You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọ̀rọ̀ àlùfàǹsá ni Obasanjo sọ, ó fẹ́ dojú ìjọba alágbádá bolẹ̀ ni - Tinubu
Oludije fun ipo aarẹ fun ẹgbẹ oselu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ti fesi pada fun aarẹ tẹlẹ ni Naijiria, Oloye Olusegun Obasanjo.
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe Obasanjo lo sọrọ lori esi ibo aarẹ ti ajọ eleto idibo, INEC kede rẹ lọjọ Aje, to si n beere pe ki wọn wọgile ibo aarẹ naa nitori awọn amgomago to jẹyọ.
Bakan naa, Obasanjo ni ki ajọ INEC fi eto idibo miran si ọjọ Kẹrin osu Kẹta ọdun 2023.
Amọ nigba to n fesi pada, Tinubu ni awọn ọrọ ti agba oselu naa sọ lo le ba nkan jẹ, eyi to si tun le mu ifasẹyin ba ilana eto iselu ilẹwa.
Tinubu, ninu atẹjade kan ti amugbalẹgbẹ rẹ feto iroyin, Dele Alake fisita wa sapejuwe awọn ọrọ Obasanjo naa bii iwa alanikanjọpọn, agberaga ati oniwa ibajẹ.
Ibo ti Peter Obi ba bori nikan ni yoo tẹ Obasanjo lọrun - Tinubu
Tinubu ni “Obasanjo fesi si ikede esi ibo aarẹ naa tori awọn iroyin eke to n lọ kaakiri nipa ẹrọ BVS ti wọn ni awọn eeyan kan ti tọwọbọ, ti esi to gbe jade si jẹ ayederu.
Obasanjọ ko wadi otitọ ọrọ nipa isẹlẹ naa, ko to bọ sita lati fesi lori rẹ, o si yẹ ko mọ pe gẹgẹ bii aarẹ ana ni Naijiria, agba ilu lo jẹ sugbọn awọn ọrọ to m jade lẹnu rẹ lo jẹ ọrọ alufansa.
Gbogbo awọn ẹsun to si fi kan ajọ INEC nipa bi esi ibo to n kede se jẹ olotitọ si, lo n pa ni lẹrin, to si jẹ eyi ti ko wu eti gbọ.”
Tinubu sọ siwaju pe “Gbogbo wa la mọ ẹgbẹ oselu ti Obasanjo fi si tori o ti kede saaju pe Peter Obi, tii se oludije sipo aarẹ fẹgbẹ oselu Labour Party ni oun n pọn lẹyin rẹ.
Amọ nibayi ti mo na Peter Obi mọle ni agọ idibo ati wọọdu Obasanjo, o ti foju han gbangba pe eto idibo ti Obi ba bori nikan ni yoo bojumu loju Obasanjo.”
"Obasanjo fẹ ditẹ gbajọba lodi si iselu alagbada ni"
Atẹjade naa wa yan pe bi ko si oloselu tootọ ti yoo faramọ pe ki wọn wọgile ilana isejọba alagbada nitori pe esi ibo ko ri bo se fẹ.
O ni bi Obasanjo se n beere pe ki wọn wọgile ibo aarẹ yii lo dabi igba to fẹ ditẹ gbajọba tako ilana iselu alagbada ati ofin ilẹ wa, yoo si dara awọn ọmọ Naijiria kọ eti ikun sọrọ aarẹ tẹlẹ naa.
Obasanjo fi ohùn ránṣẹ́ sí àjọ elétò ìdìbò INEC lori esi ibo aarẹ to n gbe jade
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe Olusegun Obasanjo sọ fún Buhari láti rii pe INEC se ohun tó tọ́ lórí ìgbéjádesì ìdìbò
Aare Naijiria tẹ́lẹ̀, Oloye Olusegun Obasanjo ti ko lẹ́ta ransẹ́.
O parọwa fun olori ajọ INEC pe ko tete 's e àwọn atunse tó ye si awọ̀n asise to n waye ninu esi idibo ti wọ́n n ka yii.
O ni eyi ko sẹ́yin bi awọ̀n egbẹ́ oselu Labour Party ati PDP se sorọ̀ lori awọ̀n kudiẹ́ kudiẹ́ to n waye nibi esi idibo to n jade naa.
Obasanjo sọ̀ pe ko buru ti ajọ̀ INEc ba sun kika esi idibo naa siwaju ki o le se atunse to ye si awón esi idibo naa.
Obasanjo so pe ti INEC ko ba maa gbe esi idibo BVAS naa si inu ero ayelujara bi o se ye le sokunfa ki esi idibo naa ma jẹ́ itẹ́wọ̀gba kaakiri.
Bakan naa lo tun parowa fun Aare Muhammadu Buhari pe ko yanju ọ̀rọ̀ esi idibo naa to n fa ikunsinu lasiko yii ninu leta naa.
O ni ki Buhari wọ́gile awon idibo ti ko lọ́ bi o ti yẹ ti ko si hande to.