Ẹ̀ṣọ́ ààbò kó sí gbaga ọlọ́pàá torí ó pa ajá ní Lekki, Eko

“Mo ń ṣàárò bí ajá mi, Roxie ṣe máa ń fò lémi. Orí bẹ́ẹ̀dì kan ni èmi àti Roxie máa ń sùn, mo ṣàárò rẹ̀ gidi gan.”

Ohun tí Okoli Esther bá BBC Pidgin sọ nìyí lórí ìfaǹfà tó wáyé láàárín òun àtàwọn aláṣẹ ibùgbé tí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ń gbé lẹ́yìn tí wọ́n pa ajá rẹ̀ kan tó ń jẹ́ Roxie.

Ní ọjọ́ Kejìlélógún oṣù Kẹta ni orí ayélujára Twitter ń gbóná janjan nígbà tí ènìyàn kan fi ìròyìn léde pé àwọn aláṣẹ ibùgbé àwọn pa ajá òun.

Fídíò tó wà lórí ayélujára ṣàfihàn àwọn ìgbà tí Esther àti ajé rẹ̀, Roxie lò papọ̀ àti ìgbà tó ń kú lọ lẹ́yìn tí wọ́n yìbọn fún un lọ́rùn.

Fídíò náà tún ṣàfihàn bí wọ́n ṣe sọ Roxie sínú àpò lẹ́yìn tó kú tán.

Esther ṣàlàyé fún BBC pé Roxie jẹ́ ẹ̀yà ajá American Bully tí òun gbé lọ sílé ẹ̀gbọ́n òun nígbà tí ajá òun mìíràn ìyẹn Lhasa Apso bímọ.

Ó ní inú ọgbà Cooperative Villa Estate, Badore, Ajah ní ìpínlẹ̀ Eko ni ẹ̀gbọ́n òun ń gbé tí òun sì gbé ajá náà lọ síbẹ̀ láti fún èyí tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ láyè.

Nítorí tí ajá ṣìnà ilé ni wọ́n ṣe yìbọn pa á

Esther ní ogúnjọ́ oṣù Kẹta ni ẹ̀gbọ́n òun, Okoli Vincent fẹ́ jáde nílé láti máa lọ síbi iṣẹ́ ní nǹkan bíi aago mẹ́rin ìdàjí ṣùgbọ́n tó ṣe àkíyèsí pé kò sí Roxie nínú ilé rẹ̀.

Ó ní ìgbà àkọ́kọ́ tí Roxie yóò ṣìnà ilé nìyí tí irú rẹ̀ kò sì wáyé rí.

“Roxie rí ilé tó wà ní ṣíṣí sílẹ̀ tó sì wọ ibẹ̀ lọ láti sùn tí ẹ̀gbọ́n òun sì ti ń wa káàkiri gbogbo inú ọgbà tí kò rí i.”

“Nígbà tí ẹ̀gbọ́n kò rí Roxie ló lọ sí ọ̀dọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tó ń ṣọ géètì inú “estate” wọn láti lọ fi ẹjọ́ sùn àti wí pé tí wọ́n bá bá òun rí ajá náà kí wọ́n kàn sí òun.”

“Ẹ̀gbọ́n tún padà lọ fún ìgbà kejì láti le jẹ́ kí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò náà mọ̀ wí pé òun kò rí ajá náà tí wọ́n sì sọ fú un pé tí àwọn bá ti rí ajá náà ni àwọn máa kàn sí i.”

Esther tẹ̀síwájú pé ní nǹkan bíi aago mẹ́wàá òwúrọ̀ ni wọ́n pe ẹ̀gbọ́n òun pé àwọn ti rí ajá náà "àmọ́ wọn ò jẹ́ kí ẹ̀gbọ́n mi wọlé nígbà tó dé ibẹ̀."

Ó ní wọ́n sọ fún ẹ̀gbọ́n òun pé àwọn máa pa ajá náà nítorí òfin ọgbà àwọn ni pé ajá tó bá ti ń rìn régberègbe nínú ọgbà àwọn pípa ni àwọn máa ń pa wọ́n.

"Ẹ̀gbọ́n mi bẹ̀ wọ́n kí wọ́n má pa Roxie, ó ní òun ti ṣetán láti sanwó ìtanràn"

“Ẹ̀gbọ́n mi sọ fún wọn pé kìí ṣe wí pé ajá náà rìn régberègbe, ó kàn ṣìnà ilé ni àti pé tí wọ́n bá fẹ́ kí òun san owó ìtanràn, òun ti ṣetán láti fún wọn.”

Ó ní Vincent sọ fún àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò náà pé tó bá jẹ́ wí pé kí òun gbé ajá náà kúrò nínú ọgbà òun ṣetán àmọ́ kí wọ́n jọ̀ọ́ kí wọ́n má pa ajá náà ṣùgbọ́n wọ́n kọ̀ jálẹ̀.

