You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Trump fẹ́ pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lẹ́yìn tí adájọ́ kan dènà àṣẹ tó buwọ́lù láti fòfin de dídi ọmọ Amẹrika nípa ọmọ bíbí
Aarẹ Donald Trump orilẹede Amẹrika ti sọ fawọn akọroyin pe oun yoo pe ẹjọ kotẹmilọrun lẹyin ti adajọ kan ni Seattle gbegi dina iwe aṣẹ to buwọlu lati fopin si didi ọmọ oniluu nipa bibi ọmọ si orilẹede Amẹrika.
Adajọ ẹkun Seattlle l'Amẹrika, John Coughenour, ṣapejuwe iwe aṣẹ ti Trump buwọlu lati fopin si didi ọmọ oniluu nipa bibi ọmọ si Amẹrika gẹgẹ bi igbesẹ to tapa si iwe ofin orilẹede Amẹrika.
Lẹyin igbẹjọ to waye fun iṣẹju mẹẹdọgbọn ni adajọ Coughenour paṣẹ idaduro aṣẹ ti Trump pa yii.
O wa ninu iwe ofin Amerika eyi ti wọn ṣe atunṣe rẹ fun igba kẹrinla lo sọ pe ẹnikẹni ti wọn ba ti bi si Amẹrika ti di ọmọ ilu Amẹrika.
Trump fẹ fopin si eyi fawọn arinrin-ajo to ba bimọ si Amẹrika atawọn to ba bimọ si Amẹrika ṣugbọn ti wọn n gbe orilẹede naa lọna aitọ.
Ipinlẹ Washington, Arizona, Illinois ati Oregon ti faramọ ki wọn da ofin naa duro bayii.
Lasiko igbẹjọ naa ni adajọ Coughenour beere lọwọ agbọjọro to ṣoju ijọba Trump wi pe nibi lawọn agbẹjọro wa nigba ti Trump fi n buwọlu iwe aṣẹ yii.
Bakan naa ni adajọ yii tun bu ẹnu ẹtẹ lu bi agbẹjọro Trump ti sọ pe bi aarẹ ti buwọlu iwe aṣẹ lati fopin sawọn to n bimọ l'Amẹrika ki ọmọ wọn le di oniluu wa ni ibamu pẹlu iwe ofin Amẹrika.
Idaduro ti ba aṣẹ ti Trump pa yii fun ọjọ mẹrinla, bi igbẹjọ ṣe n lọ lori igbẹjọ naa.
Koko lara awọn iwe aṣẹ ti Trump buwọlu kete ti wọn bura fun un gẹgẹ bii aarẹ Amerika
Ni ọjọ Aje ogunjọ oṣu kinni ọdun 2025 ni Donald Trump pada si ipo gẹgẹ bi aarẹ kẹtadinlaadọta fun orilẹede Amẹrika.
Lati igba ti o si ti de ori ipo lo ti n ṣe awọn ikede loriṣiriṣi ati igbesẹ loniranran.
Eyi ni awọn pataki ninu awọn aṣẹ waa to ti buwọlu ati awọn igbesẹ miran to ti gbe:
Aṣẹ waa lati fopin si ọrọ ẹtọ ọmọonilu fun awọn ọmọ awọn ti ko lẹtọ igbelu
Trump ti gbe igbesẹ lati ṣe atunṣe ilana didi ọmọ onilu lorilẹede Amẹrika. O ti paṣẹ fun awọn ajọ lati dẹkun fifun awọn ọmọ ti awọn obi wọn ko lẹto igbelu tabi awọn to gba fisa fidihẹ lẹtọ lati di ọmọ onilẹ.
Itumọ eyi ni pe gbogbo awọn to maa n lọ bimọ lorilẹede Amẹrika ti ọmọ bẹbẹ yoo si di ọmọ onilu ko ni le ri anfani bẹẹ mọ.
Ọgbọn ọjọ ni wọn fun awọn ajọ ijọba gbogbo lorilẹede naa lati fi idi aṣẹ yii mulẹ.
Amọṣa o awọn onwoye ti sọ pe o ṣeeṣe ki ọrọ nipa aṣẹ yii o de ile ẹjọ.
Aṣẹ waa lori ẹya akọ ati abo
Trump buwọlu iwe aṣẹ to ni pe ẹya akọ ati abo nikan ni ẹya iṣẹda ti ijọba orilẹede Amẹrika yoo da mọ o ni awọn ẹya yii ko ṣe e yipada nitoripe ninu iṣẹda ni wọn ti jẹyọ
Aṣẹ yii yoo ni ipa lori awọn ẹlẹya iṣakọ-n-ṣabo ati iṣabo-n-ṣakọ. Bakan naa ni yoo si tun ni ipa lori iwe irinna orilẹede naa.
Aṣẹ waa lati dẹkun bi awọn eeyan ṣe n wọ orilẹede Amẹrika
Aṣẹ waa yii kede aṣẹ ilu o fara rọ lori ilana iwọle-wọde lorilẹede Amẹrika. Bakan naa ni igbesẹ yii tunbọ ṣe atunto ẹnubọde orilẹede naa pẹlu awọn alamuleti rẹ, paapaajulọ orilẹede Mexico.
Aṣẹ waa lati da Tiktok pada si Amẹrika
Aarẹ Trump buwọlu iwe aṣẹ waa kan to fun ileeṣẹ ibanidọrẹ Tiktok ni afikun aadọrin ọjọ gẹgẹbi gbedeke lati tẹle ofin ti orilẹede naa gbe kalẹ pe ki wọn ta ileeṣẹ naa tabi ki wọn gbẹsẹ le.
Titi ẹnubode
Trump tun paṣẹ ki awọn ologun o ti ẹnubode orilẹede naa pa. O tka si awọn iwa ọdaran bii ogun oloro, fifi eniyan ṣe owo kotọ atawọwọn iwa ọdaran miran gẹgẹ bi oun to n gogo sii lorilẹede naa nitori bi awọn eeyan ṣe n wọle-wọde lai si ofin to ka wọn lọwọ ko.
Aṣẹ lati kuro ni ajọ ilera agbaye, WHO
Aṣẹ waa yii bẹrẹ igbesẹ ati yọ orilẹede Amẹrika kuro lagbo ajọ ilera agbaye.
Igba keji niyi ti Trump yoo maa ni ki Amẹrika kuro lajọ naa.
Awọn aṣẹ waa miran ti Aarẹ Trump tun buwọlu niwọnyii:
- Aṣẹ to kede awọn ẹgbẹ jagidijagan ati ẹgbẹ okunkun gbogbo gẹgẹ bi ẹgbẹ agbesunmọmi.
- Aṣẹ fun titẹsiwaju pẹlu kikọ awọn odi si ori aala orilẹede naa.
- Aṣẹ "remain in Mexico" tó da awọn aṣatipo lati orilẹede Mexico pada si orilẹede wọn.
- Aṣẹ waa to gbe ijiya idajọ iku kalẹ fun ọmọ ilẹ okeere ti ko ni iwe igbelu to ba daran ati ẹnikẹni to ba jẹbi ẹsun pipa agbofinro lorilẹede naa.
- Aṣẹ to fi idaduro si eto iranwọ fun awọn ilẹ okeere duro fun Trump lati ṣe agbeyẹwo awọn eto iranwọ gbogbo ti orilẹ Amẹrika n ṣe fawọn ilẹ okeere.
- Iwe aṣẹ lati yi orukọ agbami "Gulf of Mexico" pada si "Gulf of America"