Wo ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tó wa ara rẹ̀ lọ sílé olówó rẹ̀ lẹ́yìn tó rà á

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Bẹẹni Tesla wa ara rẹ lọ si ile eeyan kan to ra a fun igba akọkọ.

Eyi lo wa ninu fọnran kan ti ileeṣẹ naa fi lede lati ṣafihan bi ọkọ ayọkẹlẹ Model Y ṣe n wa ara rẹ lati ileeṣẹ naa to wa ni Austin niluu Texas lọ sile olowo rẹ, irinajo wakati kan ati abọ laisi dẹrẹba tabi ẹnikẹni ninu rẹ.

Tesla ko ti ṣalaye imọ ẹrọ to jẹ ki eyi jẹ ṣiṣe fun ọkọ ayọkẹlẹ naa.

Ẹwẹ, ọkọ Tesla Model Y ni abala ti eeyan ti le paṣẹ fun un, ti ko si ni nilo iranlọwọ eeyan lati wa a rara, eeyan naa si le gba a lọwọ rẹ nigbakugba to ba wu.

Ṣugbọn fọnran ti ileeṣẹ Tesla fi lede ṣafihan bi ọkọ yii ṣe n wa ara rẹ, lai nilo iranlọwọ ẹnikẹni, lọ sile olowo rẹ.

Ọga agba fun Tesla, Elon Musk ni ko si ẹnikẹni to tọwọ bọ iwe adehun kankan lati ri pe ọkọ ayọkẹlẹ ọhun de si ile olowo rẹ.

Ni ipari fọnran naa, ọkọ ayọkẹlẹ ọhun ni a ri to duro si ẹnu ọna abawọle, ti olowo rẹ ati awọn eeyan si wa ni ita, ti wọn n duro de.

Ẹwẹ, ọpọ eeyan lori ayelujara ti bu ẹnu atẹ lu bi wọn ṣe paaki ọkọ naa kalẹ, ti wọn si jẹ ko di mimọ pe ko yẹ ki wọn gbe ọkọ naa sibẹ.

Lẹyin ti ọkọ naa duro, Elon Musk dupẹ lọwọ awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe, to si gbe e si oju opo ayelujara X.

"Ninu oye temi, igba akọkọ ree ti ọkọ ayọkẹlẹ yoo wa ara rẹ loju ọna marosẹ lai si iranlọwọ eeyan kankan to n tọ sọna.

Ẹwẹ, aṣiṣe wa ninu ọrọ rẹ nitori ọkọ ayọkẹlẹ Waymo, to jẹ ọkan ninu awọn ọkọ ti ileeṣẹ Google ṣe, ti wa awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa niluu Phoenix, San Francisco ati Los Angeles lorilẹede Amẹrika laisi dẹrẹba ninu rẹ.

Ọpọ igba ni Elon Musk ti ṣe ileri pe lọjọ kan Tesla yoo ma wa ara rẹ .

Ni ọdun 2019, o kede sita pe titi ọdun 2020, Tesla yoo ma wa ara rẹ.

Ẹwẹ, ileri yii o wa si imuṣẹ, to si fi Tesla si aye rẹ pe ko ba ẹgbẹ awọn ọkọ to n wa ara wọn pe.

Iṣẹlẹ yii ti fi ẹrin si ẹnu Elon Musk ati awọn ololufẹ Tesla.