Akọ ajá pit bull fa ọmọ ọdún mẹ́jọ ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ ní South Africa

Awọn ọmọ orilẹ-ede South Africa ti ke si ijọba ilẹ naa bayii pe ko fofin de sinsin akọ aja pit bull ninu ile nitori ewu to wa ninu aja naa.

Ẹbẹ yii lo n waye lẹyin ti aja pit bull kan ṣekupa ọmọ ọdun mẹjọ lagbegbe Vista Park, ni Bloemfontein.

Iroyin ni ṣe ni aja ọhun ja okun ti wọn fi de ninu ile rẹ ti wọn so mọ, to si fo ori ogiri lọ sinu ọgba ile ti ologbe naa wa ni nnkan bii aago meji ọsan.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Lt-Col Thabo Covane, sọ pe aja naa kọlu oloogbe ọhun nibi to ti n ṣere, to bẹrẹ si n ge jẹ ni ọrun ati aya.

O ni “Nigba ti awọn adoola ẹmi lati ileeṣe ọlọpaa yoo fi de ọgba ile naa, oku ọmọ naa ni wọ ba.”

“Lẹyin naa ni wọn yinbọn pa aja ọhun.”

Kii ṣe igba akọkọ ree ti aja yoo pa eeyan ni South Africa

Orilẹ-ede South Afria lawọn eeyan ti n ku lọwọ aja julọ lagbaye, gẹgẹ bii awọ iroyin kanṣe sọ.

Ninu oṣu Kẹwaa, ọdun 2022 yii, aja pit bull meji pa ọmọ ọdun mẹwaa kan, bo tilẹ jẹ pe mọlẹbi ọmọde naa lo ni awọn aja ọhun.

Nibayii, ko din ni ẹgbẹrun lọna aadọta eeyan to ti tọwọ bọwe lori ayelujara pe awọn ko fẹ pit bull gẹgẹ bii ẹrabko inu ile mọ ni South Afria.

Ajọ to n ṣagbatẹru ẹbẹ awọn eeyan naa, Sizwe Kupelo Foundation sọ pe eredi igbesẹ awọn ko ṣeyin bi aja pit bull ṣe n pa awọn eeyan lorilẹ-ede naa.