Wo àwọn nǹkan tí o kò le è ṣe ninú bàálù àti ìdí tí arìnrìnàjò fi gbọdọ̀ pa fóònù rẹ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

O gbe ara rẹ sinu baaluu pẹlu ọpọ owo ti o san, boya nitori ijinigbe to wọpọ tabi nitori ati sare de ibi kan kiakia.

O jokoo, wọn bẹrẹ si i sọrọ nipa aabo rẹ, pe ki o de bẹliiti, bẹẹ ni awakọ baaluu tun n kede pe asiko ti to fun ọ lati lu foonu rẹ pa, ṣugbọn o kọ nitori o n wo fọnran kan lorii foonu rẹ lọwọ, o kọ jale.

Iwọ naa bi ara rẹ leere, se eyi bojumu?

Ọpọ iwadii lo ti fidi rẹ mulẹ pe foonu ati awọn ẹrọ mii le ṣe akoba fun baaluu lasiko irin ajo.

Gẹgẹ bi ofin baaluu wiwọ ṣe wa kaakiri agbaye, ẹrọ kankan ko gbọdọ wa ni titan silẹ lasiko ti baaluu ba wa ni oju ofurufu ni iwọn 3,000m (10,000ft). Koda, ipo 'flight mode' ni o gbọdọ fi foonu rẹ si.

Ṣugbọn sibẹsibẹ, ni oke ofurufu ti o wa, o le lo ẹrọ laptop tabi ki o gbọ orin, ṣugbọn foonu rẹ gbọdọ wa ni pipa.

Lorilẹede Amẹrika, ajọ to n risi irinajo ofurufu fofin de foonu nitori o le ṣe akoba fun baaluu lasiko to n fo lọwọ.

Wọn gbe ikilọ sita to ni, 'O le lo foonu rẹ to ba wa ni flight mode tabi ki o pa a''. Bakan naa lo le lo WiFi ti baaluu naa ba ni.

Ko wa ki n ṣe foonu nikan, bakan naa ni awọn ẹrọ bii 'Kindles ati ẹrọ ti wọn fi gba geemu naa ko ṣee lo pẹlu, nitori wọn ni afẹfẹ redio lori.

Ni ọdun 2006, iwadii kan ṣafihan, pe igba 77 ni foonu ti ṣakoba fun irinajo baaluu nitori awọn ẹrọ nla to wa ninu rẹ.

Ajọ International Air Transport Association (IATA), ṣafihan iṣẹlẹ 75 ọtọọtọ ti awọn awakọ baaluu gbagbọ pe foonu lo fa a lati ọdun 2003 ati 2009.

Akọroyin BBC, Katia Moskvitch, ṣalaye pe awọn ileeṣẹ baaluu ti n gbe idanilẹkọ jade lori bi awọn arinirinajo se le lo foonu wọn lasiko irinajo, ki n se asiko ti baaluu ba gbera tabi to balẹ nikan.

Nǹkan tí o kò lè ṣe nínú bààlúù

BBC kan si Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ijọba Nigeria lori irinajo afẹ, Civil Aviation Authority (NCAA), Michael Achimugu, lori ofin ati ilana to rọ mọ wiwọ baaluu, o si ṣalaye ọpọ wọn fun wa.

  • Mimu siga je nnkan ti aye ko gba rara ninu baaluu, koda, ijiya wa fun un labẹ ofin.
  • Lilo foonu ati awọn ẹrọ mii ninu baaluu lai gba aṣẹ lọwọ awọn alaṣẹ baaluu jẹ ẹsẹ nla.
  • Jija tabi kikọlu ẹnikẹni ninu baaluu lodi si ofin.
  • Dida wahala silẹ to le ṣe akoba nla fun awọn arin irinajo yooku jẹ ẹsẹ nla.
  • Kikọ lati tẹle ofin awakọ to n wa baaluu ati awọn oṣiṣẹ yooku.
  • Eyikẹyi iwa to lewu tabi to le fa ipalara fun awọn eeyan inu baaluu jẹ ẹṣẹ nla ti ofin ko gba laaye.
  • Gbigbe ibọn tabi igbiyanju lati gbe ohun ija wọ inu baaluu lodi si ofin, ayafi to ba jẹ irinajo naa faye gba a.
  • Mimu ọti ti ki se pe awọn oṣiṣẹ baaluu lo gbe e fun eeyan.
  • Yiya aworan awọn aaye ti ofin ko faaye gba si ori foonu rẹ