Ikú tún ṣọṣẹ́ o! Aṣojú Orílẹ̀èdè Naijiria sí Spain, Ademola Seriki, jáde láyé

Aṣoju orilẹede Naijiria lọ si orilẹede Spain, Ademola Seriki, ti jade laye.

Agba oloṣelu naa to jẹ ọmọ bibi ilu Eko lo ku si ilu Madrid ni ẹni ọdun Mẹtelelọgọta.

Awọn mọlẹbi kede iku naa ninu atẹjade kan ti awọn ọmọ oloogbe fi sita fun awọn akọroyin lowurọ ọjọbọ, wọn ni Baba naa jede laye niluu Madrid.

Ninu atẹjade naa; “Pẹlu ẹdun ọkan, ti a si n dupẹ lọwọ Ọlọrun ni a fi n kede ipapoda Baba, Ọkọ, Ẹgbọn ati Ọre wa, Ambassador Demola Seriki, ẹni to jade laye lọjọ Kẹẹdogun, ọsu kejila, ọdun 2022.

“O jade laye pẹlu irọrun ni ayika awọn mọlẹbi rẹ ni niluu Madrid, lorilẹede Spain.”