Olugbọ́n àti àwọn ọmọ Oodua míì sọ̀rọ̀ lórí ìpè Banji Akintoye láti fi September 23 sọrí àyájọ́ ìṣọ̀kan Yorùbá

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọjọgbọn Akintoye, tii se asaaju ẹgbẹ Ilana Ọmọ Yoruba, eyi to n pe fun iyapa orilẹede Yoruba kuro lara Naijiria, ti rọ awọn gomina ni gbogbo ipinlẹ Yoruba lati kede ọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹsan an lọdọọdun gẹgẹ bi ọjọ iṣọkan iran Yoruba lagbaaye.

Adari ẹgbẹ ajijagbara Yoruba Nation naa, sisọ loju ọrọ yii ninu atẹjade kan to fi sita pe awọn ọmọ Yoruba kan ṣe ayajọ ọjọ iṣọkan iran Yoruba yii niluu Ibadan ati Ile Ife.

Ọjọgbọn Akintoye fẹsun kan awọnjanduku agbegbọn ti ṣekupa ẹgbẹrun mọkandinlọgbọn ọmọ Yoruba.

Bakan naa ni adari ẹgbẹ to n pe fun iyapa Yoruba lara Naijiria naa wi pe awọn janduku agbebọn naa tun n fipa bawọn obinrin Yoruba lopọ.

O ni ọna abayọ kan ṣoṣo si awọn iṣoro yii ni ki iran Yoruba da duro gẹgẹ orilẹede.

Ọjọgbọ Akintoye sọ pe awọn Fulani ti n gbero lati gba ilẹ Yoruba lawọn igberiko ti wọn n gbe kaakiri ilẹ Yoruba.

Baba Akintoye wa rọ awọn lọba lọba atawọn gomina ilẹ Yoruba lati gbe ọrọ ayajọ ọjọ iṣọkan ilẹ Yoruba yẹwo.

Ọrọ ẹnu lasan ni Akintoye sọ tori ilẹ Yoruba wa labẹ ofin ijọba - Olugbon

BBC Yoruba wa kan si awọn oriade ati agbaagba kan nilẹ Yoruba lati mọ ero wọn si ipe Akintoye lati fi ọjọ Kẹtalelogun osu kẹsan ọdọọdun sọri Ọjọ Isọkan Youba.

Nigba to n sọ ero rẹ lori ipe yii fun BBC Yoruba, Olugbon ti Orile Igbo, Ọba Oba Francis Olusola Alao, sọ pe bi adari ẹgbẹ to n pe fun idasilẹ orilẹede Yoruba, Ọjọgbọn Banji Akintoye ṣe n pe fun ayajọ ọjọ iṣọkan Yoruba dara.

Amọ, kabiyesi naa sọ ninu ifọrọwerọ to ṣe lori foonu pẹlu BBC Yoruba wi pe, ọrọ ẹnu lasan si ni Ọjọgbọn Akintoye sọ tori ilẹ Yoruba wa labẹ ofin ijọba.

Lana ọjọ Aje ọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹsan an ni Ọjọgbọn Akintoye kepe awọn ọba alaye atawọn gomina ipinlẹ Yoruba wi pe ki wọn maa jẹ ki araalu ṣe ayajọ ọjọ iṣọkan iran Yoruba ni gbogbo ọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹsan an lọdọọdun.

'' Gbogbo awa lọbalọba, awọn gomina atawọn lajọ lajọ la gbọdọ jokoo papọ jiroro lori ohun ti a ba fẹ ṣe lori isọkan ilẹ Yoruba"

Olugbọn ni gbogbo ipinlẹ Yoruba lo wa labẹ iṣakoso ijọba alaṣẹ, o ni labẹ aṣẹ awọn ijọba yii nilẹ Yoruba wa.

Olugbon tẹsiwaju pe ‘’Ọjọgbọn Akintoye pe mi laipẹ yii wi pe oun fẹ ki iran Yoruba wa ni iṣọkan.

