeji, Ijeun-Titun, Abeokuta.
Hamzat lo gbẹmi ara rẹ sinu ile, to si jẹ pe awọn agbofinro lo pada lọ gbe oku naa kuro lọ si mọṣuari.