You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Diogo Jota, òdú agbábọ́ọ̀lù Liverpool jade láyé nínú ìjàmbá ọkọ́; Ronaldo, Liverpool ń dárò
Gbajumọ̀ agbabọọlu ọmọ orilẹede Portugal to tun n gba bọọlu jẹun ni ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool, Dogo Jota ti jade laye.
Diogo Jota jade laye ninu iṣẹlẹ ijamba mọto kan to waye ni ilu Zamora lorilẹede Spain gẹgẹbi Guardia Civil 'se fi idi rẹ mulẹ fun BBC.
Iroyin naa tun fi id rẹ mulẹ pe oun ati aburo rẹ lo ku ninu ijamba ọkọ naa.
Taya ọkọ Lamborghini to n wa lo fọ lori ere nigba to fẹ ya ọkọ kan silẹ loju popo. Ọkọ naa gbina, awọn mejeeji si gba ibẹ ku.
Iṣẹlẹ iku Jota ninu ijamba ọkọ naa waye lẹyin ọsẹ meji to ṣe igbeyawo pẹlu ololufẹ rẹ, Rute Cardoso ni ọjọ kejilelogun oṣu kẹfa ọdun 2025.
Atẹjade ti ajọ ere bọọlu lorilẹede Portugal fi sita
Aarẹ ajọ ere bọọlu lorilẹede Portugal, Pedro Proenca salaye ninu atẹjade kan ti ajọ naa fi sita pe "iporuru ọlan ti ko ṣee fẹnusọ ni iku Diogo Jota ati aburo rẹ, Andre Silva ni owurọ yii lorilẹede Spain jẹ fun ajọ bọlu lorilẹede Portugal ati gbogbo awọn ololufẹ ere bọọlu lorilẹede naa."
O din diẹ ni ifẹsẹwọnsẹ aadọta ti Jota ti gba fun Portugal ki o to jade laye.
Ọfọ nla lo ṣẹ wa – Liverpool
Ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool pẹlu ti ṣe idaro Diogo Jota ninu atẹjade kan ti wọn fi sita ninu eyi ti ọn ti ṣe apejuwe iku agbabọọlu naa gẹgẹ bi ọfọ nla fun awọn, awọn ololfẹ Liverpool, ẹbi ati ọrẹ rẹ.
Ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool ni awọn yoo ṣi danu duro naa lati le bu ọwọ fun awọn ẹbi rẹ lasiko ọfọ nla to ṣẹ wọn yii.
Ronaldo pẹlu sọrọ
Roanldo, eekan agbabọọlu lagbaye to tun jẹ Balogun fun ikọ agbaọọlu orilẹede Portugal ṣalaye ninu iroyin kan to fi si ori ayelujara pe: "eyi ko ye mi rara. Sebi laipẹ yii ni gbogbo wa pejọ si ikọ agbabọọlu orilẹede wa, ti o si tun jẹ wi pe o ṣẹṣẹ ṣe igbeyawo.Ronaldo wa ran'sẹ ibanikẹdun rẹ si awọn ẹbi Jota, iyawo rẹ atawọn ọmọ rẹ to fi silẹ'
"Mo mọ pe o ko ni fi wọn silẹ.
Sunre, Diogo ati Andre. A o ṣafẹri yin."