You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ẹ má tíì kánjú, ẹ ṣe sùúrù - Tinubu rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà
Aarẹ orileede Naijiria, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu ti gba gbogbo awọn ọmọ ati olugbe orileede yii ni iyanju lati ṣe suuru fun un ninu eto iṣejọba rẹ bẹrẹ lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun 2023.
O ni ohun gbogbo lo ṣi maa bọ soju ẹ gẹgẹ bi ireti awọn araalu, ti wọn yoo si gbadun mudunmudun eto oṣelu awarawa.
Aarẹ Tinubu sọrọ yii niluu Abẹokuta, lasiko to n ṣe abẹwo to ṣe lọ sọdọ Alake ilẹ Ẹgba, Ọba Michael Adedọtun Arẹmu Gbadebọ.
Ṣaaju asiko yii ni Aarẹ Tinubu ti kọkọ lọ si ilu Ijẹbu-Ode, lọdọ ọba alaye ilẹ Ijẹbu, Ọba Sikirulai Adetọna, Awujalẹ.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe
"Ẹ jẹ ka tẹle igbesẹ ọmọde igbagbọ yii. Mo n lo ilana ọmọ kekere igbagbọ ni mo n lo gẹgẹ bi aarẹ. Ẹ ma ṣe jẹ ka kanju. Ẹ gbaradi fun ohun to fẹẹ ṣẹlẹ. Ẹ jẹ ki itura itusilẹ maa kaakiri na. Ẹ jẹ ki igboya yẹn pada.
"Orileede yii nikan la ni. Mo ti figba kan ri jẹ ẹni to n sa asala, mo si mo nnkan to tunmọ si.
"Nigba ti adura wa, 'Emi lo kan' ti gba, ohun ti mo n beere fun bayii ni adura fun Naijiria. Mo ti pinnu lati ran orileede yii lọwọ lati gbe ọkọ orileede yii dide, ki n si mu awọn ileri mi lasiko oṣelu ṣẹ.
"Mo wa sibi lati mu lara awọn ileri mi ṣẹ. Ko si iyatọ kankan laaarin awa ati awọn araalu. Mo sọ eyi lorileede France wi pe mọlẹbi kan naa la jẹ, ti a si n gbe ninu ile kan naa, bo tilẹ jẹ pe yara ọtọọtọ la n sun si.
"Ẹ jẹ ka wa ni iṣọkan, oṣuṣu ọwọ lai gbọ ariwo ọja. Ebute ayọ rere ni gbogbo wa maa pada ja si. Ojuṣe gbogbo wa ni lati fi itan balẹ. Lagbara Ọlọrun, a maa kore iṣẹ ọwọ wa. Naijiria yoo ri ayipada rere.
"Ẹ dakun, a nilo awọn adura yin, a nilo igbarukuti yin, a nilo idasi yin ki eto ọrọ aje orileede yii le ṣina rere fun gbogbo yin si daadaa"
Ẹ̀mí Awujalẹ ti mo gbé wọ̀ ló mú mi borí - Tinubu
Aare orilẹ-ede Naijiria, Bọla Ahmẹd Tinubu ti sọ pe ẹmi Awujalẹ ti oun gbe wọ lasiko eto idibo ọdun 2023 lo mu ki oun bori ninu eto idibo naa.
Tinubu sọ ọrọ naa ni Ọjọbọ, lasiko to se abẹwo si Ọba Sikirulai Adetọna, Awujalẹ ti ilẹ Ijẹbu, niluu Ijebu-Ode, ipinlẹ Ogun.
Aarẹ Tinubu ṣabẹwo si ipinlẹ Ogun lati dupẹ lọwọ awọn ọba fun ipa ti wọn ko lasiko eto idibo apapọ ọdun 2023, eyi to gbe e wọle gẹgẹ bi aarẹ.
Ni nnkan bi aago mẹwaa owurọ ni Tinubu balẹ si papa iṣere Dipọ Dina to wa niluu Ijẹbu-Ode ninu ọkọ Baluu agberapa tijọba apapọ, eyi ti nọmba idanimọ rẹ jẹ 5N FG2.
Lẹyin naa lo lọ si Aafin Awujalẹ.
Bi Tinubu ṣe de aafin Awujalẹ lo ti wọle lọ lati ba Kabiyesi naa ṣe ipade ikọkọ, eyi ti wọn ko gba awọn akọroyin laaye lati wọle.
Ṣugbọn nigba to n sọrọ lẹyin ipade naa, Aarẹ Tinubu jẹ ko di mimọ pe niṣe loun wa fi ẹmi imoore han si ọba naa fun ipa to ko lori aṣeyọri oun.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "ipinlẹ Ogun ni mo ti gbe ẹmi itusilẹ wọ. Ile ni mo pada wa, mo si jẹ yin ni ọpọlọpọ nnkan, paapaa lati dupẹ lọwọ yin.
"Nitori ọna ti ẹ gba lati dide si mi lati gba mi, mi o mọ ohun ti mo tun le sọ ju pe ẹ ṣeun.
"Si ọpọ ninu yin, ẹ ṣeun ti e duro ti ni, ti ẹ si tun duro ti Naijiria. Ẹ fi ifẹ otitọ ati ifarajin han, debi wi pe ẹ dibo lasiko ipenija.
"Wọn gbe owo yin pamọ, wọn ko jẹ ki ẹ ri owo na. Owo ti wọn paarọ ko pada ṣiṣẹ."
Tinubu ni riri ti oun ri igbesẹ naa, oun lọ si ipinlẹ Ogun lati gbe ẹmi itusilẹ ati akikanju, "eyi ti wọn mọ wa si wọ".
O ni igba mejiẹ ọtọọtọ ni oun gbe ẹmi naa wọ.
"Ẹmi Baba (Awujalẹ). Ẹmi Baba – Emi l’okan. Iyẹn ni ti Baba. Nitori pe niṣe ni Baba maa n sọ oju abẹ nikoo , bi Baba ṣe ri niyẹn.
"Ẹmi keji ni ti ẹmi owo to mu mi sọ pe 'A maa dibo, a maa wọle', koda lasiko ti ko si owo nita.
"Lati igba naa lo ti jẹ pe awọn ẹmi yii lo n fun mi ni okun lati sin orileede yii."
Ọdun mẹjọ ni Tinubu yoo lo n'ijọba - Awujalẹ
Awujalẹ nigba toun naa n sọrọ jẹ ko di mimọ pe ajọṣepọ to wa laaarin oun ati Tinubu kọja ohun ti ẹnikẹni le lero, nitori pe awọn ti jọ wa tipẹ.
Ọba Adetọna sọ pe oun wa lara awọn to fẹyin pọn Tinubu lasiko ti wọn fẹẹ le awọn ṣọja kuro nile ijọba lọjọsi, to si ni idi rẹ niyẹn ti wọn fi n pe oun ni Baba NADECO.
Siwaju sii lo sọ pe oun wa lẹyin Tinubu lati lo ọdun mẹjọ gbako lori ipo Aarẹ Naijiria, nitori pe awọn igbesẹ rẹ ti fi han daju pe Ọlọrun lo yan an lati gbe Naijiria de ilẹ ileri ti awọn awọn araalu n fẹ
Lara awọn to wa nibẹ ni Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun; Olori awọn oṣiṣẹ Aarẹ, Ọnarebu Fẹmi Gbajabiamila, Gomina tẹlẹri n'ipinlẹ Ogun, Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba; oludamọran pataki si aarẹ lori eto aabo, Nuhu Ribadu; ati Dele Alakẹ toun jẹ oludamọran pataki lori eto ikansira-ẹni.