Ọmọ méjì kú, àìsàn ṣe mi, ọdún kan gbáko ni mi ò fi rí oorun sùn láàárọ̀, ọ̀sán tàbí lóru - Alapinni Ooṣa

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Oriṣiiriṣii adanwo lo kun ile aye, ko si sẹni ti ko le kan lasiko kan tabi ikeji, afi bi Adaniwaye ba ko ni yọ lọwọ ewu.

Bi adanwo ọhun ba de nigba mi-in, ẹni to ṣẹlẹ si le ma ni anfaani lati ṣalaye ẹ ki aye gbọ, afi ti ogun ọhun ba ṣẹ tan, ti ẹmi ko bọ si i, ti ẹni naa si gbele aye sọ ohun to ṣẹlẹ fun awọn eeyan yoku .

Iru rẹ ni ti agba oṣere tiata Yoruba nni, Alagba Ganiu Nafiu ti ọpọ eeyan mọ si Alapinni ooṣa.

Apinni ooṣa ṣalaye ohun ti oju rẹ ri lasiko to ṣe aarẹ, koda, o ni oun naa mọ pe ohun to ṣoro lati gbagbọ lo ṣẹlẹ ṣi oun, ṣugbọn bẹẹ lo ri.

Agba oṣere naa sọrọ nipa bo ṣe sinku ọmọ meji, idi to fi kanra ṣọrọ si awọn APC to polongo ibo fun ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Lori ifọrọwerọ kan ti Alapinni ṣe lori eto ayelujara kan ti wọn pe ni Jeff Owolewa TV ni Apinni ooṣa ti sọ pe:

''Mi ò sùn fún ọdún kan gbáko, kò sí oorun láàárọ̀, ọsan tabi loru''

Gẹgẹ bi Alapinni ooṣa ṣe wi:

"Lori itage ti mo ti ṣiṣẹ, mo pada si ori ijoko mi, ni mo ri i pe nnkan ko ri bo ṣe yẹ ko ri lara mi.

"Mo dura pada lọ sibi ti mo de si, oorun ti mo sun nibi ti mo de si yẹn bayii, ti mo maa laju bayii, ko si oorun kankan fun mi mọ, afigba to n gbe ẹnu le ọdun kan.

'' Ko si oorun laaarọ, ọsan tabi loru, mo maa laju silẹ ni lori ijokoo.

Ṣugbọn ti eeyan ba n gbọ ohun mi nita, ko ni i mọ pe nnkan n ṣe mi.

"Mo pada sile lati ibi ti wọn ti n tọju mi ni mo gbọ pe ọmọ ọdun mẹrin ti mo fi sile ki n too kuro nile ti ku."

"Ṣe ẹ mọ pe ti apa ko ba ka araba, o maa n ka ọmọ rẹ, mo sinku ọmọ ti ọjọ ori rẹ sun mọ ọdun mẹtadinlogoji"

Alapinni fi kun alaye rẹ pe adanwo naa ko mọ bẹẹ, o ni oun tun sinku ọmọ ti ọjọ ori rẹ n sunmọ ọdun mẹtadinlogoji (37) lọ.

"Ṣe ẹ mọ pe ti apa ko ba ka araba, o maa n ka ọmọ rẹ, aanu Ọlọrun ati bi eeyan ba ṣe mu ara ẹ niwaju Ọlọrun nikan lo n ṣe atọna aye wa."

Agba oṣere naa sọ iṣẹ ere ibilẹ tawọn n ṣe n bi awọn ẹlomi-in ninu.

O ni ajẹ ko ni i fi oju ire wo ohun tawọn n pe ni ere ori itage yẹn, nitori ajẹ wa loootọ, awọn si n gbe ohun ti wọn n ṣe sita.

O fi kun un pe ẹlomiran yoo wo ere de idaji, yoo ti maa fi oju ẹni ibi wo awọn nitori Babalawo to n ṣeka tawọn fi ṣere.

Bẹẹ ni awọn ọta miran yoo fun ọrọ awọn ni itumọ miran ti yoo mu ibinu aye wa, ọrẹ ni ọta nigba mi-in bo ṣe wi.

O ni ọta miran a si maa jẹ ẹni ti awọn ko tiẹ mọ ri rara, ṣugbọn bi aye ṣe le to niyẹn.