Mo sọ fun un pe emi naa maa gbaruku ti ohunkohun to ba maa mu iṣọkan ati alaafia jọba laarin iran Yoruba.

Ṣugbọn a gbọdọ ṣe ohun kohun ti a ba fẹ ṣe ni ibamu pẹlu alakalẹ ofin.

Ati pe gbogbo wa lati ori awọn lọbalọba, to fi dori awọn gomina atawọn lajọ lajọ ni a gbọdọ jọ jokoo papọ jiroro lori ohun ti a ba fẹ ṣe.

Fun apẹẹrẹ, abẹ iṣakoso ijọba ibilẹ ni awa lọba lọba wa lawọn ipinlẹ Yoruba.

Ọjọgbọn Akintoye ni ero rere nipa gbigbe aṣa ati iran Yoruba larugẹ, amọ, a gbọdọ ṣe ohun kohun ti a ba fẹ ṣe labẹ ofin.

Nkan ti a tun le ṣe ni pe ki gbogbo ọmọ Yoruba atawọn gomina pejọ lati dibo lori ohun kohun ti a ba fẹ ṣe.

Iran Yoruba lapapọ lagbaaye ju aadọtan miliọnu eeyan lọ, nitori naa, ọrọ yii kii ṣe nkan tawọn eeyan kan maa jokoo lati gbe igbesẹ lori rẹ,'' Olugbon ṣalaye.

Aarẹ ẹgbẹ igbimọ Yoruba lagbaye sọ idi ti September 23 fi yẹ ko jẹ ọjọ isọkan Yoruba

Ninu ọrọ tiẹ, aarẹ igbimọ apapọ Yoruba lagbaaye, Yoruba Council Worldwide, Amofin Oladotun Hassan, ṣalaye pe kii ṣe Ọjọgbọn Akintoye lo mu ọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹsan an gẹgẹ bi ọjọ iṣọkan Yoruba.

Amofin Hassan ni ọjọ yii jẹ ọjọ ti ogun Kiriji pari nilẹ Yoruba.

‘’Ọjọ yii ni a fi ọkọ ati ada ti a fi n pa ara wa gunlẹ wi pe a o ja mọ, ọjọ yii jẹ ọjọ aṣaro lori iṣọkan ilẹ kaarọ oo jire.

Kii ṣe baba Akintoye lo pe ọjọ yii ni ọjọ iṣọkan ilẹ Yoruba, ọjọ to ti ni itan lori ni.

Ati pe ọjọ ti gbogbo lẹgbẹlẹgbẹ ninu Yoruba fọwọ si ọjọ naa,’’ Amofin Hassan.

Aarẹ ẹgbẹ YCW sọ pe ẹgbẹ igbimọ apapọ Yoruba lagbaaye eyi toun jẹ oludari rẹ fontẹ lu ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹsan an yii gẹgẹ bi ọjọ iṣọkan iran Yoruba.

Ọgbẹni Hassan ni o ṣe pataki lati maa ranti awọn akọni ilẹ Yoruba ti wọn ba ogun Kiriji lọ.

O yẹ ki a maa wo nkan pato ti wọn ku le lori ki a wo bi a ṣe le anfani yẹn mu iṣokan ba ilẹ Yoruba.

Amọ, amofin Hassan ni ṣe iran Yoruba ṣetan lati fohun ṣọkan, ‘’ṣe Yoruba ṣetan lati sọrọ ilọsiwaju ilẹ kaarọ oo jire?’’

Aarẹ ẹgbẹ YCW sọ pe ọna iran Yoruba si jin si iṣọkan pẹlu gbogbo nkan to n ṣẹlẹ nilẹ Yoruba.

O ni ọrọ iṣọkan kii ṣe ohun ti eeyan n fi ori ahọn ṣe, kii sii ṣe ohun ti eeyan le fi tẹnbẹlẹkun gbin.