You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ FUTA gbé igi dínà l'Ondo nítorí àfikún owó ilé ẹ̀kọ́ wọn
Gbogbo awọn oṣiṣẹ ileẹkọ fasiti imọ ẹrọ Federal University of Technology, Akure ni ko rọna wọle laarọ ọjọ aje ni bi awọn akẹkọọ ile ẹkọ naa ṣe ti ọna abawọle sileẹkọ naa.
Awọn akẹkọọ naa ti wọn n ṣe ifẹhonu han tako afikun owo ileẹkọ wọn ni wọn fa idaduro ọkọ ni popona Akure si Ilesa latari bi wọn ṣe n se iwọde laarin ọna naa.
Awọn akẹkọọ ọun lo wi pe owo ti wọn n san tẹlẹ lo le diẹ ni ẹgbẹrun lọna ọgban naira amọ tawọn alaṣẹ ileẹkọ naa sọ iye owo naa di owo to le ni ẹgbẹrun lọna aadoje naira fun awọn to wa nileẹkọ tẹlẹ, ti awọn to fẹẹ wọle si saa akọkọ yoo si san ẹgbẹrun lọna ojilerugba naira.
Ninu ọrọ rẹ sawọn akẹkọọ nibi iwọde naa, aarẹ awọn akẹkọọ ni fasiti naa, Olayemi Oluwasoromidayo, wi pe afikun naa ko bawọn lara mu rara nitori ọrọ aje to dẹnukọlẹ.
Olayemi wi pe “a ko wa lati waa bawọn adari ileẹkọ wa ja nitori afikun yii, bi ko ṣe lati waa bẹ wọn.
“A ti n bẹ wọn labẹle tẹlẹ ka too waa ṣe iwọde ifẹhonu han yii amọ a fẹẹ kawọn araalu tun ba wa bẹ wọn.
“Ko tii pe ọdun kan ti wọn fi kun owo ọhun. Ki lo sare ṣẹlẹ ti wọn tun n ṣe afikun to toyi ni kia?”
Aarẹ awọn akẹkọọ naa wi pe o yẹ kawọn alaṣẹ o ro tawọn obi ati bi igboro ṣe ri ki wọn too ronu afikun kankan.
Awọn alaṣẹ FUTA sun ọjọ iwọle awọn akẹkọọ siwaju lẹyin ifẹhonu han
Awọn alaṣẹ fasiti naa lo ti fesi si iwọde awọn akẹkọọ ọun pẹlu lile awọn akẹkọọ to wa ninu ọgba naa sile.
Atẹjade kan latọwọ adari ẹka ikede ni fasiti naa, Adebanjo Adegbenro, wi pe “awọn alaṣẹ Federal University of Technology Akure, FUTA, ti sun ọjọ iwọle awọn akẹkọọ fun saa ẹkọ 2023/2024 siwaju.
“Wọn ti paa laṣẹ pe kawọn akẹkọọ to wa ninu ọgba ileẹkọ naa o kuro laarin wakati mẹrinlelogun.
“Bakan naa ni wọn tun paa laṣẹ pe ki idaduro o ba iforukọsilẹ awọn akẹkọọ lori ikanni ayelujara ati sisan owo ileẹkọ to yẹ ko bẹrẹ lọjọ Aje, ọjọ kẹẹdogun, oṣu kini ọdun yii.
Adegbenro wi pe ileẹkọ naa ko tii ṣi ikanni ayelujara rẹ fun awọn akẹkọọ to fẹẹ pada wọle lati maa fi orukọ silẹ gẹgẹ bi awọn kan ṣe n sọ kiri.
“Afikun ti wọn n sọrọ nipa rẹ lo wa fun awọn akẹkọọ tuntun ju awọn to n pada wọle lọ, to si jẹ pe awọn ohun ti a n ṣe lọdọ awọn araata, ti wọn si ti gbowo lori nitori bi ita ṣe ri.
“Ki gbogbo nkan o lee lọ deede, awọn nkan bii ina, omi, atunṣe ile awọn akẹkọọ ati imọtoto inu ọgba, to fi mọ awọn nkan miran lo ṣe pataki ti owo wọn si ti wọn ju ti atẹyinwa lọ.
“Lara awọn ohun taa tun fowo kun ni ayẹwo ilera fawọn akẹkọọ tuntun, kaadi idanimọ igbalode ati eto adojutofo nipa eto ilera fawọn akẹkọọ ileẹkọ giga, to fi mọ iwe ẹgbẹjọda fawọn akẹkọjade.
“O ṣe pataki lati jẹ ki awọn eeyan mọ pe a ko gba owo ileẹkọ lọwọ ẹnikẹni nitori pe ọfẹ ni.”