You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kí ló ń ba àwọn ọmọ Africa to n ṣ'àtìpó l'America lẹ́rù bí ìbò ṣe ń súnmọ́lé?
Fun ọpọ ọmọ ilẹ Africa ti wọn n ṣe atipo l'America, iyẹn awọn ti wọn n gbe niluu naa nitori aabo ti ko si lorilẹede tiwọn, idibo to ku dẹdẹ yii le yi ọjọ iwaju wọn pada si idakeji.
“ O yẹ ki aabo wa fun wa,”Dokita Yves Kaduli, ẹni ọdun mejidinlogoji, ọmọ orilẹede Congo to n gbe l'America lo sọ bẹẹ. “ Ala mi ni lati daabo bo awọn eeyan to ba n koju ifiyajẹni.”
Ni 2014 ni Kaduli sa kuro ni apa Ila-Oorun ilẹ Olominira Congo, lẹyin igba ti wọn ji i gbe ti wọn si fi iya nla jẹ ẹ nitori ero ọkan rẹ to sọ jade nipa oṣẹlu ilu naa.
Wọn dunkooko iku mọ ọn, to bẹẹ to sare kuro ni Congo lai mu ọmọ rẹ ọkunrin, ọmọ ọdun mẹwaa dani. Dokita Kaduli fi ọmọ naa silẹ fun awọn obi tiẹ lati maa ba a tọju ni.
Lẹyin ọdun marun-un to ti sa kuro l'Africa, Virginia ni Dokita Kaduli n gbe bayii, to si n ṣiṣẹ nibẹ gẹgẹ bii dokita oniṣegun oyinbo, bẹẹ lo si n reti ohun ti yoo ṣẹlẹ lorii alaye to ṣe fun wọn pe aabo loun wa de America lati Congo.
Ọkan ninu awọn ọgọọrọ ọmọ ilẹ Africa ti wọn fori laku lọ si ilẹ okeere, titi de ẹnu ibode US-Mexico ni Dokita Kaduli yii, wọn si n pọ si i niye ni.
Ṣugbọn bi ọpọ ọmọ America ṣe n sọ pe nnkan ni ọrọ awọn arinrinajo yii ninu ibo to n bọ, ti awọn ondupo naa si n sọ ohun ti yoo ṣẹlẹ ni awọn ẹnu ibode, niṣe lẹru n ba awọn atipo, ko ma di pe iya yoo jẹ wọn.
“A ri i bawọn oloṣelu ṣe n fi oju ọdaran wo wa, ti wọn sọ agbegbe wa di ibi to lewu, nigba to si jẹ pe aarẹ ni wọn, wọn nipa lori ọjọ iwaju wa,” Dr Kaduli lo sọ bẹẹ.
Àwọn tó n wọlu n pọ si i, ewu fáwọn tí kò r'ọ́nà wọlé
Ni 2022, o to ẹgbẹrun mẹtala (13,000) ọmọ Africa ti akọsile sọ pe wọn wọ ẹnu ibode US-Mexico, gẹgẹ bi akọsilẹ ileeṣe aṣọbode America ṣe sọ. Nigba ti yoo fi di 2023, onka yii ti ju ilọpo mẹta lọ, o di 58,000.
Bakan naa ni akọsilẹ United Nations High Commissioner for Refugees (UNHCR) fi han pe onka awọn to sa asala lati Africa gunke si i gan-an. Awọn ilu bii Senegal, Mauritania ati Guinea ni wọn pọ ju lati 2022 ni ẹnu ibode yii kan naa. Lati Senegal lasan, onka awọn to fẹẹ wọle fo soke si 773 ni 2022, 13,224 ni 2024.
Bo tilẹ jẹ pe nnkan ṣi dẹrun diẹ ni Senegal ju awọn ilẹ alawọ dudu mi-in lọ, sibẹ, o kọja ida mẹta awọn eeyan ibẹ ti iṣẹ ati òṣì n ba finra, gẹgẹ bi Banki Agbaye ṣe fidi ẹ mulẹ. Ko rọrun fun awọn ọmọ ilẹ Africa lati fi da awọn oyinbo loju pe atipo lawọn fẹẹ waa ṣe .
Ai gbọ ede ibi ti wọn de si tun maa n jẹ wahala, ai si mọ iha ti awọn ti wọn waa ba kọ si adulawọ tun jẹ iṣoro kan to n koju wọn. Kathleen Bush-Joseph to n ṣiṣẹ lẹka igbaniwọle arinrinajo lo sọ bẹẹ.
“Awọn adajọ ibi ati awọn olootu eto idajọ ko mọ ogun to n le awọn eeyan bọ lati Africa ” Kathleen Bush-Joseph, lo fi kun alaye rẹ bẹẹ.
‘Ìbẹ̀rù-bojo ńlá’
Nigba to n kin ẹru to n ba awọn atipo lẹyin, Nils Kinuani, aṣoju nileeṣẹ African Communities Together (ACT), iyẹn awọn to n ṣatilẹyin fun awọn atipo, ṣalaye pe ẹru nla lo n ba awọn atipo bayii pẹlu ipolongo ibo to n lọ l' America.
