Ọ̀gá àgbà fún Iléeṣẹ́ ètò ààbò Àmọ̀tẹ́kùn n'Ìpínlẹ̀ Ogun, David Akinremi jáde láyé

Ọga agba pata fun ileeṣẹ eto aabọ Amọtẹkun n'ipinlẹ Ogun, David Akinrẹmi ti jade laye.

David Akinrẹmi ni iroyin fi to wa leti wi pe o jade laye l'ọjọ Aje tii ṣe Mọnde, ọsẹ yii, lẹyin aisan rampẹ ti wọn lo kọluu.

Ọkunrin naa to fẹyinti gẹgẹ bii Kọmiṣanna ọlọpaa ni Gomina Dapọ Abiọdun yan lati di ipo ọga agba fun ẹṣọ aabo Amọtẹkun n'ipinlẹ naa mu lọdun 2021.

BBC YORUBA gbọ pe o ti ṣe diẹ ti ọkunrin naa ti n ba aisan kan ti ko han si ọpọ eeyan finra, aisan ọhun ni wọn loo pada ran an lọ sajule ọrun lọjọ Aje, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹfa, ọdun 2023.

Nigba to n f'idi iroyin ọhun mulẹ f'awọn akọroyin, ọga agba fun ileeṣẹ eleto aabo ipinlẹ Ogun ti a mọ si So-Safe Corps, Olusọji Ganzallo sọ pe adanu nla ni iku Akinrẹmi jẹ, paapaa lasiko yii.

Ganzallo sọ pe ojiji ni iku ọhun jẹ, nitori pe ohun t'awọn ko ro ti tẹlẹ ni, to si ṣapejuwe oloogbe naa gẹgẹ bi ẹni to mu iṣẹ eto aabo lokukudun pupọ.