You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ẹbí fi mí ṣe ẹlẹ́yà torí mo yan iṣẹ́ télọ̀ láàyò sí ẹ̀kọ́ ìwé
Celebrity Taylor: Iléẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ni mo ti kọ́ṣẹ́ Télọ̀, mò ń ránsọ fún Tope Alabi, Uche Jumbo, Nice ...
Ori lo mọ isẹ asela, kadara ko si ni se alaisẹ nitori ati ọrun ni koowa ti mu ayanm rẹ wa sile aye.
Obinrin kan, Ruth Olajide ree to nifẹ si isẹ asọ riran lati kekere, nigba to wa nile ẹkọ alakọbẹrẹ, to si bẹrẹ si foju si isẹ naa.
Nigba to de ile ẹkọ girama, ti baba rẹ ri pe ọkan rẹ fa si isẹ tel ju ẹkọ kiwe lọ, o ni oun pinnu lati yan ẹkọ iwe, ti awọn ẹgbọn ati baba rẹ si n tabuku rẹ tori isẹ to yan laayo naa.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Ruth Olajide ni se ni awọn ẹ́gbọn ohun maa n se ẹlẹya pe ẹwa aganyin ni oun maa ta nigbẹyin nitori pe oun ko lọ sile ẹkọ.
"Mo maa n sọ fun awọn ẹgbọn mi to lọ sile ẹkọ pe maa ni owo lọwọ ju wọn lọ nidi isẹ asọ riran"
Gbajumọ aransọ naa tẹsiwaju pe “Amọ mo maa n sọ fun wọn pe maa ni owo lọwọ ju wọn lọ, nigba to ya, emi ni mo n fun wọn ni owo ọkọ lọ sile ẹkọ Poly.”
Bakan naa ni baba mi kọ lati ran mi nile iwe tori ifẹ ti mo ni si isẹ asọ riran, sugbọn nigba to ya, ko kan le tọrọ aforijin lọwọ mi ni, tori iwa to hu si mi.”
Ruth Olajide ni bi ohun ba fun baba oun ni owo, oun kan se ojuse ọmọ si obi ni nitori pe owo naa ko tọ si ta ba wo iwa to hu si oun.
Nigba to n darukọ awọn eeyan nla nla to ti ransọ fun, gbajumọ aransọ naa ni oun ni telọ Tope Alabi, Uche Jumbo, Bella Adenuga, Nice ati bẹẹ bẹẹ lọ.