Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tún dóòlà ẹlòmíràn lọ́wọ́ àwọn ajínigbé l’Abuja

Ileeṣẹ ọlọpaa niluu Abuja tun ti doola ẹlomiran lọwọ awọn ajinigbe lọjọ Aiku.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni Abuja tii ṣe olu ilu orilẹede Naijiria, SP Josephine Adeh, Anipr,lo fọrọ yii lede loju opo X rẹ.

SP Adeh ṣalaye pe ni nkan bi ago mọkanla abọ Aiku lawọn ọlọpaa kogberegbe ti ẹkun Iddo doola ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Suleiman Sabo ni agbegbe Sauka lopona papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe niluu Abuja.

Agbẹnusọ ọlọpaa fikun ọrọ rẹ pe awọn ọlọpaa to doola ọkunrin naa tun mu afurasi ajinigbe kan, Muhammad Abel, ẹni ọdun mejilelọgbọn lati ipinlẹ Kogi.

O ni wọn ka ibọn kan mọ ọ lọwọ pẹlu ọta ibọn mẹwaa.

Ọkunrin tawọn ọlọpaa gba lọwọ awọn ajinigbe yii ni wọn sọ pe o ṣeeṣe, amọ, o ti n gba itọju nile iwosan bayii.

Agbẹnusọ ọlọpaa ni ọkunrin naa yoo pada sile ti o ba ti gbadun tan.

Ẹwẹ, kọmisọna ọlọpaa niluu Abuja, CP Haruna G. Garba, psc ti wa fi asiko yii sọ fawọn araalu pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo ri pe gbogbo iwa ọdaran dopin l’Abuja ti alaafia yoo si jọba.

O rọ awọn araalu lati maa ta awọn ọlọpaa lolobo ohun kohun tabi ọdaran ki ọdaran ti wọn ba ti kẹfin rẹ.