You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ààrẹ Tinubu kéde wíwọ reluwé lọ̀fẹ̀ẹ́ fún oṣù mẹ́fà l'Abuja
Aarẹ Bola Tinubu ti buwọlu afikun lilo ọkọ Reluwe to n jẹ Abuja Rail Mass lọfẹẹ fun oṣu mẹfa.
Aarẹ sọ eyi nigba to n sọrọ nibi ifilọlẹ oju opopona Reluwe niluu Abuja.
Saaju ni Minisita fun Olu ilu Naijiria, Nyesom Wike ti kede lilo reluwe naa lọfẹẹ fun oṣu meji, lati pe ṣe iranwọ fun araalu latari bi ile ko ṣe rọrun lasiko yii.
Ọsẹ to kọja ni Wike kede sita pe ọkọ Reluwe naa yoo bẹrẹ iṣẹ lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu karun un, ti yoo si wa fun lilo awọn araalu lọfẹ fun oṣu meji.
Nigba to n kan sara si Minisita, Aarẹ Tinubu ni oun gbọ ti Wike ni lilo ọsọ reluwe naa lọfẹ yoo wa fun araalu fun oṣu meji sugbọn o rọ ko sọ di oṣu meji.
“Baba onile ati awọn ikọ rẹ, mo gbọ ti ẹ n sọ pe lilo ọkọ reluwe lọfẹ wa fun oṣu meji. Mo rọ yin lati jẹ ko wa titi ọdun yooo fi pari.
“Bo ti lẹ jẹ pe, ẹ ko gba owo lọwọ mi lonii, eyi yoo fun araalu ni ireti ati idi lati dunu.”
Ki ni Aarẹ ba ile igbimọ aṣofin sọ?
Aarẹ Bola Tinubu ba ile igbimọ aṣofin kekere ati agba sọrọ niluu Abuja to jẹ olu ilu orilẹede Naijria.
Abẹwo Tinubu si awọn aṣofin lo da lori ayajọ ọdun kẹdọgbọn ti ijọba awarawa ti gbilẹ.
Aarẹ, ẹni to kọwọrin pẹlu pẹlu igbakeji rẹ, Kashim Shettima, de si igbimọ aṣofin ni ado mejila.
Bi Aarẹ se wọle ni awọn aṣofin fi orin iyin orilẹede ti Aarẹ sẹsẹ buwọlu fi ki kaabọ.
Nigba to n ba awọn sọrọ, Aarẹ ni oun dupẹ lọwọ aṣofin fun ijọsepọ wọn lati mu ijọba awarawa gninlẹ lorilẹede Naijria.
“Lia tabuku si ẹnikẹni, mo fẹ dupẹ lọwọ gidi gan.
“Ẹyin ọrẹ wa, ọlẹ araalu, mo ki yin ku orire ijọba awarawa ọdun kẹdọgbọn.”
Aarẹ tun kan sara si awọn aṣofin fun bi wọn fọwọsowọpọ pẹlu ijọba apapọ lati mi idagbasoke ba orilẹede Naijiria.
“Iranlọwọ lati oke okun ko le to, gbogbo ọmọ ilẹ Naijiria ni lati fọwọsowọpọ fun idagbasoke orilẹede yii fun ọjọ ọla.”
Kí ló fàá tí May 29 fi p'orúkọ̀ dà kúrò ní àyájọ́ ìjọba Tiwantiwa ní Nàìjíríà?
Ìgbà n yí, Ọlọrun nikan ni ki i yipo pada.
Lati ọdun kẹẹẹdọgbọn sẹyin (25 years) ti orilẹ-ede Naijiria ti n ba ijọba Tiwa-n-tiwa bọ lai lo ilana mi-in, ni ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un ọdun (May 29) ti maa n jẹ ọjọ to lapẹẹrẹ.
Eyi ri bẹẹ nitori ayajọ ọjọ naa ni Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ bẹrẹ iṣakoso awarawa yii ni 1999.
Ayẹyẹ ọdun kan rẹ si waye layajọ yii kan naa lọdun 2000 to tẹle e.
Lati ọdun 2000 naa, ko si May 29 ti ki i ṣe isinmi lẹnu iṣẹ kari orilẹ-ede yii.
Afi nigba to di ọjọ kẹfa, oṣu kẹfa ọdun 2018, ti aarẹ igba naa, Muhammadu Buhari, kede pe May 29 ko ni i maa jẹ ayajọ ijọba awarawa mọ.
Buhari paṣẹ pe June 12, ọjọ kejila oṣu kẹfa ni yoo maa jẹ ọjọ ijọba Tiwa-n-tiwa ti isinmi yoo si maa wa kari ni Naijiria.
Lati 2018 naa ni May 29 ko ti jẹ ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ mọ, bẹẹ ni Naijiria ko sami Demokresi ninu rẹ mọ. O di ọjọ lasan.
Àlàyé lórí àyipadà náà
Ninu alaye Muhammadu Buhari lori idi to fi ṣe ayipada awọn ọjọ yii nigba naa, o ni oun ṣe bẹẹ lati bu ọla fun Oloogbe MKO Abiọla ni.
MKO Abiọla ni ẹni naa ti gbogbo eeyan gbagbọ pe o yege ninu ibo aarẹ Naijiria to waye lọjọ kejila, oṣu kẹfa ọdun 1993.
Ṣugbọn ijọba ologun Ibrahim Babangida igba naa fagile ibo ọhun, Abiọla ko di aarẹ Naijiria. Bẹẹ lo si ku satimọle ni 1998.
Lati ma gbagbe ifarajin ati ijiya awọn eeyan kan lori ijọba awarawa yii, Buhari sọ pe oun ri i pe June 12 ṣe pataki ninu itan, idi niyẹn toun fi fagile May 29.
Ki lo de ti ijọba fi kuna lati kede isinmi lẹnu iṣẹ ni gbogbo May 29?
Ohun to foju han ni pe pẹlu bo ṣe ti pe ọdun mẹfa ti May 29 ti kuro lọjọ isinmi, awọn eeyan ṣi n beere pe ṣe ọlude ọhun ko ni i maa waye mọ ni.
Ṣe tẹlẹ, ko sohun to n yẹ ẹ, isinmi ni karii Naijiria.
Ṣugbọn lẹyin ọdun mẹfa, ayẹwo ati iwadii ṣi fi han pe ọpọ eeyan lo n fẹ ki ayajọ oni yii jẹ ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ.
Koda, laarin awọn alajọṣiṣẹpọ, ọrẹ, araale ati ara adugbo, eeyan pupọ lo ti fọkan si i pe isinmi ni May 29 ọdun yii yoo tun jẹ.
Awọn mi-in ti n foju sọna fun ikede isinmi lati ọfiisi minisita fun ọrọ abẹnu, Olubunmi Tunji-Ojo lati ọjọ kejidinlọgbọn oṣu karun-un.
Ṣugbọn nigba ti ko sohun to jọ bẹẹ ti ilẹ May 29 fi mọ, kaluku gba ibi iṣẹ rẹ lọ.
Fun awọn eeyan ti wọn reti eyi, June 12 de tan, Ayajọ Demokresi, ijọba awarawa tijọba fọwọ si niyẹn.