You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Báwo ló ṣe yẹ kí ìbálòpọ̀ pẹ́ tó láàrin tọkọ-taya?
- Author, Busayo James-Olufade
- Role, Broadcast Journalist
Wakati tabi iṣẹju melo lo yẹ ki ibalopọ fi waye laarin ọkọ ati iyawo?
Eyi jẹ ibeere kan to wọpọ laarin awọn lọkọlaya kaakiri agbaye pẹlu ariyanjiyan oriṣiriṣi to maa n waye lori iye iṣẹju to kere ju tabi to pọ ju lati fi gbadun ara ẹni.
Awọn eeyan kan gbagbọ pe ibalopọ ti ko ba pe iṣẹju marun-un ti kere ju, bẹẹ ni awọn kan ri i pe ibalopọ to ba tun kọja iṣẹju mẹẹdogun ti pọ ju.
Eyi to wu ko jẹ erongba rẹ, o ṣe pataki lati mọ iye iṣẹju to kere tabi pọju, ti o si le gbe igbesẹ to yẹ, to ba ni ipenija nipa ilera ibalopọ rẹ, boya o jẹ obinrin tabi ọkunrin.
Gẹgẹ bi akọsilẹ to wa lati ajọ ilera Heathline, bi iwe iroyin The Mirror ṣe sọ ninu akanṣe iroyin kan, asiko ti nkan ọkunrin wọ oju ara obinrin, ni a le pe ni ibẹrẹ ibalopọ, ti asiko ti ọkunrin dà omi ara rẹ, si jẹ opin akoko ibalopọ naa.
Awọn onimọ nipa ibalopọ kan ti ẹ tun sọ pe ibalopọ ti bẹrẹ lati iṣẹju ti tọkọtaya ba ti n se ere ifẹ, fi ẹnukonu, ati awọn nkan mii to n pese ara wọn silẹ fun ibalopọ gan-an.
Iṣẹju marun-un aabọ lo wọpọ ti ọpọ tọkọtaya fi maa n ni ibalopọ - Onimọ
Ọmọwe kan ni fasiti Queensland, Brendan Zietsch, sọ fun iwe iroyin The Conversation pe iwadii laarin ẹẹdẹgbẹta tọkọ-taya fihan pe ibalopọ ma n waye laarin iṣẹju aaya mẹtalelọgbọn si iṣẹju mẹrinlelogoji.
Amọ iṣẹju to wọpọ ni marun-un aabọ.
Iwadii naa tun sọ pe bi tọkọtaya ba ṣe n dagba si ni ọjọ ori, ni iye iṣẹju ti wọn fi n lopọ yoo ma a dinku.
Iṣẹju melo lo dara fun ibalopọ?
- Ibalopọ ti ko ba to iṣẹju mẹta nilo ayẹwo nileewosan
- Ibalopọ to waye laarin iṣẹju mẹta si meje bojumu
- Ibalopọ laarin iṣẹju meje si mẹtala ko buru ju, ṣugbọn to ba kọja bẹẹ, o ti pẹ ju.
Ki lo le mu tọkọtaya lo iṣẹju perete lasiko ibalopọ?
Ki ọkunrin tete dà.
Eyi ni awọn onimọ sọ pe o wọpọ ninu aisan ibalopọ to n ṣe ọkunrin.
Ileeṣẹ eto ilera ilẹ Gẹẹsi, NHS, sọ pe ọkunrin gbọdọ lọ fun itọju to ba jẹ pe bi ilaji gbogbo asiko to ba ni ibalopọ, lo tete ma n da laarin iṣẹju kan.
Awọn nkan to si le fa a ni aisan ninu koropọn, oogun oloro, iporuru ọkan, iṣoro ninu igbeyawo, aifun ara ni isinmi to, tabi ibanujẹ ọkan.
Nitori pe a fẹ pẹ ninu ibalopọ, eyi ko tumọ si pe ko wa a sọ di ere sisa ọlọgbọnrangandan. Ti ibalopọ ba pẹju boṣeyẹ, o le fa ọgbẹ fun obinrin.
Eyi ko ṣẹyin bi omiran rẹ se le gbẹ lasiko ibalopọ to pẹju, ti yoo si ma a fa irora ati ipalara si oju ara rẹ bi ọkunrin ba ṣe n wọle, to n jade.
Ọna lati mu ibalopọ pẹ
Ẹ ba ara yin sẹ ere ifẹ daadaa lati pese ara yin silẹ
Gbe gbogbo àníyàn aye ati awọn nkan to n ba ọ lọkan jẹ tì si ẹgbẹ kan ṣaaju ibalopọ
Ki tọkọtaya ni ibalopọ ni asiko ati ibi ti ẹnikẹni ko ti ni di wọn lọwọ
Eyi to sẹ pataki ni pe ki tọkọtaya fi si ọna pe ibalopọ wọn kii ṣe ere ije ti wọn fẹ fi gba ife ẹyẹ. Amọ o jẹ ọna lati tẹ ara wọn lọrun.
Nitori naa lo ṣe ṣe pataki lati ni asọye laarin ara wọn lori awọn ipenija wọn ati ọna ti wọn fi le gbadun ara wọ̀n.