Ìlera Nnamdi Kanu ń burú si, àìsàn ń ṣe é láti inú - Agbẹjọ́rò

Ifeanyi Ejiofor agbẹjọro fun adari ikọ ajijagbara IPOB, Nnamdi Kanu, ti sọrọ sita lori ilera onibara rẹ lẹyin to lugbadi arun miiran.

Ejiofor, ninu atẹjade to fi ransẹ sita fawọn akọroyin lọjọ Aje ni onibara oun ni arun to n se eeyan ni inu ati ẹnu, ti oloyinbo pe ni Gastrointestinal Distorder.

O ni eyi to mu ki aya ma ta Kanu ni ọpọ igba.

O tẹsiwaju pe ileẹjọ giga to wa niluu Abuja labẹ isakoso Adajọ Binta Nyako, palasẹ fun ajọ DSS lati pese ilera to peye fun Nnamdi Kanu sugbọn wọn kọ.

O wa ke gbajawire sita lẹyin to ṣe abẹwo si adari IPOB naa ni ọọfisi awọn DSS niluu Abuja lọjọ Ajẹ.

“Ni bayi, Nnamdi Kanu n jẹ irora nitori aisan yii, ti o si nilo itọju ni kiakia.

“Sugbọn o ṣe ni laanu pe ajọ DSS ko fun ni anfani lati ṣe itọju ara ẹ.

“Kete ti a gbọ, ni agbẹjọro agba wa Oloye Mike Ozekhome pasẹ pe ki a bẹrẹ isẹ lati fi ofin si ifiyajẹni naa.

Kò sí ohun tí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní fún ilẹ̀ Yoruba ní 2023 -Bode George

Igbakeji alaga ẹgbẹ oṣelu PDP tẹlẹ, Olabode George ti fi aidunnu rẹ han si bi ẹgbẹ oṣelu PDP ko ṣe ni nkan gboogi lati fi dije dupo ni ilẹ Yoruba ni idibo ọdun to n bọ.

Ninu ọrọ rẹ lori eto tẹlifiṣọn Arise TV lo ti fi ero rẹ han.

Bode George ni ẹgbẹ oṣelu PDP ko dabi ẹgbẹ oṣelu APC to jẹ pe iha Guusu Naijiria ni wọn ti mu ẹni ti yoo dije du ipo aarẹ ni Naijiria ni idibo ọdun to n bọ.

Bio tilẹ jẹpe ko darukọ Bola Tinubu, o ṣe afiwe nipa rẹ ati ẹgbẹ oṣelu APC.

Idi ti PDP fi le ma ri ọwọ mu ni idibo 2023 ni ileẹ Yoruba

O ni ti ilẹ Yoruba ko ba ni ipa kan patọ to fẹ lepa ninu eto idibo naa, ko si idi ti awọn eniyan ni ilẹ Yoruba yoo fi dibo fun ẹgbẹ oselu PDP.

‘’Bawo ni mo se fẹ se ipolongo idibo ni ilẹ Yoruba ki wọn wa dibo fun ẹni ti ẹgbẹ oṣelu gbe?’’

A gbọdọ mọ wipe ẹgbẹ oṣelu alatako PDP mu oludije sipo aarẹ ni ilẹ Yoruba nitori naa awọn ni ohun ti wọn fẹ ta, amọ kini ẹgbẹ oṣelu PDP fẹ ta fun awọn ara ilẹ Niajiria?

‘’Ki awn to wa ni iha Ariwa Niajiria fi ọrọ naa yẹ ara wọn wo, ṣe wọn le faramọ ki oludije sipo aarẹ, igbakeji rẹ ati alaga ẹgbẹ ki wọn wa lati iha Guusu Naijiria, se ara wọn le gba iru rẹ.’’

‘’Ohun ti mo n sọ ni ki ẹ jẹ ki idajoẹ odoodo ati ṣiṣe didara laarin awọn eniyan jọ wọn loju.’’

‘’Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP, Iyorchia Ayu gbọdọ fi ipo silẹ’’

‘’Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP, Iyorchia Ayu gbọdọ fi ipo silẹ’’