You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Aburú ni ‘Muslim-Muslim ticket,’ yóò pa Krìsìtẹ́nì lẹ́nu mọ́ - Babachir Lawal
Akọwe ijọba apapọ nigba kan ri, to tun jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC, Babachir Lawal ti sọ pe ọna ati mu awọn ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria lẹru ni bi ẹgbẹ oṣelu APC ṣe fa oludije fun ipo Aarẹ ati igbakeji rẹ to jẹ Musulumi kalẹ.
Lawal lo sọ ọrọ naa ninu ifọrowerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin Arise.
Ọrọ naa lo n jade lẹyin wakati diẹ ti ajọ eleto idibo, INEC, kede orukọ gbogbo awọn ti wọn fontẹ lu lati dije du ipo Aarẹ ati ipo aṣofin nile igbimọ aṣofin agba.
"Awọn Musulumi ko fara mọ igbesẹ APC lati pa awọn Kristiẹni lẹnu mọ"
Ti ẹ ko ba gbagbe, Bola Tinubu, to jẹ ọmọ ilẹ Yoruba ati Musulumi lo ti kọkọ mu Kashim Shettima, to jẹ ọmọ Hausa gẹgẹ igbakeji rẹ, ti oun naa tun jẹ Musulumi.
Lawal sọ pe awọn Musulumi ni Ariwa ko faramọ igbesẹ APC lati mu awọn meji to jẹ ẹlẹsin Musulumi kan naa lati dije du ipo Aarẹ.
O ni igbesẹ ọhun yoo pa awọn awọn Kristẹni lẹnumọ.
O ni “Bi awọn oludijee APC mejeeji ṣe jẹ Musulumi jẹ ọna lati tun fa ipinya laarin awọn ọmọ Naijiria, paapaa laarin awọn eeyan Ariwa.”
“Awa gẹgẹ bii adari, a n gbiyanju lati mu iṣọkan ni Naijiria, amọ ko to wi ka to fọ, wọn ti mu erongba buburu yii wa.”
“Fun awọn ololufẹ alaafia ati iṣọkan nilẹ yii, paapaa ni Ariwa nibi to ti kan wa gbungbun, igbesẹ ti wọn gbe yii ko gbọdọ ṣe aṣeyọri.”
“A si gbọdọ ri daju pe a ṣẹgun igbesẹ naa to bẹẹ ti ẹnikẹni ko fi ni gbero iru rẹ mọ nilẹ yii.”
Gẹgẹ bii ohun ti Lawal sọ, igbesẹ APC naa jẹ ọna lati mu ọrọ ẹsin wọ eto oṣelu Naijiira, eyii ti ko le so meso rere kankan.
Lawal ni ti Aarẹ ati igbakeji rẹ ba je Musulumi, o n tumọ si pe Musulumi nikan ni yoo aa wa ni awọn ipo giga ni Naijiria wọn yoo si yọ ọwọ awọn ọmọlẹyin Kristi kuro lawo ojuṣe wọn ninu idagbasaoke orilẹ-ede.
O ṣalaye siwaju sip e awọn Musulumi nikan ni yoo maa ri iṣẹ ijọba ti APC ba ṣe aṣeyọri ninu ki Aarẹ ati igbakeji rẹ jẹ Aarẹ.
O ni igbesẹ lati mu Naijiria di ẹlẹsin Musulumi nikan kii ṣe nipa fifi ipa mu awọn eeyan lọ sinu Mọṣalaṣi, amọ o jẹ igbesẹ fifi awọn Musulumi nikan si ipo giga, kii si ṣe ohun to bojumu, ko si le mu idagbasoke ba Naijiria.
Lawal wa ni pẹlu adura ati kaadi idibo PVC lawọn yoo ṣẹgun aa APC lati sọ Naijiria di ẹlẹsin kan naa.