Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún dèrò àtìmọ́lé lẹ́yìn tó bú gómìnà ìpínlẹ̀ Yobe lórí ayélujára

Wọn ti fi ṣikun ofin mu ọmọ ọdun mẹrindinlogun kan nipinlẹ Yobe lori ẹsun pe o sọrọ kobakungbe nipa gomina Mai Mala Buni lori ayelujara.

Bo tilẹ jẹ pe ọjọ kọkanla, oṣun Kejila, ọdun 2022 yii ni wọn fi ọmọde naa si atimọle, ọrọ naa ko han sita titi di igba ti baba rẹ, Garba Isa ke si awọn ọlọpaa pe ki wọn fi ọmọ oun silẹ.

Ileeṣẹ iroyin abẹle Channels jabọ pe ilu Nguru ni wọn ti mu ọmọde naa, ki wọn to tare rẹ si olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa niluu Damaturu.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, baba ọmọ naa bu ẹnu atẹ lu ohun ti ọmọ rẹ ṣe.

Ọkunrin naa ti wa rawọ ẹbẹ si gomina ipinlẹ naa ati kọmiṣọna ọlọpaa, Garba Haruna, pe ki wọn bo oju aanu wo ọmọ oun nitori ọmọde lo n ṣe.

Mo kabamọ ohun ti ọmọ mi ṣe

Isa sọ pe “Mo kabamọ ohun ti ọmọ mi ṣe.”

“Mi o leeyan kankan, iṣe agbafọ lasan-lasan ni mo n ṣe, ohun ti ọmọ mi si ṣe ko bojumu to.”

“Mo wa fi akoko yii rawọ ẹbẹ si gomina Mai Mala Buni ati awọn ọlọpaa ki wọn ṣaanu ọmọ mi, ki wọn si jọwọ rẹ ni atimọle to wa.”

Ọmọ naa yoo foju bale ẹjọ

Ẹwẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ naa sọ pe lootọ ni ọmọ naa wa ni ahamọ awọn, yoo si foju bale ẹjọ ti wọn ba ti pari iwadii lori ẹsun ti wọn fi kan an.

O ni “Ti a ba ti pari iwadii wa tan, ọmọ naa yoo foju bale ẹjọ.”

“Kii ṣe igba akọkọ ree ti awọn eeyan yoo maa lo ikanni ayelujara lati maa ba orukọ awọn ẹlomiran jẹ, a si gbọdọ fọ ilu mọ.”

“Eeyan kan ko le maa lo ikanni ori ayelujara lati maa sọ oriṣiriṣi ọrọ ti ko tọ, ofin wa ni Naijiria, ẹnikẹni to ba si tapa si ofin yoo jẹ iye to tọ labẹ ofin ọhun.”