Esther fi kún un pé àwọn tó ni ilé tí Roxie sùn sí mọ́júmọ́ náà lé ẹ̀gbọ́n òun kúrò níwájú ilé wọn nítorí àwọn kò lè jáde láti ìgbà tí àwọn ti jí bá ajá lẹ́nu ọ̀nà ilé àwọn.

“Kìí ṣe wí pé ajá náà ṣe ìkọlù sí ẹnikẹ́ni, ẹ̀yìn ilé generator gan ló sùn sí nítorí ẹ̀rù ń bà á nígbà tó rí àwọn ènìyàn pẹ̀lú ìbọn lọ́wọ́."

“Nígbà tí ẹ̀gbọ́n bẹ̀ wọ́n títí, wọ́n ní kó pe olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò, olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ní kó pe alága ọgbà àmọ́ nígbà tó pe onítọ̀hún ìyẹn ní òfin àwọn ni.”

“Wọ́n sọ wí pé ajá mi ni ajá kẹfà tí àwọn máa pa fún irúfẹ́ nǹkan báyìí tí wọ́n sì yìbọn fún un ní ọrùn ní ẹ̀ẹ̀mẹta.”

Esther ní Roxie gbìyànjú láti sáré lọ bá Vincent nígbà tó gbọ́ ohùn rẹ̀ níta géètì àmọ́ àwọn ènìyàn náà ń pariwo mọ́ ẹ̀gbọ́n òun láti kúrò ní ẹnu géètì tó wà.

Ọlọ́pàá fòfin gbé ẹni tó pa ajá

Esther ní òun àti ẹ̀gbọ́n òun lọ fi ẹjọ́ sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá Langbasa tí wọ́n sì nawọ́ gán olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ tó yìbọn pa Roxie.

Ó ní nígbà tí àwọn bèèrè fún òkú Roxie, wọ́n sọ wí pé àwọn ti jù ú sínú odò nígbà tí àwọn kọ̀ láti gbà á lọ́wọ́ àwọn.

Ó ní àwọn ti ń gbìyànjú láti gbé ẹjọ́ náà lọ sí Panti àmọ́ àwọn ọlọ́pàá ti jẹ́ kó yé àwọn pé ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n ni èyí tó le wáyé.

Àfẹnukò wa ni láti máa pa ajá tó bá ń régberègbe nínú ọgbà wa

Alága àwọn olùgbé Cooperative Villa Estate, Tokunbo Olugbenga nígbà tí òun náà ń bá BBC sọ̀rọ̀ ní ọdún 2022 ni gbogbo àwọn olùgbé inú ọgbà náà ti fẹnukò láti máa pa ajá tó ń rìn régberègbe.

Olugbenga ní èyí kò ṣẹ̀yìn bí ajá ṣe máa ń sán ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ní agbègbè náà tó sì ti ń di lemọ́lemọ́.

Alága náà ni kìí ṣe òfin tí òun dá ṣe lọ́wọ́ ara òun ni òfin náà bíkòṣe ìfẹnukò gbogbo àwọn lati le dá ààbò bo àwọn tọ ń gbé nínú ọgbà náà.

Ó ní nǹkan bíi aago méje àbọ̀ òwúrọ̀ ọjọ́ Ajé tó kójá yìí ni òun gba ìpè láti ọ̀dọ̀ ẹni tó nilé tí Roxie wọ̀ pé ajá kan wá ṣe ìkọlù sí àwọn ẹbí òun.

“Mo pé àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò láti lọ síbẹ̀ láti lọ wo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni náà kàn ń fi fóònù dààmú mi títí mo fi lọ síbẹ̀.”

“Nígbà tí èmi náà ma dé ibẹ̀ mi ò lè wọ ilé nítorí Roxie kàn ń rìn lọ rìn bọ̀ níwájú ilé àwọn ẹni náà, tí wọ́n ń yọjú lójú wíńdò.”

Ó ní nítorí Vincent wá láti sọ wí pé òun ni òun ni ajá kò túmọ̀ sí pé àwọn kò ní pa ajá náà nítorí òfin ọgbà àwọn ni àwọn máa tẹ̀lé.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá Eko, Benjamin Hundeyin ní ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Kí ni òfin Nàìjíríà sọ?

Kò sí òfin kan pàtó tó wà fún ìgbáyégbádùn àwọn ẹranko ní Nàìjíríà.

Ẹ̀wẹ̀, abala 495 ìwé òfin ọ̀daràn ìyẹn Nigerian Criminal Code Act korò ojú sí híhu ìwà àìdáa s'áwọn ẹranko.

Òfin náà làá kalẹ̀ pé ẹnikẹ́ni tó bá hu ìwà ipá sí ẹranko le fi ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà gbára tàbí kó san owó ìtanràn ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta náírà tàbí kó fi méjéèjì gbára.