Kí nìdí táwọn èèyàn fi ń sọ pé Gómìnà Adeleke fẹ́ darapọ̀ mọ́ APC? Adeleke fúnrarẹ̀ ṣàlàyé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Okunkun ko ni i kun, ki oninu ma mọ inu rẹ, bo ti wu ki ẹnu araye maa wi tiwọn to.

O jọ pe bẹẹ lo ri fun Gomina Ademola Adeleke ti ipinlẹ Osun, to tun ti kede bayii pe oun ko lero lati di ọmọ ẹgbẹ APC labẹẹ bo ṣe wu ko ri.

Adeleke ni oun ko gbèrò láti darapọ̀ mọ́ APC rara

Tẹ o ba gbagbe, awuyewuye nipa pe Gomina Adeleke fẹẹ kuro ni PDP, ko si darapọ mọ APC ko ṣẹṣẹ maa waye, iroyin naa ti kọkọ gbode bii oṣu meloo sẹyin.

Eyi ko ṣẹyin bi awọn ọmọ ẹgbẹ PDP ṣe n yọ bii ọwọ̀, ti wọn si n darapọ mọ APC.

Nigba to n ṣalaye fun awọn akọroyin, niluu Abuja, nibi ipade igbimọ to n ri si ibi ti awọn ọmọ ẹgbẹ yoo de si ṣiwaju ipade apapọ ẹgbẹ PDP ti yoo waye loṣu to n bọ, Adeleke sọ pe ọrọ mọlẹbi ni rogbodiyan to n ṣẹlẹ ninu PDP.

"Ẹgbẹ wa ṣi duro digbi, bẹẹ la ṣi ni awọn ọmọ ẹgbẹ to duro rẹgi ni Naijiria. Ẹru o bodo lọrọ temi."

Gomina Adeleke lo wi bẹẹ.

"Bí ọ̀rẹ́ mi nínú APC bá pè mi sóde, kò túmọ̀ sí pé mo ti di ọmọ ẹgbẹ́ APC tí mo bá lọ"

Ni itẹsiwaju alaye rẹ, Gomina Adeleke sọ pe awọn eeyan to n gbe iroyin pe oun fẹ di ọmọ APC n sọ bẹẹ nitori awọn ọrẹ pupọ ti oun ni ninu ẹgbẹ naa ni.

"Ẹni ti oju rẹ la daadaa ni mi. Ti mo ba ni ọrẹ ninu APC ti wọn si pe mi ayẹyẹ bii ode iyawo tabi omiran, mo maa lọ. Iyẹn ko tumọ si pe mo n darapọ mọ wọn.

"Ba a ṣe n sọrọ yii, emi ni Igbakeji Alaga ipade wa ti yoo waye lọjọ kẹẹẹdogun ati ikẹrindinlogun oṣu Kọkanla, mo si duro tọkan-tọkan bii ọmọ ẹgbẹ PDP.

"Emi naa si ni alaga igbimọ to n ri si ile gbigbe ninu ẹgbẹ wa."

O fi kun un pe ki i ṣe PDP nikan ni awọn eeyan ti n fi ẹgbẹ silẹ, awọn ko gbagbọ ninu awọn irọ funfun to n kari aye nipa ẹgbẹ naa.

Adeleke ṣalaye pe ipade apapọ PDP yoo so eso rere lagbara Oluwa, PDP yoo si maa tẹsiwaju.

" A n ṣepade a si n yanju awọn ọrọ wa labẹnu, ọrọ mọlẹbi ni. A ko fẹ ki ẹnikẹni maa ba wa fi ṣuga, ata ati iyọ si I.

"funra wa la n yanju ọrọ ara wa, a si mọ ba a ṣe n yanju ọrọ ẹ."

Bẹẹ ni Gomina Ademola Adeleke kadi alaye naa nilẹ.