Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ṣàwárí ihò ńlá tó ń gbé ìràwọ̀ mì lójú ọ̀run lójoojúmọ́

Titi di asiko yii, awọn onimọ sayẹnsi ko tii le ṣalaye iru ọrun apaadi wo ree.

Ko si sohun meji to fa a, to kọja wi pe ko tii sẹni to lọ sibẹ, to si pada wa ṣalaye ohun ti oju rẹ ri nibẹ.

Ohun kan ṣoṣo ti a mọ tabi ni lerongba nipa ibẹ ni pe kii ṣe ibi to dara lati ṣabẹwo si, ibi ẹru ti ko dara fun eeyan tabi iṣẹkan lati gbe nibẹ.

Ju gbogbo rẹ lọ, a le sọ nipa iṣẹ iwadii ijinlẹ ti agbaye wi pe, awọn onimọ sayẹnsi ti ṣawari ọna ti wọn le fi ṣalaye bi ọrun apaadi ṣe ri.

Iwe iroyin kan to jade ninu iwe atẹjade ti wọn pe ni Nature Astronomy, ṣalaye ohun nla kan to ni iho to yi aye ka, ti eefin nla si n jade nibẹ.

Awọn onimọ sayẹnsi pe sọ iho dudu nla yii ni orukọ ‘J0529-4351’, gẹgẹ bi ohun to mọlẹ julọ to yi ile aye ati agbaye ka.

Ẹnu ọna buruku iho nla naa

Awọn onimọ iwadii ijinlẹ ti wọn n pe ni ‘Astronomers’ tilẹ ti ṣawari ẹgbẹẹgbẹrun iho nla dudu yii tẹlẹ, ti wọn si n pọ si kaakiri oju ofurufu. Aarin gbungbun irawọ to korajọ ni wọn si ti saba maa n ri wọn.

Wọn tilẹ tun ṣakiyesi pe awọn iho nla wọnyi tobi ju oorun to le ni biliọnu lọ, iyẹn bi biliọnu oorun ba korajọ soju kan ṣoṣo.

Niṣe ni awọn iho yii maa n sare dide, nibi ti wọn ti n gbe awọn irawọ ati eefin to sunmọ wọn min, niṣe ni wọn maa n jabọ sinu ẹ bi igba ti wọn ko ba ju nnkan sinu iho.

Iwọnba ninu awọn ohun to ba jabọ sinu iho yii lo le jade sita pada. Ati pe apapọ gbogbo nnkan to n jabo sinu iho yii lo maa n mu ina jade, to maa n jẹ ki iho naa gbona jọjọ.

Bi awọn ohun to wa ninu iho yii ba ṣe tobi si, ni yoo sọ bi yoo ṣe gbona si, to si jẹ pe ina ti yoo maa jade ninu iho yii yoo pọ debi wi pe yoo tun mọlẹ ju ẹgbẹẹgbẹrun oṣupa ofurufu lọ.

Idi si ree to fi jẹ pe iru awọn iho yii maa n dagba kọja ile aye yii lọ, ọna si wa jinna rere debi pe irin ajo rẹ maa n gba ọpọlọpọ miliọnu ọdun, ti irin ajo ina rẹ ko sii ti de ibudo.

Ẹnu ọna iho buruku to tobi julọ lofurufu

Iho nla dudu to dabi irawọ yii, maa n gba ina to to aadọta biliọnu ara ju oorun ti a a maa n fi oju ri yii lọ.

Nitori pe iru iye ina ti iho nla dudu yii maa n gba sara, awọn onimọ gbagbọ pe ko le mu ina jade bi ko ba gba o kere tan oorun kan ti a maa n ri lojoojumọ mọra.

Bi o ba wa ri bẹẹ, iho to n gbe ẹyọkan min lojumọ yii, a jẹ pe ko ni agbara ati okun ati irora rara. Ṣugbọn sibẹ, ko si ibẹru kankan nipa iho yii.

Idi ree ti wọn fi sọ pe ina to wa ninu iho yii, yoo lo to ọdun ti ko din ni biliọnu meji ko to le de inu aye ti a wa yii, eyi to tunmọ si pe o ti pẹ ti ko ti tobi mọ.

Iru iho nla dudu ti a n sọ nipa rẹ yii, ni wọn sọ pe o ti pẹ to ti pari iṣẹ rẹ.

Iho nla ọrun apaadi to ti pari iṣẹ

Ni bayii, iho nla to tobi yii ti pari iṣẹ, ko si dagba mọ, bẹẹ si ni ko gbe awọn ohun to yiika tabi sunmọ ọn min mọ.

