You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Tinubu - Ẹ̀yin ọmọdé, ẹnikẹ́ni tó bá tẹ ẹ̀tọ́ yín mọ́lẹ̀ tábí ṣe aburú fún wọn, ẹ sọ̀rọ̀ sókè, á gbọ́ igbe yín
Aarẹ Bola Tinubu ti ṣe ileri pe ijọba oun yoo saa gbogbo ipa rẹ lati da bobo ẹtọ, mimu ohun ti wọn fẹ da wa si imusẹ ati ọjọla wa si imusẹ fun gbogbo ewe Naijiria .
Aarẹ sọ eyi lasiko to n darapọ mọ awọn ewe lati ṣe ayajọ awọn ewe ti ọdun 2025.
Ninu ọrọ rẹ to ba awọn ewe sọ lọjọ Isẹgun, Aarẹ ṣapejuwe awọn ewe gẹgẹ bii iwuri ati ogo ọjọ ọla fun orilẹede Naijiria, to si jẹ ko di mimọ pe ijọba yoo ri si idagbasoke ati aabo awọn ewe Naijiria.
"Awọn ewe wa jẹ ohun to ṣe pataki fun orilẹede wa ati ọjọ ọla, awọn ni ileri ọla fun ohun ọtun ati idagbasoke," Tinubu sọ.
Akọle ayajọ ayẹyẹ awọn ewe ọdun yii ni, "Dide, Sọrọ Soke: ṣe àgbekalẹ iran ti ko ba ọmọ lẹru,".
Aarẹ Tinubu ni o ṣe koko fun awọn ewe lati wa ni agbegbe ti ẹru ko ti ni ba wọn rara.
"Titẹ oju awọn ewe mọlẹ ko ni aye kankan ni orilẹede Naijiria ti oni rara labẹ iṣejọba mi,
"Ewe to ba n kọ ẹkọ pẹlu ibẹru bojo ko le ni idagbasoke. Ewe to n dagba ninu ibẹru ko dagba daada," Aarẹ ṣekilọ.
O tẹsiwaju, to si kede fun awọn ewe pe ki wọn ma ṣe ku ni ẹni, "To ba ri nnkan, Sọ nnkan naa, Ko si ṣe nnka".
Aarẹ Tinubu rọ gbogbo awọn obi, alagbatọ ati gbogbo ọmọ orilẹede Naijiria lati jẹ oludabobo ewe.
"Ofin nikan ko to lati da bobo awọn ewe yii. Obi, Olukọ, Olori ẹṣin,Aṣofin ati Araalu gbọdọ tọju awọn ewe."
Aarẹ ni gbogbo eto lo ti n to lati ri pe awọn ewe ni anfani pupọ ti ṣe koko fun ọjọ ọla wọn
"Fun ẹyin ewe, ọjọ ọla yin ṣe koko. Ohun yii ṣe koko.
Ko si ẹnikẹni to le tẹ ẹtọ yin mọlẹ tabi ṣe aburu fun yin. Ti ẹnikẹni ba ṣe eyi fun yin, sọrọ soke, a o gbọ ipe rẹ, ti a si dabobo rẹ."
Ijọba setan tẹwọgba ofin to dabobo ewe
Ijọba apapọ ti kede pe oun ti ṣetan lati ṣe agbeyẹwo ofin ti yoo kun idabobo awọn ewe lọwọ, ti yoo si pese aabo fun wọn lọwọ ipenija eyikeyi .
Minisita fun awọn obinrin, Imaan Sulaiman-Ibrahim, lo sọ eyi di mimọ nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Abuja lasiko apero kan ti akọle rẹ 'Save the Children International (SCI)'.
Sulaiman-Ibrahim ṣalaye pe ijọba fẹ gbe igbesẹ yii lati ri daju pe eto awọn ewe ni aabo to yẹ, ti ko si ni si iroyin nipa ifiyajẹ ọmọ nibikibi lorilẹede Naijiria.
O fikun pe laipẹ ijọba yoo kede awọn igbesẹ rẹ si lori idabobo awọn ewe lorilẹede Naijiria.
Ohun to yẹ ko mọ nipa ayẹyẹ ayajọ awọn ewe
Ọjọ kẹtalelogun, osu karun-un, ọdun 1964 ni orilẹ-ede Naìjíría kọkọ se ayẹyẹ ayájọ ọjọ awọn ewe.
Ọdun 1955 ni wọn kọkọ se ayajọ yii lagbaye labẹ onigbọwọ ajọ agbaye kan to n ri si itọju awọn awe, International Union for Child Welfare ní Geneva.
Ni ọdun 1954 ni ipade igbimọ ajọ isọkan agbaye kede rẹ, wọn se ifilọlẹ rẹ ki gbogbo orilẹ-ede le yan ọjọ kan fun ti wọn.
Lakọkọ, wọn se ifilọlẹ rẹ lati se imugbooro ìgbọra-ẹni-ye laaarín awọn ewe.
Ẹẹkeji, lati bẹrẹ igbesẹ fun jijẹ anfani ati síse itọju awọn ewe lagbaye.