"Ìpolongo tí mo ṣe fún APC àti ìdí tí mo fi kanra sọ̀rọ̀ nígbà tí wọn ò fún wa lówó"

Gẹgẹ bo ṣe jẹ pe awọn oṣere tiata Yoruba maa n wa lara awọn ti oloṣelu n lo fi polongo ibo lati odun pipẹ sẹyin, ti Alapinni naa si jẹ ọkan lara awọn to ba wọn kede fun Aarẹ Tinubu, oṣere naa fariwo ta loṣu diẹ sẹyin latari ai ri owo ipolongo naa gba.

Ninu ọrọ to sọ nigba naa lo ti juko ọrọ lu awọn APC lapapọ, to si ni ṣe Seyi Tinubu ko ri awọn ni, bi baba rẹ to jẹ aarẹ ko ba tilẹ raye.

"Mo kanra sọrọ nigba yẹn tori awọn ti Tinubu ran si wa ko jiṣẹ fun wa. Seyi Tinubu kọ lo jẹbi wa, Aarẹ naa si kọ, ṣugbọn awọn ti wọn n ran niṣẹ ti wọn ko jiṣẹ fun wa ni.

"Mo sọrọ ko le ba a de ibi to yẹ ko de ni, awa ti a jade polongo ibo fun aarẹ ko tori ara wa nikan jade, a jade nitori mẹkunnu ilu naa.

"Kò sí ẹlòmíràn tí a tún lè tẹ̀lé ju Tinubu náà lọ, oun la tún máa tẹ̀lé lẹ́ẹ̀kejì"

"Ẹni to ba ni mo ti gbowo ni, tabi pe owo ni mo n wa ti mo tun fi ni Tinubu la maa tẹle lẹẹkeji, o le maa wo baba tiẹ niran ko ku sinu iya"

O ni Tinubu naa ni awọn yoo tun tẹle fun saa keji, niwọn igba ti ko sẹni toun le fa kalẹ lati ile baba oun.

O ni ẹni to ba si ni ẹlomi-in to tun fẹ mu wa lẹyim Tinubu, ki tọhun mu ẹni naa wa ki aye ri i.

Alapinni sọ pe oun to kan yẹ fun Tinubu lati ṣe ni pe ko tun nnkan ṣe daadaa fun araalu ki saa keji ti yoo lọ fun too de. Ko le baa jẹ iwuri fun araalu lati dibo fun un.

"O fi kun un pe ẹni to ba n ṣepe tabi sọrọ buruku soun lori ti Tinubu yii, ko tete ri i daju pe epe ti ori rẹ le da gbe lo n ṣẹ, nitori bi wọn ba ro pe epe won yoo ja oun, ori elepe ni epe n lọ.

Ta ni Alapinni Ooṣa?

Gẹgẹ bi Alagba Ganiu Nafiu ṣe ṣalaye, o ni ọmọ Awori ni baba oun, nigba ti mama oun wa lati ilẹ Tapa.

Alapinni loun kawe alakọọbẹrẹ ni Kano, oun lọ sile keu, oun si pada s'Eko lẹyin igba naa, ṣugbọn oun ko tẹsiwaju ninu iwe mọ.

O ni ki i ṣe pe ko si owo, oun ni ko wu lati tẹsiwaju, ere tiata lo wu oun lati ṣe.

O ni latigba naa ni oun ti ko awọn kan jọ, tawọn bẹrẹ si i di aṣọ sinu lọ sode ariya, tawon yoo gba ounjẹ ajẹku wale.

Lẹyin igba naa lo ni oun darapọ mọ ẹgbẹ oṣere Oloogbe Akin Ogungbe, oun tun kuro nibẹ, oun darapọ mọ Oloogbe Ray Eyiwumi.

Ibẹ lo ni oun ti gba ominira.

Latigba naa loun si ti n ṣere lọ lai pada.

O fi kun un pe agbegbe Sanngo niluu Eko ni wọn bi oun si, Musulumi ni iya oun, nigba ti baba oun jẹ oniṣegun.

O ni ọmọ eleegun loun, eegun ati or oni wọn n ṣe nilee baba oun.

Lonii, ọkan lara awọn agba ọjẹ to n kopa baba alawo ju ninu ere Yoruba ni Ganiu Nafiu, Alapinni ooṣa.