Ìkọlù Owo bá wa lójijì, ọ̀pọ̀ nínú wa ti sálọ torí ìbẹ̀rù ẹ̀san - Àwọn Hausa

Awọn ọmọ ilẹ Hausa to n fi ilu Owo ṣebugbe ti ba BBC Yoruba sọrọ lẹyin iṣẹlẹ iṣekupani to waye nile ijọsin St Francis Catholic Church, to wa ni adugbo Owaluwa lọjọ Aiku.

 Wọn ni iṣẹlẹ naa jẹ eyii to ba awọn lojiji, ọpọ ninu awọn lo si salọ lẹyin ikọlu ọhun nitori ibẹru pe awọn ọdọ ilu Owo le kọlu awọn.

 Wọn ni awọn ko laye pe irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ le waye niluu Owo, inu ibẹrubojo si ni awọn si wa bayii.

 Ohun ti a foju ganni ninu ọja

 Nigba ti akọroyin BBC Yoruba ṣabẹwo sinu Ọja Ọba lẹyin iṣẹlẹ naa, niṣe ni inu ọja naa da paro bi igba ti ọfọ ba sẹ.

 Bo tilẹ jẹ pe awọn onitaja kan ti n ṣi ilẹkun ṣọọbu wọn, ti wọn si ti n ta ọja, ọpọ ninu awọn iyalọja naa ni ko tii ṣi ṣọọbu.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu diẹ lara awọn to n ta ọja ninu Ọja Ọba naa, wọn ni ibẹru to wa lọkan awọn eeyan ni ko tii jẹ ki ọpọ wọn ṣilẹkun, ati pe ọpọ ninu awọn to n ta ọja ni wọn padanu awọn eeyan wọn sinu ikọlu ọhun.

Ki ni awọn Hausa sọ?

Ọkan lara awọn Hausa to n ta ọja lati ipinlẹ Zamfara, amọ ti wọn bi siluu Owo, Yusuf Sani, sọ pẹ irẹpọ to dan mọran lo wa laarin awọn ẹya Hausa atawọn ọmọ ilu Owo ṣaaju iṣẹlẹ ọhun.

 O ni “Ilu Owo ni wọn bi mi si, ibẹ si ni mo ti pari ile ẹkọ alakọbẹrẹ ati ile ẹkọ girama mi, ibarẹpọ to mọran lo wa laarin awọn Hausa ati Yoruba ṣaaju iṣẹlẹ naa, wọn ko gbogun ti awọn Hausa, ko si si ija laarin ẹya mejeji.”

 “Amọ gẹgẹ bii ohun ti mo gbọ, wọn ni awọn ọdọ kan wọ inu ọja yii lati ba awọn ọja Hausa jea lẹyin ikọlu naa, amọ lẹyin ti Gomina ba awọn araalu sọrọ lati maṣe kọlu awọn Hausa to n wa nnkan ti wọn maa jẹ, awọn ọdọ naa dawọ ikọlau ọhun duro.”

 Sani tẹsiwaju pe “Ti wọn ba tilẹ sọ pe awọn Fulani lo ṣe ikọlu naa gan, awọn yii Fulani yii yatọ si awa Hausa, nitori awọn Fulani naa n gbogun ti awa Hausa funra gan ni ilu wa lọhun.”

 “Ọpọ awọn Hausa lo salọ kuro niluu Owo lọjọ Aiku ti ikọlu naa ṣẹlẹ fun ibẹru ẹmi wọn nitori wọn gbabọ pe awọn ara ilu anaa le kọlu wọn.”

Ọja ko ri bii ti tẹlẹ mọ

 Ni ti bi ọja naa ṣe maa n ri ṣaaju iṣelẹ naa, Sani sọ pe ṣe ni Ọja Ọba naa maa n kun fun ọpọ ero ati ọja, amọ wọn kọ lati ṣi ṣọọbu wọn.

 Ọmọ Hausa mii to tun ba BBC sọrọ lati ipinlẹ Sokoto, Abubakar Aliyu ni irẹsi, alubọsa ati ẹwa ni oun n ta niluu Owo.

