You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ẹ dákun, ẹ yé bímọ 100 láàrin oṣù kan - Ààrẹ Tanzania rawọ́ ẹ̀bẹ̀
Aarẹ orilẹede Tanzania, Samia Suluhu Hassan ti sọ ẹdun ọkan rẹ lori bi ọmọ bibi ṣe wọpọ, to si rọ awọn obinrin lati fetosọmọbibi lawujọ wọn.
Igbesẹ yii lo fihan pe Aarẹ Hassan ko fara mọ ero Aarẹ tẹlẹ lorilẹede Tanzania, John Magufuli, ẹni to gba awọn obinrin nimọran lati maṣe feto sọmọ bibi.
Aarẹ Samia ṣe abẹwo si Geita, ni iwọ oorun Tanzania lati ki awọn ọmọ tuntun ti wọn sẹsẹ bi kaabọ.
“Wọn sọ fun mi pe ni wọọdi Buselesele ni Geita, ile wosan kan, ọgọrun un ọmọ ni wọn bi nibẹ laarin osu kan.
Aarẹ ana ni Tanzania lo ni kawọn obinrin gbagbe ifetosọmọbibi
“Ni bayi, yara ẹkọ melo ni a ma nilo lẹyin ọdun mẹta si akoko yi, Ile wosan n kọ, melo ni a lilo lati se afikun rẹ lati ṣe itọju awọn ọmọ wọnyi?
Ike ounjẹ melo ni a lilo? Ẹ jẹ ki a ṣe adikun, ki a si lọ ṣe ifetosọmọbibi.”
Lọdun 2018, nibi ipolngo kan, aarẹ tẹlẹ Magaufuli sapejuwe awọn to ṣe ifetosọmọbibi gẹgẹ bi ọlẹ.
Bakan an lọdun 2016, lẹyin ti wọn ṣe ifilọlẹ ẹkọ ọfẹ ni Tanzania, o ni “Obinrin le gbagbe ifetosọmọbibi nitori ọfẹ ni ile ẹkọ.”
Iwadi Banki agbaye lọdun 2020 safihan pe ọpọ awọn oninrin ni wọn tete bimọ nitori pe wọn tete lọ sile ọkọ.
Bakan naa ni awọn obinrin orilẹede Tanzania kuna lati lọfeto sọmọ bibi.
''Kò dín ní agbésùnmọ̀mí 101 tó ronúpìwàdà tó ti kúrò lẹ́wọ̀n''
Ijọba apapọ ti kede pe awọn ti tu awọn agbesunmọmi mọkanlelọgọrun to ronupiwada silẹ kuro kuro lọgba ẹwọn.
Awọn wọnyii ni wọn yoo gbe lọ si ileeṣẹ ti wọn ti n tun ero awọn eniyan pada si ti awujọ (deradicalisation Camp), ki wọn to ṣẹṣẹ wa da wọn pada si awujọ.
Adari ileeṣẹ eto aabo ni Naijiria, Ọgagun Lucky Irabor lo sọ bẹẹ nibi ipade ajọ eto aabo orilẹede Naijiria ni ilu Abuja.
Awọn miran to wa nibi ipade naa ni Minisita fun eto abẹle, Rauf Aregbesọla, Minisita fun ileeṣẹ ọlọpaa, Mohammed Dingyyadi, ti aarẹ Buhari si ṣe alaga ipade naa.
O ti le ni ọdun mẹwaa ti ikọ Boko Haram ati ISWAP ti n ṣọṣẹ lorilẹede Naijiria
Ọpọlọpọ awuyewuye lo ti waye lẹyin ti ijọba fi awọn agbẹsunmọmi mọkanlelọgọrun naa silẹ.
Awọn agbesunmọmi yii pẹlu awọn to ṣọṣẹ ni oju irin Kaduna ni Ọjọ Kejidinlọgbọn, ki wọn to doola ẹmi awọn eniyan ni Ọjọ Karun, Oṣu Kẹwaa, ọdun yii.
Irabor ninu ọrọ rẹ ni awọn wọnyii n gba itọju lọwọ paapaa lọna ti wọn yoo fi pada si awujọ awọn eniyan lai si iṣoro kankan.
O fikun un pe awọn ti wọn tu silẹ yii ti lo ọpọlọpọ ọdun ni ọgba ẹwọn, ti wọn si ti lo iye ọjọ to yẹ ki wọn lo ni ọgba ẹwọn pari.
Ninu ọrọ rẹ tirẹ, Aregbesọla ni wọn gbe awọn wọnyii kuro ni ọgba ẹwọn pẹlu aṣẹ ileẹjọ, wi pe ki wọn tu wọn silẹ.
O ti le ni ọdun mẹwaa ti ikọ Boko Haram ati ISWAP ti n ṣọṣẹ lorilẹede Naijiria, ti wọn si ti gbẹmi ọpọlọpọ eniyan.
Amọ ninu ọrọ rẹ, Aarẹ Buhari ni awọn yoo tẹsiwaju lati wa ọna abayọ si igbesunmọmi naa, ki o le dopin, ki awọn le wa ni isinmi.