You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àgbàrá òjò gbé akẹ́kọ̀ọ́ kan lọ ní ìpínlẹ̀ Ondo
Agbara ojo ti gbe akẹkọọ ile ẹkọ Mount Carmel Girls School Ikarẹ Akoko kan lọ lọjọ Iṣẹgun.
Gẹgẹ bi ohun ti a gbọ, akẹkọọ naa ti orukọ rẹ n jẹ Motunrayọ John n ṣere loju agbara ojo kan, eleyi ti wọn ni o ki ẹsẹ bọ ti o si yọ sinu rẹ ti agbara ojo naa si gbe e lọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, SP Ibukun Ọdunlami fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC.
Nigba ti a beere boya wọn ti pada ri oku ọmọdebinrin naa, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo ni oun ko tii lee sọ ni pato, lasiko ti a fi baa sọrọ.
Awọn eeyan kan ni ilu naa ṣalaye pe agbegbe Sẹmusẹmu nilu Ikarẹ ni iṣẹlẹ naa ti waye.