 O ni oun wa ninu ọja lasiko ikọlu naa, amọ oun fi ọja silẹ ti oun si fẹsẹ fẹ lati doola ẹmi oun.

 Gẹgẹ bii ohun to sọ, awọn ọdọ to kọlu ọja naa ba awọn nnkan ti awọn n ta jẹ.

 Amọ oni lẹyin ti Kabiesi ilu Owo, Ọba Gbadegesin Ogunye kẹta, ati Gomina Rotimi Akeredolu ba awọn eeyan sọrọ, wọn da ọwọ ikọlu naa duro.

 O pari ọrọ rẹ pe awọn Hausa inu ọja Ọba naa ko mọ ohunkohun nipa iṣẹlẹ ọhun, ati pe oun gbadura ki aṣiri awọn to wa nidi iṣẹlẹ naa yoo tu sita laipẹ.

Ìwádìí ọlọ́pàá tọ́ka sí lílo adó olóró àti nǹkán míì níbi ìkọlù Owo

Iṣẹlẹ ikọlu agbebọn to waye ni ipinlẹ Ondo lopin ọsẹ to kọja ti bẹrẹ si ni lojutu sawọn agbofinro.

Eyi ko sẹyin bawọn ọlọpaa ti ṣe gbe abajade iwadii ibẹrẹ jade eleyi to tọka si pe awọn agbebọn to ṣe ikọlu si ile ijọsin St. Francis Catholic Church, Owaluwa, Owo lo ado iku atọwọda taa mọ si Improvised explosive device,IED.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa lorleede Naijiria Muyiwa Adejobi lo fidi ọrọ yi mulẹ ninu atẹjade kan to f sita ni ilu Abuja.

Gẹgẹ bo ṣe wi ninu atẹjade yi,''awọn agbebọn yi bi iwadii ibẹrẹ wa ti se fi han se amulo nkan ija ati awọn nkan ibugbamu ado oloro lati fi kọlu ile ijọsin naa ni Owo''

Ọpọ ẹmi lo ṣofo ninu ikọlu yi tawọn ọpọ eeyan si farapa lorisirisi.

Olumuyiwa Adejobi sọ pe ''awọn oluwadii ọlọpaa wa lara awọn to kọkọ de ibi ikọlu naa nibi ti wọn ti ri aṣẹku ọta ibọn AK-47 nigba ti ikọ to n se iwadii lilo ado oloro naa si fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni wọn lo awọn ado oloro''

O tẹsiwaju pe '' lẹyin ti awọn naa ri aṣẹku ado oloro ati awọn ado oloro mẹta kan ti wọn ko ti yin nibi iṣẹlẹ naa''

Bakan naa Olumyiwa fi kun ọrọ rẹ pe ''iwadii tọka si pe awọn afurasi yi darapọ mọ awọn olujọsin ninu sọọsi ti awọn agbebọn mii si rọ yika ile ijọsin naa ti wọn si ṣina ibọn fawọn olujọsin''

Lori bi awọn afurasi naa ti ṣe ribi salọ, Olumuyiwa ni '' ọkọ Nissan Sunny pẹlu nọmba idanimọ AKR 895 AG ti wọn ja gba lọwọ eeyan kan ni wọn gbe salọ gba oju ọna Owo/Ute''

O ni awọn ti ri ọkọ naa ati pe ẹni to ni ti wọn ja gba mọwọ ti n ran awọn lọwọ ninu iwadii wọn.

Esi iwadii yi foju jọ ọrọ ti awọn ti iṣẹlẹ naa soju wọn sọ fun ileesẹ iroyin BBC ni paapa wi pe awọn agbebọn yi ju ado oloro dynamite lu awọn olujọsin naa ninu sọọsi.

Ileesẹ ọlọpaa lawọn ṣi n tẹsiwaju pẹlu iwadii amọ wọn ko ti sọ boya ọwọ ti tẹ ẹnkankan ninu awọn to hu iwa buruku yi.