Òṣèré sinimá, Tonto Dikeh di olùdíje igbákejì gómìnà ní Rivers

Gbajumọ oṣere sinima lorilẹede Naijiria, Tonto Dikeh ni wọn ti yan bayii gẹgẹ bi igbakeji oludije gomina ipinlẹ Rivers fun idibo apapọ ọdun 2023 labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu ADC.

Alukoro fun ẹgbẹ oṣelu ADC ni ipinlẹ Rivers, Luckyman Egila fi idi iroyin yii mulẹ fun BBC.

Oludije fun ipo gomina lẹgbẹ oṣelu ADC nipinlẹ Rivers, Tonte Ibraye pẹlu kede eyi loju opo Facebook rẹ lowurọ ọjọ Ẹti.

“Lẹyin oniruuru ifikuluku pẹawọn adari ẹgbẹ oṣelu wa, ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC ni ipinlẹ Rivers ati ni ẹka apapọ, mo layọ lati kede Ambasadọ Tonto Dikeh gẹgẹ bi igbakeji mi ni idije fun ipo gomina lọdun 2023 ni ipinlẹ Rivers.

“Inu wa dun lati kii kaabọ si |RiversRescueMission2023 bi a ṣe n sa ipa lati lati mu idagbasoke ba igbe aye awọn eeyan ipinlẹ Rivers.”

Tonto Dikeh funra rẹ naa ti tẹwọ gba ipe yii lati di igbakeji oludije ẹgbẹ oṣelu ADC, o si ti gbe e saye loju opo Facebook rẹ.

“Mo dupẹ lọwọ ọgbẹni Tonte Ibraye, oludije fun ipo gomina lẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC ni ipinlẹ Rivers fun fifa orukọ mi kalẹ gẹgẹbi igbakeji rẹ.

Tonto Dikeh ni oun ṣetan lati ṣiṣẹ takuntakun bi o ti tọ ati bi o ti yẹ fun idapada igbe aye irọrun fun awọn eeyan ipinlẹ Rivers.

Tonto Dikeh ati Tonte Ibraye yoo maa darapọ mọ awọn oludije ipo goimina fun aga ile gomina ipinlẹ Rivers bii alaga ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ni ipinlẹ naa, Comrade Beartrice Itubo to n dije labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu Labour Party ati Dumo Lulu-Briggs to n dije labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu Accord Party lọdun 2023.