You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Awuyewuye lórí àwọn èèyàn tí Tinubu ń yàn sípò
- Author, Mansur Abubakar
- Role, BBC News, Abuja
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Àwọn ọmọ Nàìjíríà kan ti ń kọminú pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí nínú àkọ́ọ́lẹ̀, pẹ̀lú bí ẹ̀yà àti ẹ̀sìn ṣe pọ̀ ní Nàìjíríà, ààrẹ kò máa wo èyí nípasẹ̀ bó ṣe ń fún àwọn èèyàn nípò nínú ìṣèjọba rẹ̀.
Ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó wà ní Nàìjíríà ló ti ń fa ìwà ẹlẹ́yàmẹ̀yà látẹ̀yìn wá.
Lábẹ́ ìwé òfin Nàìjíríà, gbogbo ẹkùn tó wà ní Nàìjíríà ni ó gbọ́dọ̀ ní aṣojú nínú ìgbìmọ̀ aláṣẹ, àmọ́ níṣe àwọn adarí máa ń lo ọgbọ́n inú wọn láti fi pín àwọn ipò tó ṣe kókó míì láti ri pé kò yọ ẹkùn kankan sílẹ̀.
Irúfẹ́ ìkọnimú báyìí lórí báwọn ààrẹ ṣe máa ń fún àwọn èèyàn kò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa wáyé ṣùgbọ́n níṣe ni ọ̀rọ̀ náà pọ̀ si báyìí báwọn èèyàn kan ṣe ń bu ẹnu àtẹ́ lu ààrẹ Bola Tinubu pé ọ̀pọ̀ àwọn tó ń yàn sípò láti ìgbà tó ti wà lórí ipò ààrẹ láti bíi ọdún méjì sẹ́yìn ló jẹ́ láti ìran Yorùbá tó ti wá.
Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ààrẹ ti jiyàn ẹ̀sùn yìí.
Ìbẹ̀rù tó gbọkàn àwọn èèyàn yìí ni pé ẹ̀yà kan ni yóò jẹ gàba láwọn ipò tó ṣe kókó, ohun tí èyí sì túmọ̀ sí ni pé àwọn èèyàn máa ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ipò kọ̀ọ̀kan nígbà tí ìjọba bá kéde yíyan èèyàn sípò.
Ó lé ní ẹ̀yà 250 tó wà ní Nàìjíríà tó sì jẹ́ pé Hausa-Fulani láti àríwá, Igbo láti gúúsù ìlà oòrùn àti Yorùbá láti gúúsù ìwọ̀ oòrùn ló pọ̀ jù.
Àwọn lámèyítọ́ sọ pé Tinubu, Mùsùlùmí láti ẹkùn gúúsù, ṣàfihàn àpẹẹrẹ láti má náání lílo ẹ̀yà tàbí ẹ̀sìn láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ nígbà tó ti yan Mùsùlùmí míì láti ẹkùn àríwá láti jẹ́ igbákejì rẹ̀ níbi ètò ìdìbò ọdún 2023.
Láti ìgbà tí Nàìjíríà ti padà sí ìjọba alágbádá lọ́dún 1999, ọ̀pọ̀ àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú tó ṣe kókó máa ń yan ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí àti ọmọlẹ́yìn Kristi gẹ́gẹ́ bí olùdíje bí ó ṣe jẹ́ pé àwọn ẹlẹ́sìn méjéèjì yìí ló pọ̀ jù ní Nàìjíríà.
Àmọ́ àwọn ìyànsípò Tinubu láti ìgbà tó ti gbapò ààrẹ Nàìjíríà nínú oṣù Karùn-ún, ọdún 2023 ló ń fa awuyewuye báyìí.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ipò ni olórí orílẹ̀ èdè máa ń yàn, àwọn ipò mẹ́jọ kan wà tí ó ṣe kókó sí ìṣèjọba gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ nípa ètò òṣèlá àti agbẹjọ́rò Lawal Lawal ṣe sọ.
Àwọn ipò náà olórí:
- Ilé ìfowópamọ́ àgbà
- Iléeṣẹ́ NNPC
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
- Iléeṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́
- Iléeṣẹ́ ológun
- Iléeṣẹ́ ẹ̀ṣọ́ ẹnubodè
- Àjọ tó ń gbógunti ìwà àjẹbánu
- Iléeṣẹ́ tó ń pawó wọlé
Kò sí ohun tó sọ pé ipò kan ju òmíràn lọ lábẹ́ òfin àmọ́ àwọn ipò yìí ló ń ṣe àkóso àti ìdarí ètò ìsúná àti ààbò Nàìjíríà.
