Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ẹ dákun ẹ dábọ̀, ẹ fiyè dénú

Ìjọba Nàìjíríà ló rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Amẹ́ríkà lórí àtúnṣe gbígba físà tí wọ́n gbé jáde lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun

Iléeṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè ní Nàìjíríà sọ pé

Ìgbésẹ̀ náà lòdì sí ìbáṣepọ̀ tó wà láàárín orílẹ̀ èdè méjéèjì

xxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxx

Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà, Supreme Court ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé

Gómìnà ìpínlẹ̀ Edo, Monday Okpebholo ni ojúlówó gómìnà tí wọ́n dìyàn díbò yàn

Adájọ́ Mohammed Lawal Garba nígbà tó ń gbé ìdájọ́ kalẹ̀ sọ pé

Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP àti òṣèlú kò fìdí ẹ̀sùn wọn múlẹ̀ tó lórí ẹjọ́ tí wọ́n pè tako Okpebholo àti APC

xxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxx

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun àfọ̀mọ́ ọ̀rọ̀

Lórí ọkùnrin kan, Ogbonna Ogbojionu tó ní wọ́n dájọ́ ikú fóun nítorí òun ra ẹ̀rọ jẹnẹrétọ̀ tí wọ́n jí gbé

Àmọ́ Kọmíṣánnà fétò ìdájọ́ ìpínlẹ̀ Ogun, Oluwasina Ogungbade sọ pé irọ́ ló pa àti pé

Ogbonna wà lára àwọn tó lọ ja ilé epo kan lólè lọ́dún 2000 níbi tí wọ́n ti pa èèyàn kan