Èyí ni àwọn ìwé tí o gbọ́dọ̀ ní bí o kò bá fẹ́ kí wọ́n dá ọ padà sílé láti America

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

O le ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un ọmọ Naijiria ti idapadasile lati America n run lorii wọn bayii, nitori ai ni iwe to yẹ lati maa gbe ilu naa.

Eyi jẹyọ lati ara lẹta kan to tẹ ẹka iroyin Fox lọwọ, lati ọdọ ajọ to n ri si iwọle-jade ati lile awọn mi-in wale lati ilẹ America. (US Immigration and Customs Enforcement and Removal Operations (ICE).

Lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni ọdun 2025, ẹka iroyin Fox, royin pe awọn orukọ kan ti wa lori iwe ajọ ICE, ti wọn fẹẹ le wọn lati oṣu Kọkanla ọdun 2024.

Iroyin naa sọ pe awọn ọmọ Naijiria lo wa nipo keji ninu awọn to n japa ju. Somalia, Ghana, Senegal atawọn mi-in ni wọn tẹle e.

Latigba ti Aarẹ Donald Trump ti gba akoso logunjọ oṣu Kin-in-ni ọdun 2025 ni ilẹ America ti n le awọn ti ko niwe niluu naa pada si orileede wọn.

Eeyan 956 ni wọn mu lọjọ Aiku, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kin-in-ni ọdun 2025, nigba ti wọn dọdẹ wọn.

Eyi waye lẹyin ti wọn ti kọkọ mu eeyan 286 ni Satide, ti wọn si mu eeyan, 539 lọjọ Ẹti, 538 l'Ọjọbọ.

Loṣu Kọkanla ọdun 2024, eeyan to le ni miliọnu kan ni wọn wa loju iwe ajọ to n ri si iwọle ijade, ti wọn fẹẹ le wọn kuro l'America.

Bakan naa ni agbenusọ ẹka irinna naa sọ pe ẹgbẹẹgberún awọn ọmọ ilẹ Africa lo wọ America lọna aitọ laaarin 2023 si 2024.

Nicaragua lo pe ilu ti wọn gba wọle.

Àwọn ìwé tí o gbọ́dọ̀ ní láti máa gbé America lọ

*Ojulowo iwe irinna to ba idi ti o fi wa l'America mu (Boya fun iṣẹ, mọlẹbi )

*Ẹri to foju han pe o yẹ ki o wa l'America, boya o ba ẹnikan to jẹ ọmọ America tan, tabi ẹnikan lo ran ọ wa, eyi ni i ṣe pẹlu iru fisa ti o ni lọwọ.

*Iwe adehun iṣẹ, iwe ọjọọbi, iwe ẹri igbeyawo, iwe to n ṣalaye ipo ilera rẹ, iwe ẹri owo to o ni, to le jẹ ki wọn mọ pe o lowo ti o le maa na l'America, lai huwa ọdaran tabi ki ọwọ bọ owo olowo.

Ìwé tó ṣe pàtàkì fún àwọn tó fẹ́ẹ́ màa gbé America lọ (Green Card)

Orilẹede America maa n fun awọn to ti pinnu lati maa gbe nibẹ niwee ti a mọ si Green Card.

Iwe naa lo n fi han pe wọn lẹtọọ lati maa gbe l'America.

Ki o too le ni iwe Green Card yii, o gbọdọ ni fọọmu 1-551.

*O gbọdọ ni fisa arinrinajo (immigration visa.)

*Ẹri to fi ajọṣe iwọ ati ọmọ orilẹede America han, to si han pe o lẹtọọ lati maa gbe niluu naa titi lae.

Ìwé tí àwọn tó torí iṣẹ́ lọ s'America gbọ́dọ̀ ní

Iwe I-766, to n fi han pe o le ṣisẹ l''America.

Iwe lati ọdọ ọmọ America to gba ọ siṣẹ.

Iwe ti a mọ si I-140 ( To wa fun ọmọ ilu mi-in to waa ṣiṣẹ l'America).

Iwe to n ṣafihan jijẹ oṣiṣẹ ( ti o ba ni).

Ìwé àwọn tó lọ fún ọ̀rọ̀ mọ̀lẹ́bí

Iwe I-130.

Iwe ọjọọbi awọn mọlẹbi rẹ.

Iwe ẹri igbayawo ( nibi ti wọn ba ti beere).

Fún àwọn tí kò ní í pẹ́ẹ́ kúrò l'America

*Ojulowo iwe irinna

*Fisa to ba ohun ti o tori ẹ wa si America mu, boya iṣẹ tabi iwe kika tabi okoowo

*Awọn iwe to wa lati ọdọ awọn ileewe tabi ohun ti o tori ẹ wa s'America naa.