You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
DSS fẹ́ yọwọ́ nínú ẹjọ́ ìbọn níní lọ́nà àìtọ́ tí wọ́n fi kan Emefiele, wọ́n ní Ó lẹ́jọ́ tuntun láti jẹ́
Ijọba apapọ ti yọwọ ninu ẹjọ ti wọn pe gomina tẹlẹ fun banki apapọ Naijiria,CBN Godwin Emefiele lori ẹsun “nini ibọn lọna ti ko ba ofin fun eyi ti wọn pee niwaju ile ẹjọ giga apapọ to wa nilu Eko.
Adari agba ileeṣẹ eto idajọ ni ijọba apapọ, Mohammed Abubakar ṣalaye ninu arọwa afẹnuṣe kan to gbe kalẹ niwaju ile ẹjọ naa pe awọn n gbe igbesẹ yii nitori awọn esi iwadi tuntun to tẹ awọn lọwọ.
Amọṣa agbẹjọro fun Emefiele, Agbẹjọrọ agba Joseph Daudu, SAN tako ipe yii pẹlu awijare pe ki ijọba kọkọ yẹ ara rẹ wo lori aigbọran rẹ si aṣẹ ti ile ẹjọ ti kọkọ pa pe ki wọn gba beeli Emefiele ki wọn to gba ipe wọn wọle.
Onidajọ Nicholas Oweibo to gbọ ẹjọ naa sun igbẹjọ si Ọjọbọ ọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹjọ ọdun 2023 lati gbe idajọ kalẹ lori ẹbẹ tuntun ti ijọba apapọ gbe ka iwaju rẹ naa.
Ninu ọrọ to ba awọn akọroyin sọ lẹyin ijoko ile ẹjọ naa, adari agba ni ileṣẹ eto idajọ ijọba apapọ to tun jẹ agbẹjọro fun ijọba ṣalaye pe ogun ẹsun miran lo tun ti jade ti wọn ti fi kan Emefiele niwaju ile ẹjọ giga apapọ to wa ni ilu Abuja tii ṣe olu ilu Naijiria.