You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wọ́n fẹ̀sùn ìgbésùnmọ̀mí kan ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn nítorí ó ṣèwọ́dé tako ìjọba
Gbajugbaja ajafẹtọọ ọmọniyan lorilẹede Kenya, Boniface Mwangi, ni wọn ti fẹsun kan bayii pe agbesunmọmi ni.
Yatọ si eyi, wọn tun fi ẹsun nini nnkan ija oloro lọwọ lọna aitọ kan ajafẹtọọ ọmọniyan naa.
Eyi n waye lẹyin iwọde tako ijọba orilẹede Kenya to waye loṣu to kọja, nibi ti o kere tan, eeyan mọkandinlogun ti dagbere faye.
Bo tilẹ jẹ pe Mwangi tako awọn ẹsun naa ti wọn si ti fi aaye beeli silẹ fun un lẹyin ti wọn kọkọ fi ọwọ ofin gbe e.
Lọjọ Aiku, awọn ọtẹlẹmuyẹ kede pe awọn ko awọn foonu, kọmputa alagbeletan ati eyi to da bii iwe, ẹrọ tajutaju ati eroja kan to le bu gbamu ni ọfiisi rẹ to wa ni agbegbe Lukenya, Nairobi Kenya.
Bi wọn ṣe mu Mwangi ti mu ọpọ ajafẹtọọ ọmọniyan koro oju si igbesẹ ijọba orilẹede naa.
Ohun ti wọn n sọ ni pe ijọba Kenya n pa ohun mọ agogo awọn araalu lẹnu, paapaa awọn to ba n tako ijọba.
James Orengo, oloṣelu to gbajumọ to si tun jẹ gomina ni ẹkun-un Siaya, sọ nipa mimu ti wọn mu Mwangi pe, "Iyalẹnu lo jẹ pe wọn le fi ẹsun kan Boniface Mwangi ati awọn ọmọ wa to fẹhonu han pe wọn lọwọ ninu igbesunmọmi.
Ṣugbọn minisita fun ọrọ abẹle, Kipchumba Murkomen, juwe iwọde to pa ọpọ eeyan naa bi igbesunmọmi ti wọn ṣe lọna ọtọ.
O ni ọna to lodi sofin ni awọn eeyan naa gba, wọn si fẹẹ fi doju ijọba bolẹ ni.
Minisita naa ṣo pe ọpọ ọkọ ni wọn dana sun, wọn tun kọlu teṣan ọlọpaa, awọn agbofinro si fi ara pa bo ṣe sọ.
O le ni ọgọrun-un eeyan to ti ku ninu iwọde Kenya lati oṣu Kẹfa ọdun to kọja.
Wọ́n ti gbé Mwangi jù sí àtìmọ́lé lọ́pọ̀ ìgbà
Gẹgẹ bii ajafẹtọọ to maa n lewaju ifẹhonuhan lọpọ igba lorilẹede Kenya, ọpọ igba naa ni wọn tig be Boniface Mwangi ju si ahamọ.
Loṣu Karun-un, Mwangi ati ajafẹtọọ ọmọ orilẹede Tanzania, Agather Atuhaire, ni wọn jọ ti mọle lẹyin ti wọn mu wọn lasiko ti wọn n lọ sibi igbẹjọ olori ẹgbẹ ọmọ alatako, Tundu Lissu.
Ẹsun pe o fẹẹ doju ijọba bolẹ ni wọn fi kan Tundu Lissu.
Lẹyin ti wọn fi wọn silẹ lẹyin ọpọlọpọ ọjọ, awọn mejeeji ṣalaye pe wọn ji awọn gbe ni.
Wọn fi kun un pe wọn ba awọn ṣe iṣekuṣe ti ko yẹ pẹlu, wọn si lu awọn.
Awọn ajafẹtọọ naa sọ pe awọn ti pe ẹjọ lori eyi si kootu Ila -Oorun, fun idajọ ododo.