Gbogbo ààrẹ ló máa ń bá àwọn tí ẹni tó gbésẹ̀ bá yàn sáwọn ipò yìí, tí àwọn náà sì ní àṣẹ láti fi ẹlòmíràn rọ́pò wọn.
Títí di oṣù Kẹrin ọdún 2025, gbogbo àwọn tó ń darí àwọn iléeṣẹ́ mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ ló jẹ́ ọmọ Yorùbá.
Ìyànsípò Bayo Ojulari sípò adarí iléeṣẹ́ tó ń rí sí epò bẹntiróòlù ìyẹn Nigerian National Petroleum Company, NNPC, ẹni tó gba ipò náà lọ́wọ́ ará àríwá mú kí awuyewuye lórí yíyan àwọn èèyàn ẹkùn kan sáwọn ipò tó ṣe kókó tún bọ̀ pọ̀ si.
Tí a bá wo báwọn méjì tó ṣèjọba ṣáájú Tinubu ṣe pin àwọn ipò yìí, a wòye pé kò sí irúfẹ́ ìwà kí ẹ̀yà kan jẹ gàba láwọn ipò tó ṣe kókó yìí.
Goodluck Jonathan – tó ṣèjọba láàárín ọdún 2010 sí 2015 – ni ìyànsípò rẹ̀ fẹ́ ẹ̀ kó gbogbo ẹ̀yà tó pọ̀ díẹ̀ bó ṣe yan Fulani méjì, Hausa méjì, Igbo kan, Yorùbá kan, Atyap kan àti Calabar kan.
Muhamma Buhari ní tirẹ̀ – tó ṣèjọba láàárín ọdún 2015 sí 2023 yan Hausa mẹ́ta, Kanuri méjì, Igbo kan, Yoruba kan àti Nupe kan sáwọn ipò mẹ́jọ náà.
Gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ àwọn Nàìjíríà, iran kan náà ni Hausa, Kanuri àti Nupe, pé àríwá kan náà ni gbogbo wọn ti wá, tí wọ́n sì fẹ̀sùn kan Buhari pé ó ṣe ojúṣàájú.
Àwọn kan ń sọ ọ́ pé ipa Buhari náà ni Tinubu ń tọ̀ àmọ́ bó ṣe jẹ́ pé Yorùbá ni gbogbo awọn tó wà ní ipò mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ náà kìí ṣe ohun tó ti ṣẹlẹ̀ rí.
"Ọ̀jọ̀gbọ́n Tijjani Naniya, onímọ̀ nípa ìtàn sọ fún BBC pé òun kò lè ṣe ìràntí ìgbà tí ẹ̀yà kan ti gba gbogbo ipò tó ṣe kókó báyìí láti ìgbà tí Nàìjíríà ti ń dìbò yan ààrẹ.
Ọ̀jọ̀gbọ́n náà sọ pé ọ̀rọ̀ nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn kọ́ ni èyí bíkòṣe pé ó le ní ipa lórí ìṣọ̀kan àti ọjọ́ iwájú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
"Fún èmi, ohun tó ń bàmí lẹ́rù nip é tí ààrẹ míì náà bá tún tọpasẹ̀ yìí ńkọ́, tó kó gbogbo ipò tó ṣe kókó fáwọn èèyàn tó wà lái ẹkùn rẹ̀, kò ní jẹ́ káwọn yòóku rí ara wọn bíi ọ̀kan, tó sì tún mú àdínkù bá ìgbàgbọ́ nínú ìṣèjọba àwaarawa," ó sọ.
Àwọn tó wà ní àkóso NNPC, ọlọ́pàá, iléeṣẹ́ ẹnubodè àti EFCC ni wọ́n gba ipò lọ́wọ́ àwọn ará àríwá.
Ìyọnípò Abdulrasheed Bawa, tó jẹ́ ìran Hausa, gẹ́gẹ́ adarí EFCC lọ́dún 2023, lẹ́yìn ọdún méjì tó dé ipò náà jẹ́ èyí tó mú awuyewuye dání.
Lẹ́yìn tí wọ́n yọ ọ́ nípò ni wọ́n fi òfin gbe, fẹ̀sùn kàn án fún àṣìlò agbára, tó sì wà ní àhámọ́ fún ọgọ́rùn-ùn ọjọ́ kí wọ́n tó da àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án nù.
Ola Olukoyede ni wọ́n fi rọ́pò rẹ̀, ẹni tó jẹ́ Yorùbá.
