You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Man City vs Fulham àti àwọn ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tí yóò wáyé ní Premier League àti Laliga lópin ọ̀sẹ̀ yìí
Ọsẹ Ifẹsẹwọnsẹ keje ti ligi ilẹ Gẹẹsi yoo tẹsiwaju lonii, ti awọn ẹgbẹ agbabọọlu yoo si ma gba alejo ara wọn.
Lẹyin ifẹsẹwọnsẹ mẹfa, ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool lo n leke lori tabili pẹlu ami mẹdogun, ti Man city si wa ni ipo keji pẹlu ami mẹrinla.
Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ati Chelsea lo wa ni ipo kẹta ati ipo kẹrin pẹlu ami mẹrinla ati mẹtala.
Ẹgbẹ agbabọọlu Man City ati Arsenal nikan ni ko ti padanu ifẹsẹwọnsẹ kankan lati igba ti liigi Premiership ilẹ Gẹẹsi ti bẹrẹ ni saa yii.
Bawo ni awọn ifẹswọnsẹ yoo se waye lonii?
ni irọlẹ oni, awọn ifẹsẹwọnsẹ ti yoo waye ni idije premier league ilẹ Gẹẹsi niyi:
- Crystal Palace vs Liverpool - ni dede agogo mejila abọ.
- Arsenal vs Southampton - ni dede agogo mẹta.
- Bentford ati Wolverhamton Wanderers - ni dede agogo mẹta.
- Leicester City vs Bournemouth - ni dede agogo mẹta.
- Man City vs Fulham - ni dede agogo mẹta.
- West Ham vs Ipswish Town - ni dede agogo mẹta.
- Everton vs Newscastle United - ago marun un abọ
To ba di ni ọla ọjọ Aiku, ọjọ kẹfa oṣu kẹwaa, ifẹsẹwọnsẹ mẹta yoo waye.
- Aston Villa vs Manchester United - ni ago meji lọsan.
- Chelsea vs Nottingham Forest - ni ago meji lósàn.
- Brighton & Hove Albion vs Tottenham Hotspur - ago mẹrin abọ
Ni liigi La Liga ti orilẹede Spain
Ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona lo n leke tabili lẹyin ifẹsẹwọnsẹ mẹjọ pẹlu ami mokanlelogun.
Ipo Keji ni ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid wa ni pẹlu ami mejidinlogun
Bi awọn ifẹsẹwọnsẹ yoo se waye lonii ree:
- Espanyol vs Mollorca - ni ago kan ọsan.
- Gatafe vs Osasuna - ni ago mẹta kọja isẹju marun un
- Real Madrid vs Villarreal - ni ago mẹjọ alẹ.
- To ba di ọla ni ọjọ kẹfa oṣu kẹwaa,
- Deportivo Alaves vs Barcelona - ni agọ mẹta kọja isẹju marun un
- Ti Real Sociedad vs Atletico - ni ago mẹjọ aṣalẹ.