Bí ìgbáradì fún ètò ìdìbò ṣe ń lọ káàkiri ilẹ̀ Yorùbá nìyí

Ajọ eleto idibo nipinle Osun ti bẹrẹ pinpin ohun elo idibo to ṣe koko si awọn ijọba ibilẹ kọọkan.
Ọga INEC ti ipinlẹ Osun Ọmọwe Mutiu Agboke ti ṣe ileri pe ko ni si magomago kankan ninu eto idibo yii rara.
Agboke ṣalaye pe oun ati awọn oṣiṣe to ku ti gbaradi gidigidi fun idibo to maa waye ni ọjọ Abamẹta to n bọ yii.
O fi awọn oludibo lọkan balẹ pe ki wọn jade dibo nitori aabo yoo wa fun wọn daada.
Ileeṣẹ ọlọpaa Osun ṣepade pẹlu awọn ẹgbẹ oṣelu

Kọmiṣann ọlọpaa Osun, Peter Abayomi ti pe ipade gbogbo awon ẹgbẹ oṣelu pọ lọsan yii.
“Emi ko ni fi aaye gba wahala kankan saaju, lasiko ati lẹyin idibo.”
“Ki onikaluku ṣe ikilọ gidigidi fun awọn to n dami alafia ru lati so agbejé mọwọ.”
Pinpin awọn ohun elo to ṣe koko bẹrẹ ni ipinlẹ Ekiti
Ní ìpínlẹ̀ Ekiti ẹ̀wẹ̀, ajọ eleto idibo ti pin ohun èlo idibo to se kókó sí àwọn ìjọba ìbílẹ̀ mẹrindinlogun tó wà ní Ekiti.
Ètò pinpin ohun èlo idibo naa waye ni Ọfiisi banki apapọ orilẹede Naijiria (CBN) tẹka ipinlẹ Ekiti pẹlu gbogbo awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu ati awọn agbofinro.
Kọmisanna eleto ìdìbò ni ipinlẹ Ekiti Ọjọgbọn Ayobami Salami sọ pe àjọ eleto idibo ti mura silẹ fun idibo ọjọ Sátidé yii.
Bakan naa lo sọ pe àìsí epo àbí ọwọn gogo rẹ ati àìsí owo ni igboro ko ni mu akude ba eto idibo nipinle Ekiti.
Awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu to ba akọroyin sọrọ, Olayinka Dada ti ẹgbẹ oṣelu NNPP ati Owoola Daramola alága ẹgbẹ́ IPAC nipinle Ekiti rọ ajọ eleto idibo INEC lati tẹsiwaju pẹlu ètò pinpin àwọn ohun elo idibo de gbogbo ibudo Idibo.
Ẹgbẹ́ akọ̀ròyìn ìpínlẹ̀ Ogun kọminú lórí àgbáradì INEC ní ìpínlẹ̀ náà

Ẹgbẹ́ àwọn akọ̀ròyìn, NUJ ni ìpínlẹ̀ Ogun ti bu ẹnu atẹ lu ìgbáradì àjọ eleto idibo apapọ ilẹ̀ wa, INEC tẹ̀ka ipinlẹ Ogun lórí eto ìdìbò ti yoo wáyé ní ọjọ́ Abamẹta.
Alaga NUJ ní ìpínlẹ̀ Ogun, Wale Olanrewaju nínú ìpàdé àwọn Akoroyin tí ó wáyé lónìí ní olú ile ẹgbẹ́ náà, ìwé ìròyìn Abẹ́òkúta ni kò sí àpẹẹrẹ tó fi hàn pé àjọ INEC ni ètò gidi fún eto idibo tó n bọ̀ yii.
Ko ni si aaye fun iwa jagidijagan ni Kwara - INEC Kwara


Adari ajọ eleto idibo ni ipinlẹ Kwara, Mallam Garuba Attahiru Madami ti sọ idaniloju rẹ pe eto idibo ti ko ni amulumala kankan ninu ni awọn maa ṣe aridaju rẹ pe o waye ni ipinlẹ naa.
Mallam Garuba Attahiru Madami ṣe ileri yi nibi pinpin ohun elo idibo to se koko, to si jẹ ẹlẹgẹ ni Olu Ile Ifowopamọ Naijiria ni Ilorin, Olu Ilu Ipinlẹ Kwara.
Adari ajọ naa tun rọ gbogbo ẹgbẹ oṣelu pata lati jina si iwa jagidijagan to le da eto idibo naa ru ki ohun gbogbo le lọ irọwọ rọsẹ ni ibamu pelu ofin.












