Bàálù hẹlikọ́pútà ọmọogun Nàìjíríà kan já nípínlẹ̀ Niger

Baluu hẹlikọputa ileeṣẹ ọmọogun Naijiria kan ti jabọ lagbegbe ilero Chukuba ni ipinlẹ Niger.

Baluu naa ti nọmba idanimọ rẹ jẹ MI-171 wa lẹnu iṣẹ idoola ẹmi lasiko ti iṣẹlẹ naa ṣẹ.

Gẹgẹbi alukoro ileeṣẹ ọmọogun ofurufu lorilẹede Naijiria, Edward Gabkwet.

Ijamba baluu naa ṣẹlẹ ni nnkan bii agogo kan ọsan ọjọ Aje, ko si tii si ẹni le sọ ni pato iye awọn eeyan to wa ninu rẹ nigba ti iṣẹlẹ naa ṣẹ.

“Baluu hẹlikọputa naa gbera kura ni ile ẹkọ alakọbẹrẹ Zungeru Primary School lati kọri si ipinlẹ Kaduna ki wọn to ṣakiyesi pe o ti ja ni ileto Chukuba ni ijọba ibilẹ Shinroro ni ipinlẹ Niger.

“Akitiyan n lọ lọwọ lati doola awọn ero to wa ninu ọkọ baluu hẹlikọputa naa. “

Alukoro ileeṣẹ ọmọogun ofurufu naa ni iwadii pẹlu si ti bẹrẹ lat mọ ohun to ṣeeṣe ko fa ijamba baluu naa

Ni ọjọ kejilelogun oṣu keji ọdun 2021 lawọn ọmọogun ofurufu meje ku ninu ijamba baluu kan to n gbe wọn lati Abuja lọ si Minna.