You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
NLC yóò bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì ní Aug. 2, àwọn nǹkan tó yẹ kó o mọ̀ nípa rẹ̀ nìyí
Ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ Nàìjíríà, NLC ti kéde pé àwọn máa bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì oníkìlọ̀ ọlọ́jọ́ méje bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́rú, ọjọ́ Kejì oṣù Kẹjọ, ọdún 2023.
Bákan náà ni wọ́n ní ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn yóò tún máa wáyé káàkiri Nàìjíríà ní ọjọ́ yìí kan náà.
Ìgbésẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí NLC ṣe sọ kò ṣẹ̀yìn bí ọ̀wọ́n gógó ṣe ti bá gbogbo nǹkan lọ́jà àti ìṣòro tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń kojú látàrí àwọn ìgbésẹ̀ tí ìjọba tó wà lóde ń gbé.
Ìgbìmọ̀ aláṣẹ ẹgbẹ́ NLC nínú àtẹ̀jáde kan tí wọ́n fi léde lẹ́yìn ìpàdé tí wọ́n ṣe ní ọjọ́ Kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù Keje ni wọ́n ti fi ìkéde yìí síta.
Wọ́n ní àwọn fẹ́ ṣe ìwọ́de yìí láti fi han ìjọba lórí bí inú ṣe ń bí àwọn tó lórí àwọn ìgbésẹ̀ tí wọ́n ń gbé èyí tó ń kó ìpalára bá àwọn ará ìlú láti ìgbà tí ìjọba tuntun tó wà lóde ti gba àkóso Nàìjíríà.
Káàkiri gbogbo ìpínlẹ̀ tó wà ní Nàìjíríà ni ìwọ́de náà ti máa wáyé àyàfi tí ìjọba bá ṣe gbogbo nǹkan tí àwọn ń bèèrè fún kí ọjọ́ náà tó pé.
Kí ló dé tí NLC fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì?
Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní àwọn fẹ́ gùnlé ìyanṣẹ́lódì nítorí àwọn ètò tí ìjọba tuntun lábẹ́ ìdarí Ààrẹ Tinubu gbé kalẹ̀ ti sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ òṣìṣẹ́ sínú ìṣẹ́ àti òṣì.
Wọ́n ní yíyọ ìrànwọ́ orí epo èyí tó sọ owó epo bẹntiróòlù di ₦500 láti ₦185 ti ṣokùnfà ìnira tó pọ̀ fún àwọn ọmọ Nàìjíríà àti pé bí owó epo náà ṣe tún lékún di ₦617 ti sọ àwọn òṣìṣẹ́ sínú òṣì pátápátá.
Ó ní àwọn ìgbésẹ̀ yìí ti fi hàn pé ìjọba kò nání ará ìlú rárá àti pé gbogbo igbe tí ará ìlú ń pa k]o k]an wọ́n rárá.
Wọ́n ní láti nbí oṣù méjì tí owó epo ti lọ sókè ìjọba kọ̀ láti wá ọ̀nà tí ara máa fi dẹ àwọn ará ìlú èyí tí ọrọ̀ ajé tó le koko yìí ń fà fún wọn.
Bákan náà ni wọ́n ní ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ló ń bínú tí wọ́n sì ń ké sí NLC láti ṣaájú ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn láti fi ẹ̀dùn ọkàn wọn han ìjọba.
Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ṣàlàyé pé ìjọba kò pe ìgbìmọ̀ tí wọ́n gbé kalẹ̀ láti jíròrò lórí ọ̀nà tí wọ́n fẹ́ gbà fi mu ìtura bá ará ìlú fún ìpàdé láti ọjọ́ yìí, wọ́n ní ìjọba kàn ń bá ti wọn lọ ni.
“Láti ìgbà tí Ààrẹ Tinubu ti kéde pé kò sí “subsidy” mọ́ ni ara ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ni ará ìlú, tí àwọn ènìyàn kò sì ní àláfíà mọ́ nítorí òṣì kàn ń pọ̀ sì fún àwọn ènìyàn ni.
“Àlékún ti dé bá owó gbogbo ọjà ní Nàìjíríà, bẹ́ẹ̀ náà ni owó àwọn ilé ẹ̀kọ́ tún ti gbówó lórí tó fi mọ́ àwọn ilé ẹ̀kọ́ tó jẹ́ ti ìjọba.”
Kí ní NLC ń bèèrè fún?
Ìjọba àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ti ń ṣe ìpàdé fún bíi ọjọ́ mélòó kan lórí ọ̀rọ̀ yìí àmọ́ ìjọba àpapọ̀ ní àwọn tún fẹ́ gbé ìgbìmọ̀ kan dìde láti jíròrò lórí ọ̀rọ̀ náà dáadáa àti láti wá ọ̀nà tí wọ́n fi máa paná rẹ̀ ní kíákíá.
Àmọ́ àtẹ̀jáde tí NLC fi síta ní láti ìgbà tí àwọn ti ṣe ìpàdé kẹ́yìn tí ìjọba sì ti ṣèlérí láti gbé ìgbìmọ̀ náà kalẹ̀, àwọn kò gbọ́ nǹkankan mọ́ lórí ọ̀rọ̀ náà.
Ohun tí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ń bèèrè lọ́wọ́ ìjọba ni:
- Láti dá owó epo bẹntirọòlù padà sí iye tó wà tẹ́lẹ̀ kí àlékún tó báa.
- Láti mú àyípadà bá owó àwọn ilé ẹ̀kọ́ tó ti gbówó lórí gege.
- Láti ṣe àgbédìde ìgbìmọ̀ tí wọ́n fẹnukò lé lórí tẹ́lẹ̀ ní wàràńsesà láti jíròrò lórí àwọn ọ̀nà tí ìdẹ̀kùn fi máa bá ará ìlú.
- Fún ìjọba ní ọjọ́ méje láti fi ṣe àmúṣẹ gbogbo àwọn ìbéèrè yìí kí ìyanṣẹ́lódì ńlá tó bẹ̀rẹ̀.
Kí ló ti ṣẹlẹ̀ nígbà tí NLC dúńkokò láti gùnlé ìyanṣẹ́lódì tẹ́lẹ̀?
Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ máa dúnkokò láti gùnlé ìyanṣẹ́lódì lẹ́yìn tí Bola Tinubu gba ipò Ààrẹ Nàìjíríà.
Nínú oṣù Kẹfa ọdún 2023 ni wọ́n ti kọ́kọ́ kéde pé ìyanṣẹ́lódì máa wáyélẹ́yìn tí ìjọba yọ ìrànwọ́ orí epo.
Àmọ́ NLC yí ìpinnu padà lẹ́yìn tí ààrẹ ẹgbẹ́ NLC, Joe Ajaero ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn aṣojú ìjọba ni wọ́n fagilé ìyanṣẹ́lódì náà kí ìjíròrò le wáyé láàárín ìjọba àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́.
Láti ìgbà náà ni ìrètí ti wà pé ìjóba àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC àti TUC yóò jíròrò lórí ọ̀nà tí ìjọba fi máa mú ìdẹ̀kùn bá ará ìlú.
Ṣaájú ìgbà náà ni ilé ẹjọ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ òṣìṣẹ́ ti kọ́kọ́ gbé ìdájọ́ kalẹ̀ pé ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ kò gbọdọ̀ gùnlé ìyanṣẹ́lódì nígbà tí ìjọba àpapọ̀ pe ẹjọ́ tako àwọn òṣìṣẹ́ lórí èròńgbà láti gùnlé ìyanṣẹ́lódì ọ̀hún.