NUPENG ṣẹ́wélé ìyanṣẹ́lódì lẹ́yìn àdéhùn pẹ̀lú iléeṣẹ́ ìpọnpo Dangote

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ẹka epo rọbi lorilẹede Naijiria, NUPENG ti wọgile iyanṣẹlodi wọn ti wọn bẹrẹ lọjọ Aje.
NUPENG ṣẹwele iyanṣẹlodi naa lẹtin ti adehun waye laarinẹgbẹ baa ati ileeṣẹ ipọnpo Dangote.
Ninu atẹjade ti wọn fi sita loju opo X wọn, NUPENG kede pe awọn alaṣẹ ileeṣẹ ipọnpo Dangote ti gba pe eyikeyi to ba wu ninu awọn dẹrẹba ọkọ epo ileeṣẹ naa lo le darapọ mọ oṣiṣẹ - igbesẹ yii ko ba awọn alaṣẹ ileeṣẹ ipọnpo Dangote lara mu.
NUPENG nfi ẹsun kan ileeṣẹ ipọnpo Dangote pe o n sọ ara rẹ di balogun eminikan lọga lẹka ipọnpo, sisan owo oṣu ti ko ya ranti f'awon oṣiṣẹ rẹ, ati gigunle awọn iwa ti lodi si ọrọ oṣiṣẹ eleyii ti wọn ni o takọ ofin oṣiṣẹ labẹle ati lagbaye.
Ileeṣẹ Dangote ko tii fesu si awọn ẹsun naa.
Pataki ẹka epo rọbi ninu eto ọrọ aje Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹka ipọnpo ati afẹfẹ gaasi ni igi lẹyin ọgba fun ọrọ aje Naijiria pẹlu idiyele ojilelugba biliọnu dọla ($240b).
Awọn ile ati ileeṣẹ gbogbo lo nilo epo gẹgẹ bi ohun amuṣagbara fun ẹrọ amunawa wọn.
Bakannaa lawọn awakọ pẹlu nilo rẹ lati fi gbe ọkọ wọn ro.
Awọn awakọ ti ṣalaye ẹdun ọkan wọn lori itaporogan ti waye laarin awọn igun mejeeji yii, eyi ti wọn sọ pe o le tun wa ọwọngogo epo ati ẹkunwo ọkọ jakejado Naijiria.
Ẹwẹ, minisita fun eto ilera pẹlu ti sekilọ pe iyanṣẹlodi NUPENG yoo ni ipa to le lara awọn ileewosan kaakiri Naijiria, nitori ida ọgọrin ninu wọn lo jẹ pe ẹrọ amunawa ni wọn n lo.
Adehun ti awọn mejeeji t'ọwọ bọ laa kalẹ pe gbigba awọn oṣiṣẹ sinu ẹgbẹ oṣiṣẹ yoo bẹrẹ lẹyẹ-o-ṣọka, yoo si waye fun ọsẹ meji.