Àwọn kan láti àríwá gbàgbọ́ pé wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ tí Bawa dànù láti fi ààyè gba Olukoyede.
Olùyànnànà ọ̀rọ̀ kan, Isah Habibu sọ fún BBC pé ààrẹ nílò láti mọ̀ pé ìran kan lára Nàìjíríà ni Yorùbá àti pé ààrẹ láti pín ipò káàkiri àwọn ẹ̀yà àti ìran tó kù.
Láì sọ ipò kan ní pàtó, agbẹnusọ Tinubu kan sọ pé ààrẹ ń ṣe ohun tó tọ́ nípa bí ó ṣe ń pín ipò tí a bá wo gbogbo àwọn tó ti yàn sípò lápapọ̀.
Sunday Dare, agbẹnusọ Tinubu nínú àtẹ̀jáde kan tó fi sórí X rẹ̀ lọ́jọ́ Kẹsàn-án, oṣù Kẹrin sọ pé àwọn ará àríwá 71 ni Tinubu ti yàn sípò, tó sì yan èèyàn 63 láti gúusù àmọ́ tó padè pa àtẹ̀jáde náà rẹ́ nígbà táwọn èèyàn yọ àwọn àṣìṣe kan jáde nínú àtẹ̀jáde ọ̀hún.
Ó ṣèlérí láti gbé àtẹ̀jáde míì jáde àmọ́ tí kò ì tíì ṣe bẹ́ẹ̀ títí di àsìkò yìí.
Yàtọ̀ sí àwọn ará ìta, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Tinubu náà ń kọminú lórí àwọn ìyànsípò tó ń ṣe.
Sẹ́nétọ̀ Ali Ndume láti ẹkùn àríwá, tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC bíi Tinubu sọ lórí ètò kan pé ohun ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún òun bí Tinubu ṣe ń pín ipò.
Ó ní ó yàtọ̀ sí ìlèrí Tinubu tó ṣàdéhùn pé gbogbo ẹ̀yà ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni òun máa fà lọ́wọ́ lásìkò ìṣèjọba òun.
Abẹ́ṣinkáwọ́ Tinubu míì, Daniel Bwala ni òun kò gbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ pé ipò kan ju òmíràn lọ.
"Ohun tí mo mọ̀ ni pé, pẹ̀lú ìlànà ìwé òfin, ààrẹ ti ṣe àwọn ohun tó yẹ lórí ìyànsípò – kò sí ibi tó wà níní ìwé òfin pé àwọn ipò kan ló wà níwájú," ó sọ fún BBC.
"Gbogbo ipò tí wọ́n bá ti yan èèyàn sí ló ṣe kókó, tó sì ṣe pàtàkì."
Ọ́fíìsì akọ̀wé ìjọba Nàìjíríà, tó máa ń ṣàkóso àwọn ètò ìjọba, nínú àtẹ̀áde tí wọ́n fi léde lọ́jọ́ Kejìlá, oṣù Kẹrin sọ pé Tinubu kò ṣe ojúṣàájú lórí bó ṣe ń pín ipò.
"Ìṣèjọba yìí ń ṣe àrídájú rẹ̀ pé gbogbo ẹkùn tó wà ní orílẹ̀ èdè yìí ni wọ́n ní aṣojú láwọn iléeṣẹ́ àti lájọlájọ ìjọba," àtẹ̀jáde náà sọ.
Onímọ̀ nípa òṣèlú, Lawal sọ pé ààrẹ gbọ́dọ̀ yan èèyàn tó kájú òṣùwọ̀n láì fi ẹ̀yà ṣe, tó sì ní òun gbàgbọ́ pé nǹkan tí Tinubu ń ṣe nìyí.
"Àsìkò ti tó fáwọn ọmọ Nàìjíríà máa rí kọjá ẹ̀yà nìkan," ó sọ.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Naniya bóyá ìgbà kan ń bọ̀ táwọn ọmọ Nàìjíríà kò ní máa wo ẹ̀yà àwọn tó wà nípò adarí mọ́ ṣùgbọ́n a ò tíì débẹ̀ báyìí.
Ó ní òun gbàgbọ́ pé èyí le rí bẹ́ẹ̀ nígbà tí Nàìjíríà bá ní ààrẹ mẹ́rin tẹ̀lé ara wọn tí wọ́n ń fún gbogbo ẹ̀ka ní àkànṣe iṣẹ́ àti ìyànsípò tó yẹ.
"Mo lérò pé ó ṣeéṣe àmọ́ a nílò àwọn adarí tó tọ́."