You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
‘Container’ já lu àwọn ọkọ̀ l’Eko, èèyàn kan kú, mẹ́rin míì farapa
Awakọ ero kan ti padanu ẹmi rẹ niluu Eko lẹyin ti ọkọ ajagbe kan ati ile ẹru ori rẹ ṣubu le awọn ọkọ lori lagbegbe Cele Bus stop to wa loju ọna marosẹ Oshodi si Apapa.
Kete lẹyin iṣẹlẹ naa ni awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi ipinlẹ Eko, LASEMA atawọn ẹṣọ oju popo, LASTMA lọ sibẹ lati doola awọn ti ijamba naa kan.
Ninu atẹjade kan ti akọwe agba LASEMA, Olufemi Oke-Osanyintolu fi ṣọwọ si awọn akọroyin, o ni eeyan mẹrin mii lo farapa nibẹ.
Atẹjade ọhun ni “Nigba ti a de ibẹ, a ri pe ọkọ nla kan to gbe ile ẹru ti iwọn rẹ to 20ft, ọkọ akero Volkswagen pẹlu nọmba AKD 489XZ, ọkọ Highlander SUV pẹlu nọmba AGL 366FP ati ọkọ Toyota RAV4 to ni nọmba AAA 353FH ni ọrọ naa kan.”
“Iwadii wa fi han pe ijanu ọkọ nla naa lo kọṣẹ lasiko to wa lori ere asapajude ko to kọlu awọn ọkọ to wa niwaju rẹ.”
“O ṣeni laanu awakọ akero bọọsi kan to jẹ ọkunrin padanu ẹmi rẹ, nigba ti awọn mẹrin mii farapa.”
“Mẹta ninu awọn to farapa jẹ ọkunrin ti ẹnikan si jẹ obinrin, a si ti ko awọn eeyan naa lọ sile iwosan.”
Oke-Osanyintolu sọ siwaju si pe awọn adoola wa nikalẹ lati ri daju pe ohun gbogbo pada bọ sipo nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.
O pari ọrọ rẹ pe wọn ti gbe oku awakọ to padanu ẹmi rẹ fun awọn mọlẹbi rẹ lati sin.