Àwọn nǹkan tí Hulk Hogan ṣe nígbà ayé rẹ̀ tó fa awuyewuye

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Lai si ani ani, ọpọ eeyan ni yoo maa ṣe iranti gbajugbaja ajijakadi n ni, Hulk Hogan, to doloogbe fun itu to pa ninu ere idaraya ijakadi.

Ṣugbọn ọpọ eeyan naa si tun ni yoo maa ranti rẹ fawọn nnkan to ṣe eyi to fa awuyewuye tawọn eeyan n sọ nipa rẹ.

Yoruba bọ wọn ni a kii mọ ọ rin ki ori o ma mi, bayii ni ọrọ ilumọọka onijakadi to doloogbe naa ṣe ri.

Wọnyii lawọn nnkan ti gbajugbaja onijakadi n ni Hogan ṣe to fa awuyewuye:

Hogan jẹri nile ẹjọ lọdun 1994 ninu igbẹjọ Ọgbẹni Vince McMahon to jẹ ọkan lara awọn oludasilẹ ileeṣẹ WWE to n ṣakoso ere ijakadi.

Nibi igbẹjọ naa lawọn olupẹjọ ti fẹsun kan McMahon ati ileeṣẹ WWE pe wọn fawọn onijakadi loogun oloro ''steriods'' lo lati maa ja.

Nnkan Hogan sọ jẹ ọkan gboogi lara nnkan to jẹ ki ijọba jẹbi ẹjọ naa, ti McMahon si gba idalare.

Amọ, ọpọ lo ri Hogan bi ọdalẹ tori o jẹri tako McMahon.

Lọdun 2015 ni wọn yọ Hulk Hogan kuro ninu ẹgbẹ ogbontarigi WWE Hall of Fame lori ẹsun pe o sọrọ kan to ni i ṣe pẹlu idẹyẹsi si ẹya mii.

Ṣugbọn wọn gba a pada lẹyin ọdun mẹta ti wọn le kuro nibẹ.

Lọdun 2024, Hogan sọ nipa igbakeji aarẹ Amẹrika telẹ, Kamala Harris, o si beere bo ya ki oun ju u soke koun si la a mọlẹ.

Hogan sọrọ yii nibi eto kan nibi to ti n mu ọti.

Ni ibẹrẹ ọdun 2025 ti Hogan yọju sita ni ọpọ ero bẹrẹ si ni ṣe huu le e lori, eyi to jẹ iyalẹnu fun ọpọ eeyan papaa julọ pẹlu aṣeyọri to ti ṣe ninu ere ijakadi.

Ipa ti Hulk Hogan ko nilu eto oṣelu Amẹrika

Barack Obama ni Hulk Hogan ṣatilẹyin fun ninu ibo aarẹ Amẹrika ọdun 2008, oun naa lo si wọle ibo ọhun.

Amọ, Hogan yi ipinnu rẹ pada lẹyin ọdun mẹta.

''Mo ṣatilẹyin fun Obama ko le wọle, ero mi ni wi pe yoo ṣe gbogbo nnkan to sọ.

Obama ko mu ileri rẹ lori awọn nnkan to sọ pe oun maa ṣe ṣẹ,'' Hogan lo sọ bẹẹ fun Fox News lọdun 2011.

Inu Hogan ko dun si bi Obama ṣe kọ ọrin ti akọle rẹ n jẹ '''Real American'' lasiko ounjẹ alẹ rẹ nileeṣẹ ijọba White House.

Bi orin yii ṣe n lọ ni wọn ṣafihan iwe ẹri ọjọ ibi Obama eyi to fidi rẹ mulẹ pe Amẹrika ni wọn bi i si.

Ṣaaju ni Donald Trump ti n sọ ahesọ kan pe Obama kii ṣe ọmọbibi orilẹede Amẹrika.

Nigba to di asiko idibo aarẹ Amẹrika ọdun 2016, Trump ni Hogan ṣe atilẹyin fun.