Idi ni pe eefin to n jade tabi gba aarin irawọ kọja naa tun maa n jẹ irawọ funra rẹ, gẹgẹ bi Nazari ṣe ṣafihan rẹ.

Lẹyin ọpọlọpọ biliọnu ọdun, awọn irawọ wọnyi yoo to ara wọn, wọn yoo si farahan lọtọọtọ.

Awọn irawọ yii yoo parapọ lati di ila to gun kan, ati pe iho nla dudu yii, ko ṣiṣẹ bo ṣe maa ṣiṣẹ tẹlẹ mọ

Koda, bi irawọ kan tun jabọ sinu iho yii pada, niṣe ni yoo jade sita pada nigba to ba wu

Eyi si maa n ṣẹlẹ lagbaye nigba ti awọn irawọ ba n rin lọ si awọn ibi to ṣoro lati de lagbaye.

Ju gbogbo rẹ lọ, bi ọpọ nnkan ba wa lofurufu, nibi ti awọn irawọ ti lọ parapọ, niṣe ni wọn maa gbina loju ẹsẹ, ti wọn a si pin yẹlẹyẹ sinu agba ‘space’ ti irawọ to tobi julọ, eyi to wa ni ipo karun ninu awọn irawọ to yi oorun ka, eyi t a mọ si Jupiter.

Iru nnkan bayii ti ṣẹlẹ gbẹyin ni kete ti a da ile aye, ati pe iho nla dudu yii ti a fi we ọrun apaadi, maa n jẹ anfaani kikorajọ.

Obiripo ọrun apaadi - Ibi ti awọn onimọ ijinlẹ ko to bẹẹ lati de

Agbegbe yii ni ita to dabi obiripo to jẹ ẹnu ọna. Ibi to gbona jọjọ ni, ati pe ohunkohun ti yoo ba gba lati debẹ, ko nii pada wa.

Ita lo maa n wa pẹlu ọpọlọpọ kurukuru, to si jẹ pe awọn kurukuru yii maa n gbọnran nigba to ba ti n sunmọ iho yii

Kurukuru yii lo maa n sare rin ni iwọn ẹgbẹrun lọna ọgọrun kilomita laarin iṣẹju-aaya (100,000klm/sec).

Eyi tunmọ si pe laarin iṣẹju aaya kan, kurukuru yii le kari gbogbo ibi ti ile aye le de laarin wakati kan.

Ki lo de ti wọn ko tii ri iho ọrun apaadi yii?

Bi iho ba jẹ eyi to mọlẹ julọ ni gbogbo agbaye, ki lo wa de ti wọn ko tii ṣawari rẹ titi di asiko yii?

Idi ni pe ọpọ iru awọn iho yii ti wọn tobi, ti wọn si mọlẹ lo wa kaakiri agbaye.

Pupọ awọn ohun to wa ninu ‘space’ lo jẹ pe ẹrọ ti wọn fi n ṣayẹwo imọ ijinlẹ ti a mọ si ‘telescopes’ ni wọn fi n wo wọn, idi ree to fi jẹ pe awọn oniṣẹ iwadii ni lati lo awọn irinṣẹ miran to le ri ohun ti wọn n fẹ lati fi mọ iru nnkan ti wọn ba ri.

Awọn irinṣẹ ti wọn n lo yii, le ri iho nla dudu, ṣugbọn kii ṣe pe ki wọn ri iru iho nla dudu ti a n sọrọ rẹ ṣaaju, eyi ti wọn pe ni ọrun apaadi.

Lọdun 2015, awọn ẹgbẹ kan lati Chana ṣawari iho kan to n sare dagba, ṣugbọn wọn ko ri daadaa nitori iru ọna ti wọn gba lati tọpinpoin rẹ.

Erongba wọn ni lati wa irawọ tabi ohun miran to tun jọju, to si mọlẹ, to si tun n sare dagba laarin awọn iho nla dudu.

Awa, ni ti wa, lo awọn ọna to jọ eyi ti wọn ti lo ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin nibi ti a ti ri ohun tuntun miran.

Iṣẹ iwadii wa yii gba wa ni ajọṣepọ ọdun mẹwaa laarin awọn onimọ sayẹnsi ti Australia ati Yuroopu ti wọn ni irinṣẹ agbefo lọ sinu ofurufu (space).

  • Christian Wolff jẹ Ọjọgbọn imọ ijinilẹ Astronomy ni fasiti Austrilia, iyẹn Australian National University.