You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo ọ̀kan lára àwọn ‘Áńgẹ́lì ìránṣẹ́ ikú’, tó ń túfọ̀ fáwọn èèyàn Israel
- Author, Julia Braun
- Role, BBC World Service
- Reporting from, São Paulo
Ileeṣẹ ologun Israeli n ṣe eto iranwọ pataki fawọn mọlẹbi to padanu eeyan ninu ikọlu ti ologun n sẹ sawọn ti wọn pe ni agbesunmọmi.
Lara eto yi ni pe ọmọ ogun kan yoo ṣabẹwo si wọn lati tufọ iku ẹni ti wọn ba padanu.
Ṣugbọn latigba ti ikọlu Hamas ti ṣeku pa awọn to din diẹ ni ẹgbẹrun kan ati aabọ, niṣe ni iṣẹ gbomi fawọn to wa nidi eto yi ju tatẹyin wa lọ.
Tori eyi, awọn oṣiṣẹ ologun Israel Defense Forces (IDF) ti wọn kii ba wọn ṣe iru iṣẹ yi tẹlẹ ni wọn ti n pe bayii lati wa kun wọn.
*Rafael, to jẹ ọmọ bibi orileede Brazil wa lara awọn ẹṣọ ogun ti wọn pe.
Lati ọjọ kẹtala, oṣu kẹwaa, lo ti jẹ pe o kere ju, yoo ṣabẹwo si idile mẹta to ba padanu eeyan lati lọ tufọ fun wọn.
O sọ fun BBC pe ''Igbakigba ti mo ba kan ilẹkun ile awọn mọlẹbi wọnyii, niṣẹ ni mo maa n dabi angẹli iranṣẹ iku”,
“Ṣugbọn ohun ti mo mọ daju ni pe iṣẹ yii ṣe pataki pupọ, nitori pe yoo fi ọkan awọn mọlẹbi awọn to padanu ẹmi wọn balẹ lati mọ aridaju ohun to ṣẹlẹ, ki wọn si le tete sin wọn.”
Igba akọkọ ree ti Rafael yoo gba iru iṣẹ bayii lati igba to ti darapọ mọ iṣẹ ologun.
Lati ọdun mẹrinla ti Rafael ti wa ninu iṣẹ ologun Israel ẹka eto ofin wọn ni ọmọ bibi ilu Rio de Janeiro naa ti n ṣiṣẹ pẹlu IDF.
“Awọn kan wa ninu iṣẹ ologun yii to jẹ pe iṣẹ ti wọn yan wọn fun ree latilẹ ṣugbọn nigba ti iye awọn to n ku ti kọja odiwọn ti wọn lero, ni wọn ṣẹṣẹ mọ pe awọn oṣiṣẹ ologun ti wọn ti ṣe idanilẹkọọ iru iṣẹ bayii fun ko to nnkan.”
Rafel ni oun la idanilẹkọọ oni wakati mẹrin kọja ko to di pe wọn gbe iṣẹ naa le oun lọwọ.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “Nigba ti a n gbaradi fun iṣẹ yii, paapaa ni ọsẹ akọkọ, wọn jẹ ko ye wa pe o le maa mu ki ara wa gbọn tori aisokun tabi airorun sun daada. Ohun to si n ṣẹlẹ ree nitori pe o maa n ṣoro fun wa lati sun tabi jẹun.''
“Ṣugbọn sibẹ, mo ni lati maa jẹ ounjẹ mi, ki n si maa gbiyanju lati sun oorun, nitori pe bi mi o ba ṣe bẹẹ, awọn mọlẹbi meji, mẹta, mẹrin yoo wa ti wọn ko nii gba iroyin nipa awọn eeyan wọn to wa loju ogun.''
Rafael tẹsiwaju pe lara awọn abẹwo toun ṣe, eyi to fọwọ kan oun lẹmi l’awọn eyi toun ṣe lọ sile mọlẹbi awọn to ni awọn ọmọde, paapaa awọn ọdọlangba.
Ninu rẹ, o loun ni lati tufọ iku ọmọdebinrin, ọmọ ọdun mẹtadinlogun fun baba rẹ.
Ọmọbinrin naa n ṣe faaji lọwọ pẹlu ọrẹkunrin rẹ nitosi odo igbafẹ Gaza, nigba ti awọn Hamas kọlu wọn.
