You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Iléeṣẹ́ aṣojú America sọ ìdí tó fi ń fagilé físà àwọn ọmọ Naijiria
Lẹyin awuyewuye kan to gbode pe, ileeṣẹ ilẹ America to n ri si irinajo ni Naijiria n fagile fisa awọn ọmọ Naijiria ti wọn ti fun ni anfaani lati rin irinajo lọ si America tẹlẹ, ileeṣẹ naa ti ṣalaye bi ọrọ ṣe ri gan-an.
Gẹgẹ bi iwe iroyin Guardian ṣe ro o, atẹjiṣẹ ni ọfiisi to n ri si irinajo lọ si America lati Naijiria fi n ranṣẹ si awọn ọmọ orilẹede yii to ni fisa America lọwọ.
Ninu atẹjiṣẹ naa ni wọn ni wọn n kọ ọ si, pe ki wọn mu iwe irinna wọn ti a mọ si Passport wa si Ẹmbasi ilẹ America, wọn yoo si ṣe bẹẹ fagile fisa wọn lai si alaye kankan.
Awọn ti ọrọ naa kan ni awọn akẹkọọ to ni fisa igbẹkọ lọwọ, awọn oniṣowo ati awọn akọṣẹmọṣẹ.
Ṣaaju ni ijọba ilẹ America ti fi orukọ awọn orilẹede kan sita pe wọn ko le wọ America mọ, wọn si fi ofin de awọn orilẹede kan pẹlu, ṣugbọn ko kan Naijiria.
Eyi lo ṣe jẹ iyalẹnu fun awọn ti wọn ni Ẹmbasi America fagile fisa wọn bayii, to si jẹ pe alaye kan ṣoṣo ti wọn ṣe fun wọn ni pe awọn yoo maa kan si wọn.
Wọn ko ṣalaye bi kikan si wọn naa yoo ṣe ri ati ibi ti yoo ja si.
Kí ni ileeṣẹ aṣoju America sọ?
Nigba to n fesi si iṣẹlẹ yii lọjọ Iṣẹgun, Agbẹnusọ kan ni Embasi America, ṣalaye fun BBC pe, "ọfiisi yii lagbara lati fagile fisa, ṣugbọn a n lo gbogbo akọsilẹ ti a n ko jọ lati ṣe eyi ni ọna ti ko ṣẹlẹ ri, ka le da aabo bo ẹnu ibode America, ka si ri i daju pe gbogbo agbegbe ni aabo wa ni America."
Gẹgẹ bo ṣe wi, abala 221(i) ofin irinna ati jijẹ-ọmọ-onilu; Immigration and Nationality Act (INA), fi aaye silẹ fun Akọwe ati awọn oṣiṣẹ aṣọju ijọba ni ẹmbasi lati fagile fisa nigbakigba, aṣẹ yii naa la si fi n ṣiṣẹ nigba to ba foju han pe awọn kan ko kunju oṣuwọn to labẹ ofin INA."
"Ijọba Trump n da aabo bo orilẹede wa ati awọn eeyan ibẹ ni, nipa titẹle ilana aabo to ga ju pẹlu bi awọn eeyan ṣe n gba fisa America.
" Bi a ko ṣe jẹ kawọn to le ṣakoba fun aabo wa wọle si US n jẹ ki alaafia wa fun wa si i, koko pataki lo jẹ fun wa lati ri i pe aburu ko ṣe awọn ọmọ America nilee wọn."
"O fi kun un pe labẹ iṣakoso Trump, ẹka to n ri si fisa l'America n fagile fisa nigba ti ajeji kan ba ti kọja iye asiko to yẹ ko lọ niluu naa.
Koda, ko baa jẹ akẹkọọ to ti ẹyin odi wa ni, wọn ni awọn yoo fagile fisa rẹ nigba to ba ti léjọ́, tabi to n lọwọ si iwa ọdaran.
America fi kun un pe oun yoo fagile fisa awọn to ba n ṣatilẹyin fun awọn agbesunmọmi, ti wọn n ko nnkan ija ogun fun wọn tabi ti wọn n tapa si ofin America.
Ṣaaju ni America ti kede, pe oun yoo maa yẹ oju opo ayelujara awọn to ba fẹẹ gba fisa awọn wo, wọn ni eyi naa yoo wa lara ohun tawọn yoo wo mọ ẹni to fẹẹ gba fisa America lara kawọn too pinnu boya yoo ri I gba tabi bẹẹ kọ.
BBC beere lọwọ awọn eeyan kan ti wọn ni fisa America lọwọ tipẹ, pe ṣe wọn ti fagile tiwọ naa, wọn ni wọn ko fagile e.
Ẹ o ranti pe latigba ti Aarẹ Donald Trump ti bẹrẹ saa keji rẹ lo ti mulele nipa ofin irinna ati bi wiwọle si America yoo ṣe dinku jọjọ.
Loṣu to kọja yii ni US kede pe oun yoo ṣe agbeyẹwo fisa awọn ọmọ Naijiria ati awọn ilu mi-in lagbaaye, kawọn le tete gbe igbesẹ to yẹ bi wọn ba rufin.
Oṣu Kẹjọ yii kan naa ni wọn ge asiko to n wa lorii fisa awọn ọmọ Africa ku si oṣu mẹta pere.
America ni oun ṣe eyi lati fi gbẹsan bi Naijiria naa ṣe din akoko to wa lorii fisa wọn ku fun awọn ọmọ America.
Ṣugbọn ijọba Naijiria fesi pe ọdun marun-un ṣi n pe perepere lorii fisa tawọn n fun awọn ọmọ ilẹ America lati wọle si Naijiria nigba to ba wu wọn.