Kí ló dé tí Peller fi kúrò lẹ́yìn Adelabu àti Folarin, tó ń "kọrin Seyi Makinde ni o"?

Bi eto idibo gomina ipinlẹ Oyo se n sumọ bẹẹ naa ni awọn ohun iyalẹnu n jẹyọ sita lori tani yoo jawe olubori ninu eto idibo naa.

Ṣaaju oṣu yii ni awọn ẹya kan ninu ẹgbẹ oṣelu Accord Party ya kuro lẹyin oludije sipo gomina, Adebayo Adelabu, ti wọn si to sẹyin oludije miiran.

Ọpọlọpọ awọn oloṣelu lo ti n ya kuro lẹgbẹ oṣelu kan si omiran, ti wọn si n kede pe awọn ti to sẹyin oludije miiran yatọ si ẹni ti wọn mọ wọn mọ.

Ọmọ ile igbimọ aṣojuṣofin orilẹede Naijiria, Shina Peller, to n soju ẹkun ijọba lseyin/ltesiwaju/ Kajola/lwajowa to tun jẹ oludije to lulẹ ninu idibo ile igbimọ asofin ni oṣu to kọja pẹlu ẹgbẹ oṣelu Accord ni oun ti kuro lẹyin oludije ẹgbẹ oṣelu rẹ, to si tun bọ sẹyin Gomina Seyi Makinde fun saa keji.

Ipinu ati igbesẹ waye lẹyin ti Shina Peller padanu sọwọ oludije ipo Sẹnetọ lati inu ẹgbẹ oṣelu APC, Fatai Buhari.

Peller lo binu kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APC lẹyin to fi ẹsun kan oludije Sẹnẹtọ pe o fi ọna eru bori eto idibo abẹle APC.

Nigba ti o n ba awọn eeyan sọrọ niluu Iseyin, Peller ni oun ko tii ri gomina kankan to ni irufẹ aṣeyọri Gomina Seyi Makinde ni Oke Ogun ati paapa nipinlẹ Oyo.

O ni asiko ti to lati sọ otitọ ọrọ ti awọn ẹgbẹ oṣelu kan fẹ fi imọtara ẹni nikan ko ba awọn eeyan ipinlẹ Oyo.

"Ẹ ko tii ri gomina to ṣe to Gomina Seyi Makinde ni apa Oke Ogun.

"A ni lati sọ otitọ ọrọ nitori ti a ba sọọ, aa ku, ti a ko ba si sọọ, a ṣi maa ku.

"Seyi Makinde ni aa tẹle."

Ki lo sẹlẹ saaju laarin Peller ati Folarin?

Iroyin ni Shina Peller fẹsun kan Teslim Folarin pe o ran awọn janduku ati agbanipa kan lati gbẹmi oun amọ oun moribọ.

Ṣugbọn Folarin fesi ninu atẹjade kan pe irọ nla gbaa ni ọrọ naa ati pe oun kii ṣe apaniyan, bẹẹ si ni oun ko ni awọn apaniyan kankan ni ikawọ tabi ran ẹnikẹni lati gbẹmi Peller.

Ṣaaju ni fidio kan ti kọkọ n tan kalẹ lori ayelujara, nibi ti awọn agbofinro ti mu awọn janduku kan loju ọna Iseyin.

Fidio ọhun ṣafihan awọn ọkunrin bii mẹrinla ti ọwọ awọn agbofinro tẹ, ti awọn afurasi naa si ni awọn ohun elo ipolongo ti wọn kọ orukọ Sẹnetọ Teslim Folarin si lara.

Lara awọn ohun elo ipolongo ibo naa ni ọkọ ayọkẹle, awọn fila, atawọn nnkan mii.

Oṣojumikoro kan sọ fun awọn akọroyin pe Teslim Folarin gan funra rẹ lo ṣaaju awọn afurasi janduku naa lati wa da ilu Iseyin ru nitori ọrọ ibo.

SDP kede Folarin gẹgẹ bi oludije ẹgbẹ oṣelu naa

Bakan naa ni Ẹgbẹ oṣelu SDP kede pe awọn ti yan oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Teslim Folarin gẹgẹ bi oludije wọn dipo ẹni ti tẹlẹ.

Alaga ẹgbẹ oṣelu naa, Michael Okunlade ninu ipade ti wọn ṣe pẹlu awọn alaga ijọba ibilẹ ẹgbẹ oṣelu naa

Okunlade ni awọn ti pinnu lati maa dibo fun Gomina Seyi Makinde lori bi o ṣe ja wọn kulẹ lọdun 2019.

O tẹsiwaju pe ipe fun awọn alatilẹyin wọn lati dibo fun Teslim Folarin ni o mọ ni ipo gomina nikan, to si rọ wọn lati dibo fun awọn ọmọ yooku to n dupo kan tabi omiran.

"A ni igbagbọ pe ohun ti a se yii lo jẹ ohun ti yoo mu idagbasoke de ba ipinlẹ Oyo ati lati gba agbara lọwọ ijọba to kuna lati ṣe ohun to tọ fun ilọsiwaju ipinlẹ Oyo.

"Ipinnu wa dale ohun ti yoo mu ilọsiwaju ba ipinlẹ Oyo, ti a ri pe Teslim Folarin nikan to kaju ipo naa."