Trump naa lo tun gbaruku ti lasiko ibo aarẹ ọdun 2020, koda, o tun sọ pe oun gan an le ṣe igbakeji Trump.

Hulk Hogan tun sọ pe oun gan an le dupo aarẹ orilẹede Amẹrika.

Hogan tun darapọ mawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Republican lọdun to kọja lẹyin to mori bọ lọwọ awọn to fẹẹ pa a.

Hulk Hogan, gbajúgbajà oníjàkadì, ti jáde l'áyé

Ogbontarigi onijakadi, Hulk Hogan ti ku lẹni ọdun mọkanlelaadọrin.

Ajọ to n mojuto idije ijakadi, WWE, lo fidi iroyin iku Hogan mulẹ ni irọlẹ Ọjọbọ.

Ninu atẹjade ti World Wrestling Entertainment ọhun fi sita lo ti sọ pe ibanujẹ nla lo jẹ lati gbọ iku gbajugbaja elere ijakadi Hulk Hogan.

Wọn ṣapejuwe Hogan gẹgẹ bi "ọkan lara awọn to gbajumọ julọ", to si ran WWE lọwọ lati di ilumọọka kaakiri agbaye ni nnkan bi ọdun 1980 soke.

Wọn ni awọn ba ẹbi, ọrẹ ati awọn ololufẹ oloogbe naa kẹdun.

Ohun to yẹ ki o mọ nipa Hulk Hogan

Hulk Hogan lo fẹ ẹ jẹ onijakadi to gbajumọ julọ ninu itan ere idaraya naa.

Ọdun 1953 ni wọn bi, ti wọn si sọ orukọ rẹ ni Terry Boella.

Lati ọdun 1980 titi di nnkan bi 2000, ni Hogan fi jẹ gaba lagbo awọn onijakadi kaakiri agbaye, ko to o di pe o bẹrẹ si ni kopa ninu fiimu ati awọn eto agbelewo mii lori tẹlifisan.

Ọdun 1979 lo kọkọ darapọ mọ ẹgbẹ ijakadi to n jẹ World Wrestling Federation to pada di World Wrestling Entertainment. Amọ o ku kuro ni ọdun 1981.

Hogan ni oludije gboogi to kọkọ kopa ninu idije WrestleMania niluu New York lọdun 1985, nibi ti oun ati Mr T ti fẹyin Paul Orndorff ati Roddy Piper, janlẹ.

Lọdun 2018, ileeṣẹ naa gba a ṣiṣẹ pada, ti wọn si sọ pe o lẹtọọ si anfaani lẹẹkeji. Ṣugbọn ṣa, ọpọlọpọ awọn gbajugbaja elere ijakadi, lara eyi ti New Day ati Titus O'Neil, sọ pe yoo ṣoro lati kan gbagbe ọrọ ti Hogan sọ.

Ni ọdun diẹ sẹyin, Hogan kopa nibi ipolongo ibo Trump, ati lasiko ipolongo fun idibo ilẹ America to waye lọdun to kọja.

Awọn eero iworan ho le Hogan lori laipẹ yii to lọ si idije WWE kan, nigba to kopa ninu eto ileeṣẹ naa, Monday Night Raw, lati polowo ọtí to n ṣe.

Ni gbogbo ọdun 1990 soke, okiki Hogan tayọ kọja ijakadi, pẹlu bo ṣe kopa ninu awọn fiimu bii Mr Nanny ati Suburban Commando.

Nitori naa ni ko ṣe jẹ iyalẹnu fun ẹnikẹni nigba ti WWE fi ami ẹyẹ da a lọla gẹgẹ bi akọni manigbagbe ti wọn n pe ni Hall of Fame, lọdun 2005. Wọn tun gba a gẹgẹ ọmọ igbimọ oludari ajọ naa. Amọ ṣa, wọn yọ orukọ rẹ kuro ninu iwe awọn akọni manigbagbe lọdun 2025, nigba ti wọn fi opin si iṣẹ rẹ ninu WWE, nitori pe fidio kan to ṣafihan bo ṣe pe èdè idẹyẹsini kan lu sita.