Pre-eclampsia: Àìsàn aláboyún tó jẹ́ àdììtú tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́nsì kò rí tú

    • Author, By David Cox
    • Role, Journalist
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aisan yii n fa iku alaboyun to le ni 70,000 lọdọọdun - amọ awọn onimọ sayẹnsi ko tii mọ koko nnkan to n fa a.

Lẹyin to ti ṣe aṣeyọri to ni ogo lẹnu iṣẹ gẹgẹ bii elere sisa, ninu eyi to ti gba ami ẹyẹ goolu meje ni idije Olympics, mẹrinla fun World Championship, Allyson Felix lero pe oyun nini yoo rọrun bi ere sisa.

Sugbọn nigba to lọ fun ayẹwo ọlọsẹ mẹtadinlogoji nile iwosan, iyalẹnu lo jẹ nigba ti wọn sọ fun pe o ni aisan Pre-eclampsia to l'agbara.

Aisan yii ma n waye ninu oyun, o si lewu pupọ nitori pe o ma n fa ẹjẹ riru, o si ma n bà awọn ẹya ara jẹ. Wọn tun sọ fun pe o nilo ki wọn da a duro sile iwosan ni kiakia.

Ni ọjọ keji, awọn dokita ṣe iṣẹ abẹ pajawiri, eyi to mu ko bi ọmọ rẹ, Camryn, ni oṣu meji ṣaaju ọjọ to yẹ ki wọn o bi. Ibudo itọju awọn ọmọ ti oṣu wọn o pe si ni ọmọ naa wa fun oṣu kan.

Ko to di pe iṣẹlẹ naa waye, ko si àpẹẹrẹ kankan pe, nnkan n ṣe Felix ati ọmọ inu rẹ, ayafi ẹsẹ rẹ to wu.

"Iyẹn o ba mi lẹru rara, sugbọn mo kiyesi pe Protein ma n wa ninu ìtọ̀ mi, ati ifunpa giga."

Bo tilẹ jẹ pe Camryn ti pe ọmọ ọdun marun-un bayii, ti ilera rẹ si duro daadaa, Felix tun ti ri ẹni to ni aisan naa.

Tori Bowie, akẹẹgbẹ rẹ, to tun gba ami ẹyẹ oriṣiriṣi, ku nitori aisan Pre-eclampsia lasiko to n rọbi ọmọ. Ẹni ọdun mejilelọgbọn ni.

Iwadii sọ pe Pre-eclampsia n pa alaboyun to le ni 70,000, ati iku oyun inu bii 500,000 ni ọdọọdun.

O tun ma n fa aisan rọpa-rọsẹ tabi ẹjẹ riru ọlọjọ pipẹ.

O le waye ninu oyun lai fi àpẹẹrẹ kankan han. Ko to o pe ọsẹ mẹrinlelọgbọn lo ti ma n bẹrẹ ninu agọ ara awọn alaboyun mii.

Obinrin tun le ni Pre-eclampsia laarin ọsẹ mẹfa lẹyin to bimọ.

Òye diẹ ninu awọn onimọ sayẹnsi ri nipa nnkan to n fa Pre-eclampsia - ti ile ọmọ ba wu ju bó ṣe yẹ, eyi ma n koba ibaṣepọ laarin ara iya ati oyun inu, paapaa o ma ni ṣe akoba fun awọn ọpa to n gbe ẹjẹ lọ si ara ikeji ọmọ, ẹya to n gbe awọn eroja aṣaraloore ati eemi ti oyun inu nilo.

Nitori pe bi ẹjẹ ṣe n ṣan ninu ikeji ọmọ ko ja geere, o n tako bi ara iya ṣe n ṣe akoso ìgbòkègbodò ẹjẹ ara rẹ, eyi to si n yọri si ifunpa giga, to n fa Pre-eclampsia.

Ọjọgbọn Ian Wilkinson, onimọ nipa aarun, ni Fasiti Cambridge, orile-ede United Kingdom, sọ pe awọn obinrin ti ọjọ ori wọn ti le ni ogoji ati awọn to sanra, wa ninu ewu lati ni aisan naa.

"Idi ni pe o nira fun agọ ara wọn lati gba ipa ti oyun ma n ni lara obinrin.

Sibẹsibẹ, aditu ṣi ni idi ti awọn obinrin kan fi n ni Pre-eclampsia, eyi ti kii fi àpẹẹrẹ kankan han ni ọpọ igba, ati idi tì awọn kan kii fi i ni.

Ni pataki, ida ọgọta ni awọn obinrin alawọ dudu to n ni, ti ipa rẹ si tun ma n l'agbara pupọ.

Àwọn oniwadii kan gbagbọ pe airi ounjẹ aṣaraloore jẹ ati eto adojutofo ilera lo n fa eyi.

Ni bayii ti imọ ijinlẹ ti lagbara si, ti eto ayẹwo to muna doko si ti n waye, o ṣe e ṣe ki awọn onimọ sayẹnsi le tan imọlẹ si awọn to wa ninu ewu julọ, ati idi to fi ri bẹẹ.