“Nigba ti a tufọ iku naa fun baba rẹ, baba naa sọ pe oun ti ri aworan ọmọ oun lori ẹrọ amohunmaworan, pẹlu awọn kan ti wọn sọ pe wọn jigbe.
“O ni oun ṣi ni ireti wi pe bi wọn ba ji eeyan gbe, o ṣi ṣeeṣe ko wa laye.”
Irin ajo miran ni ti abẹwo to ṣe lọ si ile awọn obi arabinrin, ẹni ọgbọn ọdun kan ti wọn lọ pa mọ ile rẹ, ti ọkọ rẹ si ti di awati.
“Awọn ibeji, ọmọ oṣu mẹwaa ni wọn fi silẹ lọ, idi ti awọn ibeji yii si fi wa laye ni pe awọn obi wọn ti tete daabo bo wọn, wọn si ti ko wọn pamọ ko to di pe awọn agbesunmọmi naa de.
“Ipenija nla ni; Gbogbo igba lkan mi maa n ronu nipa awọn mọlẹbi yi. Wọn jẹ obi ti wọn ko tun ni f’oju kan awọn ọmọ wọn mọ, wọn tun jẹ awọn ọmọ ti wọn yoo dagba lai si awọn obi wọn.”
Rafael tun fi kun ọrọ rẹ pe pupọ awọn mọlẹbi awọn to padanu ẹmi wọn ninu ikọlu ọjọ keje, oṣu kẹwaa yoo ni lati duro fun ọpọ ọjọ ko to di pe wọn le gbo iroyin iku eeyan wọn.
“O maa n ṣoro lati da awọn oku wọnyi mọ, nitori pe pupọ wọn ni ko ṣee da mọ rara ati rara. Fun idi eyi, iroyin iku maa n ṣoro lati mu lọ f’awọn mọlẹbi wọn.''
“Awọn to le ni ẹgbẹta ni wọn ti sọnu, to si ṣe ni laanu pe pupọ wọn lo ti ku, ṣugbọn lati da oku wọn mọ lo ṣi n jẹ iṣoro bayii.”
Ikọlu ọjọ keje, oṣu kẹwaa jẹ ogun atẹyinja, eyi to ga julọ, to ti ṣẹlẹ si Israel lati ọpọlọpọ ọdun sẹyin.
Awọn ikọ Hamas fọ gbogbo ogiri ti wọn fi mọ odi Gaza yika lati ṣe ikọlu si awọn abule.
Nibẹ ni wọn ti pa awọn ti ko din ni ẹgbẹrun kan ati aabọ eeyan, ti wọn si tun ji awọn eeyan to le ni igba gbe.
Bakan naa ni awọn jagunjagun yin ado oloro lati Gaza, eyi to ba awọn ilu to wa ni jina titi to fi de Tel Aviv ati Jerusalem.
Ni esi tawọn naa fi dawọn lohun ikọlu yi, Israel naa yin ado oloro si Gaza lẹyin ọjọ diẹ ti ikọlu yii waye.
Awọn to din diẹ ni ẹgbẹrun mẹta (2,700) ni wọn ibugbamu ado oloro ti Israel yin lọjọ Aje, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹwaa.
Siwaju sii, ninu ohun ti ijọba Palestine sọ, wọn sọ pe awọn eeyan to to ẹgbẹrun kan ni wọn ti di awati latigba ti ado oloro naa ti sọkalẹ sori awọn ile to jona.
Ni ọpin ọsẹ to kọja, awọn ologun orileede naa tun kede sita pe awọn ti n gbaradi lati ṣe ikọlu tuntun si ilẹ, omi ati afẹfẹ Gaza.
Awọn Israel si ti sọ fun awọn miliọnu kan le ara Palestine ti wọn n gbe lagbegbe Ariwa Gaza lati tete lọ si agbegbe Guusu Gaza, ki ikọlu ti wọn fẹẹ ṣe ma baa ba wọn nibẹ.
Wahala ikọlu yi to sọ ọpọ di atipo ni agbegbe Palestin e yi n peleke si ti awọn alẹnulọrọ si n jaya pe yoo tan kaakiri de awọn orileede mii bi Lebanon ati Iraq.
*BBC mọọmọ fi orukọ bo ọgagun taa ba sọrọ laṣiri ni lati le daabo bo ẹmi rẹ