You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Awakọ̀ tẹ agbálẹ̀ òṣìṣẹ́ LAWMA méji pa l'Eko
Awọn obinrin meji kan ti wọn jẹ oṣiṣẹ ajọ kolẹ-kodọti tawọn eeyan mọ si LAWMA nipinlẹ Eko ni wọn padanu ẹmi wọn laaarọ ọjọ Aje, ọjọ kẹtala oṣu kọkanla yii, lagbegbe Charlie Boy ni Gbagada.
Awakọ kan la gbọ pe o ṣokunfa iku ojiji naa, nigba to kọlu awọn obinrin naa lẹnu iṣẹ wọn.
Gẹgẹ bi ẹni kan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ṣe ṣalaye, ọkọ Sienna ni dẹrẹba to ṣekupa wọn naa n wa.
O ni ko sẹni to mọ ohun to fa a ti awakọ ọhun fi lọọ ba awọn obinrin meji naa nibi ti wọn ti n ṣiṣẹ wọn laaarọ kutu Aje.
O fi kun un pe awakọ naa kọlu wọn debii pe wọn ku lẹsẹkẹsẹ sibi ti wọn ti n tun oju popo ṣe ni.
Iṣẹlẹ naa da sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ silẹ loju ọna yii, awọn tiku awọn iya naa ka lara ni wọn di oju ọna marosẹ Gbagada-Oṣhodi, to si dohun ti ọpọ eeyan wa loju kan lai rọna lọ.
- Ọmọ-iṣẹ́ tó fi N64.4m ọ̀gá rẹ̀ fẹ́ ìyàwó tuntun dèrò ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún
- Ọwọ́ àjọ NDLEA tẹ afurasí tó ń fi ''wheelchair'' bojú ṣe kátà-kárà egbòogi olóró
- Àwọn òṣìṣẹ́ OAUTH gbéná wojú àwọn aláṣẹ nítorí gbèsè owó oṣù mẹ́wàá
- Kí ló dé tí Ìyá ọmọ 'Mummy Calm down' gbà ẹ̀mí ara rẹ́?
- Ikú àwọn ọmọ wa obìnrin méjèèjí nínú ìkọlù Israel àti Palestine ló sọ wa dí ọ̀rẹ́ bí ọmọ ìyá- Bassam àti Rami
Ajọ LAWMA kẹdun awọn oṣiṣẹ wọn to ku
Ninu atẹjade ti ajọ LAWMA fi sita lẹyin iṣẹlẹ yii ni wọn ti fi tẹdun-tẹdun kede iku awọn oṣiṣẹ wọn meji naa, ti wọn si gbe nọmba ọkọ naa ti i ṣe EPE 984 DV jade.
Wọn parọwa sawọn awakọ pe ki wọn yee sare lojuu popo, eyi to n fa iku ojiji fawọn eeyan ti wọn n ba tiwọn lọ jẹjẹ wọn.
Ajọ LAWMA ni kawọn eeyan fọkan balẹ lori iṣẹlẹ yii, nitori gbogbo igbesẹ ti yoo foju ododo han lawọn n gbe, awọn yii si mu awakọ to huwa ọdaran naa.
Wọn ba awọn ẹbi oloogbe mejeeji kẹdun, wọn si rawọ ẹbẹ s’Eledumare lati fọrun kẹ wọn.