“ Ẹru n ba awọn eeyan gan-an, wọn n ro o pe wọn le kọlu wọn” Kinuani lo sọ bẹẹ
ACT n rọ awọn ileeṣẹ yooku lati ran awọn atipo lọwọ, nitori ẹru n ba wọn ki wọn ma baa da wọn pada siluu wọn.
Ọna abayọ kan ṣoṣo to wa fun wọn, ni ti awọn oniluu ba ṣaanu fun wọn nipa iranlọwọ ọmọniyan. Eyi yoo jẹ kawọn eeyan ti ogun le de ribi duro si .
Awọn alaṣẹ America lo le fi oju aanu yii wo wọn, ti wọn yoo si maa gbe nibẹ fun igba diẹ, wọn yoo maa ṣiṣẹ pẹlu.
Awọn atipo ti wọn ti jẹ anfaani yii ni Ukraine, Cuba, Nicaragua, Haiti, Venezuela ati Afghanistan.
Bakan naa ni ewu n bẹ fawọn ti wọn ti fẹẹ wọ US ti wọn ko ri i wọ.
Ni 2022, ajọ to n ri si ẹtọ ọmọniyan, Human Rights Watch (HRW) fi atẹjade kan sita to ṣalaye pe ọpọ awọn ọmọ Cameroon ti wọn fẹẹ waa ṣatipo ni wọn ju si ẹwọn. Wọn ni wọn fiya jẹ awọn ẹlomi-in gidi, wọn fipa ba awọn kan lo pọ lẹyin ti wọn le wọn pada lẹnu ibode America.
“ Wọn da awọn eeyan pada sinu ewu ati idajọ, nigba to foju han pe wọn ko tẹle ilana otitọ ẹtọ ọmọniyan”, Oluwadii, Lauren Seigbert lati HRW lo ṣalaye bẹe
“Ewu nla ni lati maa da awọn eeyan pada gẹgẹ bo ṣe sọ.
Ko si eto fifi ọmọniyan ṣe, tabi ṣiṣe aanu ẹnikeji laaarin US ati ilẹ Africa.
Ni nnkan bii ọsẹ diẹ ti ogun bẹ silẹ ni Ukaraine, wọn fi aaye silẹ fawọn ọmọ ibe to n sa fun ogun lati le jẹ anfaani aanu yii.
Lati oṣu kẹrin 2023, ogun to n waye ni Sudan ti sọ miliọnu mẹsan-an eeyan di alarinkiri. Gẹgẹ bi Nils Kinuani, alamohuto African Communities Together (ACT), ṣe sọ.
Ẹgbẹ́ òṣèlú méjéèjì ni wọ̀n fẹ́ẹ́ mú ti àtìpó gbọ́.
Ẹgbé oṣelu Democratic Party ati Republican l'America ni wọn ti kede pe awọn yoo mu ti awọn atipo gbọ. Wọn sọ eyi ninu ipolongo ibo wọn.
Donald Trump to wa fun Republican ti sọ pe oun yoo le awọn ajeji jade niluu naa to bẹẹ gẹẹ ti iru rẹko ni i si niu itan America ri.
Kamala Harris lati Democratic ni tiẹ ṣeleri lati mojuto ajọsẹpọ awọn arinrinajo, awọn atipo.
Iṣakoso to n lọ lọwọ l'America, ti Kamala jẹ Igbakeji aarẹ, ti gbe igbesẹ lati mu ọrọ ẹnu ibode ni koko, labẹ ofin kan ti wọn ṣe loṣu Kẹfa.
Awọn alaṣe le sare le ẹni to n ṣe atipo danu, to ba ti jẹ pe ọna ẹburu lo ba wọ America.
Eyi ti ran wọn lọwọ daadaa lẹnu ibode naa gẹgẹ bi awọn alaṣẹ ẹnu ibode ṣe sọ.
''Ó ti yé wa pé wọ́n ń fi ṣíṣe àtìpó parọ́ wọ America ni''
Bi nnkan ṣe n lọ yii, o ti ye awọn eeyan pupọ l'America, pe ọpọ awọn ti wọn n wọle sorilẹde naa labẹ eto atipo ṣiṣẹ n parọ wọle ni.
“ Ni US, ilanilọye n waye si i lati jẹ ka mọ pe pe ọpọ eeyan to n wọle sibi labẹ eto atipo yii n purọ wọle ni'' Kathleen Bush-Joseph lo sọ bẹẹ
Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí Dókítà Kaduli lọ́wọ́ yìí?
Ni bayii, Dokita Yves Kaduli wa lagbedemeji.
O le jẹ pe yoo ni lati duro fun ọdun mẹrin si mẹwaa lati mọ ohun ti yoo gbẹyin diduro rẹ l'America.
Ni nnkan bii ọdun diẹ sẹyin ni baba rẹ ku, ṣugbọn ko le lọ sile lati ṣẹyẹ ikẹyin, nitori ko le jade niluu to wa yii rara.
“ Ko rọrun fun mi bi mi o ṣe mọ ibi ti ọrọ mi yoo ja si, mo si n ri ohun tawọn oloṣelu yii n sọ lorii tẹlifiṣan ati iwe iroyin, ṣugbọn mo mọ pe o ni idi kan ti mo fi wa nibi.''
Ireti rẹ ni pe iya ati ọmọ rẹ yoo wa ba a l'America lọjọ kan.