Ile Ife kìí ṣe fún ẹlẹ́sìn Musulumi tábi Krìstẹ́nì rárá - Arole Obatala àgbáyé

Ní Ọjọbọ ọsẹ tó kọjá ni a gbọ pé awọn oniṣẹṣe kan yawọ inú Mọsalasi tí ó wa ni agbegbe Idiomo ni bii aago mẹrin ọsan, ti wọn si lu awọn ti wọn ba ninu Mọsalasi naa lalubami, nibi ti ọpọ wọn ti farapa yanayana.

Idi ree tawọn musulumi nilu Ile Ife fi ṣe iwọde lati fi aidunu wọn han si bi awọn Oloro ṣe ṣe ikọlu si Mosalasi naa.

Awọn olórí àwọn olooṣa àti musulumi bá ikọ BBC News Yorùbá sọrọ lórí ìkọlù tó wáyé láàárín wọn ilu naa.

Olaolu Dada to jẹ Arole Obatala àgbáyé tó si tun jẹ olórí àwọn oloosa sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé Ilé-Ifè kìí ṣe fún ẹlẹ́sìn musulumi tàbí fún Kristẹni rárá.

"Ilé-Ifè wá fún ẹbọ, òrìṣà àti bẹẹbẹẹ lọ ní Ilé-Ifè wá fún".

Bakan naa ló sọ wipé ìkéde ti wa ṣíwájú ọjọ́ tí awọn fẹ́ gbé oro jáde.

“Àti kéde lórí Radio àti lori ìwé ìròyìn káàkiri kí oro tó jáde, àwa kìi fa wàhálà rárá”.

“Àwọn ẹlẹ́ṣin musulumi lo kọ́kọ́ dojú ìjà kọ àwọn ọmọ wa ti wọ́n sì fá ọkàn lára ọmọ oro wọ inú mọsalasi tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣáa ní àdá ṣùgbọ́n tí irúnmọlẹ kò jẹ ki o wọlé síi lára”.

Arole Obatala ṣalaye pe mọsalasi tí ó wa ńi Ìdíomo jẹ ọkan ninu awọn mọsalasi tó máa fún awọn lẹ́bùn lọdọọdun tẹ́lẹ̀.

“Wọn máa ra omi àti ọtí sìnaabu bẹẹ ni wọ́n máa fún wa lowo lákòókò tí oro bá ti n kọjá lọ tẹ́lẹ̀.

Arole Obatala àgbáyé ni àwọn ti gbé igbesẹ lórí ọrọ yìí ti wọ́n sì ti kọ̀wé sì ọga ọlọpaa pátápátá lórílẹ̀édè yìí àti Aarẹ Buhari láti jẹ ki wọ́n kó mọ ohun tí ọn sẹlẹ lọ́wọ́ lọ́wọ́ nílé ìfẹ́.

Ki ni igun ti awọn musulumi sọ?

Ẹni tó gbà ẹnu sọ fún aṣiwaju àwọn musulumi, Baba Adinni tí Ilé-Ifè Sikiru Balogun ṣàlàyé pe “irọ tó jìnà sí òtítọ́ ọ̀rọ̀ ni pé àwọn ọmọ wa ló gbé ìbọn tàbí lọ yín ìbọn lákòókò tí ìjà wáyé láàárín àwa mùsùlùmí àti àwọn olóró.

Olórí àwọn ẹlẹ́ṣin musulumi náà ni olukuluku lo ni ominira labẹ ofin lati se ẹsin to wù ú, o si rọ awọn musulumi lati fọwọ wọnu ki alafia le jọba.

Bakan naa, Sikiru Balogun parọwa fun awọn ẹlesin ibilẹ lati kilọ fun awọn ọmọ wọn ti wọn ko loye tó, ki wọn si da wọn lẹkọ lori bi wọn o ti ṣe máa hù ìwà lawujọ.

Sikiru Balogun dúpẹ́ lọwọ Ọlọ́run pé àwọn tó fara pa tí ní àlàáfíà bayii bẹẹ ni kò sì ẹni kánkán tó kú nínú ìkọlù naa.

Ẹwẹ, alukoro ileeṣẹ Ọlọpa tí Ìpínlẹ̀ Osun, Yemisi Opalola tí sọ̀rọ̀ pé, àwọn Ọlọpa kò tii rí ẹni kánkán mú latari ìkọlù tó wáyé náà ní Ilé-Ifè lọ́jọ́ alamisi tó kọjá.

Ìwádìí sì n lọ lọwọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọhun àti wípé ilé ìṣe olopa kò ní fi àyè gba irú ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé yìí ni Ipinlẹ Osun.

ASP Opalola rọ àwọn olúgbé ìlú Ilé-Ifè àti Ìpínlẹ̀ Osun lapapọ lati gba àlàáfíà láyè kò jọba kí olúkúlùkù lè ṣe ẹṣin rẹ pẹlu àlàáfíà.